Ọkọ̀ òfurufú ọmọ ogun Nàìjíríà fi àdó olóró pa ọ̀pọ̀ èèyàn ní Zamfara– Aráàlú

NAF

Oríṣun àwòrán, NAF

Iroyin to n tẹ wa lọwọ sọ pe ọpọ araalu lo ti jade laye bayii lẹyin ti ọkọ ofurufu ọmọ ogun Naijiria kan ju ado oloro siluu Mutumji, ni ijọba ibilẹ Maru, nipinlẹ Zamfara.

Awọn ara abule naa sọ pe awọn agbesumọmi lawọn ọmọ ogun naa n gbiyanju lati ju ado oloro naa lasiko ti wọn sa wọ inu ọja, ko to lọ ṣekupa awọn araalu.

Iroyin ni odidi ọjọ meji gbako lawọn ọmọ ogun fi n koju awọn agbesumọmi naa niluu Malele, ki wọn to sa lọ siluu Mutumji.

ọja lawọn wa nigba ti wọn ri ọkọ ofurufu ọmọ ogun to n fo loke, lẹyin naa ni wọn gbọ iro ado oloro.

Ọkan lara awọn eeyan ọhun, Saidu Ishaka ti ori kọ yọ ninu ibugbamu naa ṣalaye pe igba meji ọtọtọ ni oun ṣubu lulẹ lasiko ti ilẹ n mi titi nitori ibugbamu ọhun, amọ lasiko to oun yoo fi dide, ọpọ oku ni oun ri nilẹ.

O fidi rẹ mulẹ pe ile iwosan Yariman Bakura to wa ni Gusau ni wọn gbe awọn to farapa lọ.

Ọkan lara awọn olugbe Dansadau Emirate sọ pe awọn agbesumọmi naa korajọ lati kọlu ilu Malele ki awọn araalu to ke si awọn ileeṣẹ ọmọ ogun.

Kọmiṣọna eto abo ipinlẹ ọhun, DIG Mammam to ṣabẹwo si awọn to farapa nile iwosan ti bu ẹnu atẹ lu ikọlu naa.

Ki ni ileeṣẹ ọmọ ogun sọ?

Ẹwẹ, ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria ti sọ pe irọ patapata ni iroyin naa to sọ pe awọn fi ọkọ ofurufu pa awọn araalu.

Nigba to n ba ileeṣẹ iroyin Channels sọrọ lori ẹrọ ilewọ, adari eto Operation Hadarin Daji, Major General Uwem Bassey, sọ pe ko si nnkan to jọ bẹẹ.

O fi kun pe iroyin naa jẹ ọna lati ba orukọ ileeṣẹ ọmọ ogun jẹ ati lati fi ẹnu tẹmbẹlu akitiyan wọn.

Bassey pari ọrọ rẹ pe ọta araalu ni gbogbo awọn to n gbe irufẹ iroyin bẹẹ kiri, iru wọn ko si fẹ ki ileeṣẹ naa ṣe aṣeyọri ni.

Awọn ọmọ ogun ṣekupa ọpọ agbesumọmi

Ẹwẹ, ileeṣẹ ọmọ ogun ti ṣekupa ọpọ awọn agbesumọmi ni ipinlẹ Zamfara yii kan naa.

Opin ọsẹ ni wọn ṣakọlu si awọn agbebọn naa niluu Maru lẹyin ti awọn agbesumọmi ọhun ti kọkọ ji ọpọ eeyan gbe nibẹ.

Ilu Maru ni awọn ọmọ ogun ti le awọn agbebọn ọhun lọ siluu Mutunji nibi ti wọn ti ju ado oloro si wọn.

Awọn araalu naa sọ fun BBC pe awọn ka oku bii ọgọta nilẹ lẹyin ikọlu ọhun, nigba ti ogun eeyan farapa.

Wọn tun sọ fun BBC pe awọn araalu kan wa lara to jade laye lasiko ikọlu ọhun.

Gẹgẹ bii ohun ti wọn sọ, awọn araalu to fara gba nibẹ jẹ awọn arugbo ti wọn ko le sare lati sa asala lasiko ti ikọlu naa n waye.