'Mo jẹ́ "disable" àmọ́ ẹ̀gbin ló mú mi máa ṣe "Motor", Ọ̀kada àti Kẹ̀kẹ́ tí èèyàn tí kò lẹ́sẹ̀ lè wà'
Kò sí ìgbà tí mò ń wa mọ́tò àrà ọ̀tọ̀ tí mo ṣe yìí kiri tí inú mi ò máa dá dùn
Ni gbogbo ipinlẹ Kwara paapaa ni Ilorin ati agbegbe Iludun mọ Oro, odu ni ẹni to n jẹ “Dorki” kii ṣe aimọ fun oloko fun iru ara ọtọ̀ eeyan to jẹ.


“Turtle, gear, hand break, clotch ni o, gbogbo ẹ ni mo ṣe si ọwọ̀ niwọn igba ti eeyan ko ni ẹsẹ.”
Gẹgẹ bo ṣe sọ fun BBC Yoruba, ọpọlọpọ̀ ẹbi awọn to ni ipenija ẹsẹ lo maa n wa ba oun lati ba wọn ṣe nnkan irinsẹ fun eeyan wọn.

“Lọpọ́ igba ti mo ba n wa kẹkẹ ti mo ṣe lọ si Ilorin ni awọ́n eeyan a gbe Kamẹra tẹle mi lẹyin pe awọn fẹ fọrọ wa mi lẹnu wo ti wọ́n a da mi duro lọna.”
Segun ni inu ohun dun pe oun lanfani lati maa mu inu awọn eeyan dun to jẹ pe wọn o ni maa gbe wọn kaakiri mọ tori ailẹsẹ ati pe o gbagbọ pe pẹlu gbogbo nnkan ti oun n ṣe, ọjọ iwaju to dara wa fun oun.









