Iṣẹ́ ìdọ̀tí ni mò ń ṣe àmọ́ ó ń san owó iléèwé ọmọ - Akẹ́kọ̀ọ́gboyè Kehinde Adeoye

Àkọlé fídíò, Kehinde Adeoye graduate Potter: Iṣẹ́ ìdọ̀tí ni mò ń ṣe àmọ́ ó ń san owó iléèwé

“Ọja taa n ta, ti a o ko lọ si ibi kankan ti awọn eeyan si n wa si ile lati wa koo, Ọlọrun lo ṣee.”

Kehinde Adeoye jẹ ẹni to wa lati iran awọn amọkoko Abeokuta ni ipinlẹ Ogun. Ninu ifọrọwanilẹnuwo yii pẹlu BBC Yoruba, Kehinde ṣalaye bi o ṣe gbọnju ba koko ṣiṣe ninu ẹbi rẹ.

Kehinde Adeoye
Kehinde Adeoye
Kehinde Adeoye

Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe lẹyin ti oun tilẹ kawe gboye tan nile ẹkọ awọn olukọni, ti o wa iṣẹ titi titi ti ko ri, o pinu lati pada sile sidi owo ẹbi rẹ eyi tii ṣe koko mimọ.

“Mi o ronu pe mo tilẹ wa iṣẹ ijọba mọ. A n gba awọn eeyan si iṣẹ, o si n to waa jẹ, mi o tilẹ ronu iṣẹ ọba mọ.

Iṣẹ taa ba nile nidile iya ati nidile baba ni koko mimọ, kii ṣe eyi ti a kọ.