Tírélà ti gba àárín èmi àti Ooni Ogunwusi rí àmọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ rèé - Olori Tobi Phillips

Olori Tobi Ogunwusi

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Olori Tobi Phillip-Ogunwusi ṣalaye bo ṣe bẹrẹ iṣẹ arinrinoge to wa lara awọn nnkan to ti ṣe ko to di ayaba l’Aafin Ooni Ogunwusi.

Olori Tobi ni gbogbo ile ẹkọ ti oun lọ lati alakọbẹrẹ titi de Fasiti loun ti figagbagba gẹgẹ bi arinrinoge ti oun si maa n bori.

Bawo ni Ooni Ile Ife ṣe foju gaani arẹwa obinrin to pọn rẹdẹrẹdẹ bii tirẹ bayii?

Ooni ati Olori Tobi

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Olori Tobi n sọ awọn ọrọ yii lasiko to n fesi lori eto amohunmaworan ileeṣẹ TVC eyi to jẹ pe asan obinrin ni awọ́n atọkun eto naa.

Tobi ni lootọ ọpọlọpọ eto lo ti waye sẹyin ti oun ati Ooni ti pade amọ ko tete si nnkan to jẹ mọ ọrọ ifẹ.

“Eeyan kan kan dede pe mi lọjọ kan ni to si ni “ṣe o fẹ ṣegbeyawo?”

Olori Tobi ni oun beere pe ki lo ṣẹlẹ. Ẹni naa sọ fun un pe ṣe waa nifẹ lati fẹ Ooni ti Ile Ife, o dẹ fi wọn han ara wọn.

“La ba bẹrẹ ere ifẹ wa, ọpọlọpọ idiwọ ati ikọsẹ lo waye lasiko naa torinaa a ko fẹ ara wa, o ba mi ninu jẹ pupọ.”

Ṣe ẹ yo ifẹ Kabiyesi nigba naa ni?

Ooni Ati olori Tobi

Oríṣun àwòrán, OTHERS

“Bẹẹ ni, mi o ba ma si nibi lonii bi mi o ba gbe ifẹ Kabiyesi sọkan. Mo ti ṣeleri fun ara mi lọpọ́ igba pe ẹni ti mo ba yo ifẹ rẹ ni maa fẹ.

Ẹ wo mi daadaa, arẹwa ọmọbinrin ni mi torinaa, kii ṣe pe mi o ri ọkunrin kọ́ ẹnu ifẹ si mi pe oun fẹ fẹ mi ṣugbọn awọn nnkan to da ni yatọ wa ti mo fẹ ninu ọkunrin ti yoo ba fẹ mi Ooni si ni wọn.”

Torinaa Olori Tobi ni kii ṣe pe iya ọkọ lo jẹ oun debi pe mo fẹ Ooni Ile Ife.

Ki lo de ti ẹ pinu lati lọ si ile olorogun?

Olori Tobi

Oríṣun àwòrán, OTHERS

O ni bo ṣe jẹ pe oun wa nibi to jẹ pe ọpọlọpọ̀ Olori lo wa l’Aafin, oun ti mọ pe Kabiyesi o le maa ri gbogbo aye yẹn lojoojumọ.

“Ati pe mo mọ pe eeyan ti ọwọ rẹ maa n di gaan ni Kabiyesi pẹlu ọpọlọpọ eto, bẹẹ si ni emi gan jẹ eeyan to ni ọpọlọpọ iṣẹ lati ṣe. Mi o ki n ṣe ẹni ti ọwọ rẹ dilẹ rara rara, yatọ fun pe mo gbudọ wa ọna lati wọ inu ipo pe mo jẹ Olori.”

O ni oun kii ṣe ẹni ti yoo ma lẹ ara pọ mọ eeyan kan tẹlẹ.

Lori ọrọ ti o lọ kaakiri ayelujara nipa iha ti wọn kọ́ sii nigba to fẹ fẹ Kabiyesi, Olori Tobi ni iya oun lo kọkọ roo bakan bakan ṣugbọn o sọ pe o ni boya bi Ọlọrun ṣe fẹ ẹ niyẹn.

Bawo lẹyin Olori mẹfa tan yanyan ṣe n to orun sisun lápó Kabiyesi? Ta lo ni ọjọ “Monday”?

Ooni ti Ile Ife

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ẹrin keekee ni Olori Tobi bu si to si fesi si ibeere awọn atọkun eto pe “ko si akọsilẹ aato kankan ti a n tẹle fun sisun ti Kabiyesi lati ni ibalopọ pẹlu Kabiyesi.”

Nigba ti wọn bii pe ṣe Kabiyesi lo kan maa tọka si ẹni to wu u lati wọle tọ ni abi bawo ni, Olori Tobi ni oun ko le sọ iyẹn o pe boya igbakuugba ti Ooni ba yọju si ẹnikẹni fun “tibi” naa ni o ya.

O ni o dẹ wa ku si ọwọ Kabiyesi lati mọ bi yoo ṣe ṣe apa ibi ti wọn n mu ibeere lọ yẹn o.

“Mo jẹ eeyan ti ko ku ẹnu rara, mo mọ bi mo ṣe le sọ imọlara mi ati nnkan ti mo fẹ lai ṣẹ si ẹni ti mo n ba sọrọ.”

O ṣalaye pe ẹni to fẹran gbogbo eeyan ni Ooni torinaa kii ṣe ẹrujẹjẹ.

Bawo ni ibaṣepọ laarin awọn iyale rẹ gẹgẹ bi Olori to kere ju?

Olori Tobi ni ki oun to de Aafin Ooni loun ti nifẹ lati maa bọwọ fun agba torinaa ninu Aafin, oun kan nifẹ lati maa fi ọrọ ami ibọwọ́ “ma” ti oun ba n ba awọn iyale oun sọrọ.

Iyawo Ooni sọ pe ọrọ ile olorogun ko le bo tilẹ jẹ pe oun ko lero pe oun yoo ba ara oun nile olorogun.

Amọ o ni ki oun tilẹ to fẹ ẹnikẹni, o ni awọn nnkan to jẹ pe ti ọkunrin ko ba ni, oun ko le wa pẹlu rẹ.