Ìdí rèé tí wọn fí ń pè mí ní ìyá Seyi Makinde - Mutiat Ladoja

Oríṣun àwòrán, others
Iyawo gomina tẹlẹ nipinlẹ Oyo, Mutiat Ladoja ti salaye idi ti ọpọ eeyan, paapaa awọn eeyan nipinlẹ Oyo, ṣe maa n pe e ni iya isalẹ Gomina Seyi Makinde.
Aya Ladoja sọ eleyi nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ níbi ayẹyẹ ìfinijoye Iyalode tí ilu Illishan Remo nipinlẹ Ogun.
O ni lati ọdun 2002 ni oun ti mọ Seyi Makinde, tí awọn mejeeji si bẹrẹ si ni maa kọwọrin lọdun 2009.
"Mama Seyi ni ìyá Seyi Makinde gan maa ń pè mi"
"Nigba ti a ṣe ipolongo ibo lọdun 2002, Seyi Makinde wa pẹlu wa, fun idi eyi mo mọ nípa Seyi Makinde gan.
"Koda ki ìyá Seyi Makinde to ku, o maa n pe mi ni Iya Seyi."
"Emi ni iya isalẹ rẹ"
Ladoja tẹsiwaju pe eto iṣejọba Seyi Makinde nipinlẹ Oyo ko lẹgbẹ rara nitori ohun meremere to ṣe fun ilọsiwaju ati idagbasoke ipinlẹ Oyo.
"Ẹ lọ beere lọwọ awọn eeyan ipinlẹ Oyo, koda awọn ti kii ṣe ọmọ ipinlẹ Oyo mọ pe Seyi Makinde ṣe gudugudu meje ati yaya mẹfa.
"Eto ẹkọ, eto Ilera ati awọn ohun meremere ni a jẹ anfani rẹ nipinlẹ Oyo lọwọ yii."
Ta ni Mutiat Olayinka Ladoja?
Alhaja Mutiat Olayinka Ladoja ni aya gomina ana nipinlẹ Oyo, Senator Rashidi Adewolu Ladoja.
Oun si lo jẹ obinrin akọkọ nipinlẹ Oyo laarin ọdun ọdun 2003 si 2007 lasiko ti ọkọ rẹ fi wa nipo gomina nipinlẹ naa.
Lasiko to fi jẹ obinrin akọkọ nipinlẹ Oyo, aya Ladoja da ajọ kan silẹ to pe oruk rẹ ni Idera De, eyi to fi n sisẹ aanu fun ọpọ mẹkunnu nipinlẹ Oyo.
Ẹni ọdun mẹrindinlaadọrin ni Mutiat Ladoja, o jẹ obinrin dudu to n dan, ti ọpọ eeyan si maa n sapejuwe rẹ bii arẹwa obinrin.
Koda, o ni ọna aramọnda to maa n gba we gele rẹ, ti yoo ga gongo siwaju lọna to yatọ si ti ọpọ obinrin eyi to maa n mu ki ẹwa rẹ tubọ yọ si.
Ọpọ obinrin si lo maa n fi aramọnda gele wiwe yii se idamọ Alhaja Mutiat Ladoja, ti wọn si n se awokọse ọna to n gba we gele naa.
Oloselu gidi ni Mutiat Ladoja, nitori pe yatọ si pe ọkọ rẹ jẹ oloselu, oun gan ko kẹrẹ nidi oselu.
Lọwọ lọwọ bayii, akọni obinrin yii ati oloselu pataki ni Maye Iyalode tilẹ Ibadan.















