Fathia Balogun, Yomi Fabiyi, Kemi Afolabi àtàwọn èèkàn òṣèré míì kẹ́dùn ikú ‘Sir Kay’

Kamal Adebayọ

Oríṣun àwòrán, Other

Ọpọ eekan oṣere ni wọn ti n daro gbajumọ oṣere, Alhaji Kamal Adebayo, ‘Sir Kay’ to jade laye.

Alhaji Kamal Adebayo, ti ọpọ mọ si ‘Sir Kay Warrior’ jade laye lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kejila ọdun 2022.

Fathia Balogun ninu ọrọ idaro tirẹ fi aworan aṣafihan (emoji) ẹkun si oju opo rẹ pẹlu aworan abẹla to n jo ninu okunkun.

O wa kọ akọle “Iru aye wo leyi. Sir Kay...Ọlọrun” si ori abẹla naa.

Ninu ọrọ ikẹdun ti oun pẹlu kọ si ori ayelujara, Kẹmi Afọlabi ni “Haa, rara o. ko yẹ ko jẹ sir kay”

Bakan naa ni eekan oṣere, Jide Kosọkọ pẹlu kẹdun iku osere tiata naa pẹlu.

Adura pe ki Allah tẹ ẹ si afẹfẹ rere, “Hun ki Allah fun ni Aljanna.” ni Kosoko kọ ni tiẹ.

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 1

Ninu ọrọ ikẹdun ti oun kọ si oju opo instagram rẹ, gbajumọ oṣere ati olotu ere sinima, Yọmi Fabiyi ni

“O di gba kan naa, Sir K Warrior. Wabili Kabbar. Sunre o, akọni Ọkunrin.”

Bakan naa lo tun kọ ọ si akọle miran pe iku ‘akọni!’ naa, to pe ni “Ẹgbọn” mu irẹwẹsi ba oun.

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 2

Ninu ọrọ tirẹ, oṣere sinima, Funṣọ Adeolu kẹdun pe, “Haaa ibanujẹ nla leyi o, ki Ọlọrun fun ni isinmi.”

Àkọlé fídíò, Quest University Ghana: Ìyá àti ọmọ bọ́ sọ́wọ́ gbájúẹ̀ fásitì torí ìyanṣẹ́lódì ASUU

Kòríkòsùn MC Oluomo, gbajúmọ̀ òṣèré Kamal Adebayo 'Sir Kay' jáde láyé

Sir Kay

Oríṣun àwòrán, Kingmcoluomo/Instagram

Gbajumọ oṣere tiata, Alhaji Kamal Adebayọ ti ọpọ mọ si Sir Kay ti jade laye.

Musiliu Akinsanya ti ọpọ mọ si MC Oluọmọ to jẹ eekan lara awọn ọrẹ oloogbe naa kede iku gbajumọ oṣere naa loju opo Facebook rẹ lọsan ọjọ Iṣẹgun.

Aworan Kamal Adebayọ loju opo FB MC oluọmọ

Oríṣun àwòrán, screenshot

“Pẹlu ibanujẹ ọkan ni mo fi n kede ipapoda Alaaji Kamal Adebayọ (Sir Kay). Ki Allah gba a si afẹfẹ rere.”

Titi di bi a ṣe n sọrọ yii, ko tii si iroyin kan pato lori ohun to ṣokunfa iku rẹ.

Gbajumọ oṣere naa jẹ eekan adẹrinpoṣonu nigba aye rẹ to si ti kopa ninu oniruuru sinima.

Skip Instagram post, 3
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 3

Alaaji Adebayọ ni Baba Adebayọ Ridwan, ti ọpọ mọ si Isbae U Barbie lori oju opo ayelujara.

Alhaji Adebayo jẹ oṣere to gbajumọ fun oniruuru aṣa to maa n da ninu ere sinima gbogbo to ba ti kopa.

Iku rẹ si n waye lẹyin oṣu diẹ ti ọmọ rẹ, Isbae U fi ẹbun miliọnu kan naira ta a lọrẹ fun ọjọ ibi rẹ.