Ojú ọ̀nà ẹ̀sìn làwọn obìnrin méje tó kú nínú bọ́ọ̀sì tó gbiná kú sí - Ẹgbẹ́ Mùsùlùmí

Oríṣun àwòrán, Screen shot
Ẹgbẹ apapọ awọn Musulumi ti kẹdun pẹlu awọn mọlẹbi obinrin meje to padanu ẹmi wọn nigba ti bọọsi akero to gbe wọn lọ si ibi apero kan niluu Ijebu Ode gbina lopopona marose Sagamu si Benin.
Ijamba naa lo waye ni orita Odogbolu nigbati ọkọ ayọkẹlẹ Mazda kan, ti nọmba idanimọ rẹ jẹ AGL 886 YD sadede gbina.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ẹgbẹ ọhun, Abdulwasi Taiwo Bangbala fi lede, o sapejuwe ijamba naa gẹgẹ iku ati ọdọ Ọlọrun.
O ni awọn eeyan to padanu ẹmi wọn naa ku si ilana oju ẹsin nitori ọna ẹsin ni wọn ku si.

Oríṣun àwòrán, Abdulwasi Taiwo Bangbala
"Al-Jannat Fridaws ni Ọlọrun yoo pese fun awọn eeyan to ku naa nigba ti yoo tẹwọ gba wọn"
Ẹgbẹ musulumi naa ni pẹlu ẹdun ọkan ni awọn fi gba iroyin naa sugbọn gẹgẹ bii Musulumi, awọn ti fi gbogbo ọrọ siwaju Ọlọrun.
Bangbala wa ransẹ ibanikẹdun si awọn mọlẹbi awọn eeyan ati awọn to farapa yanayana pe Ọlọrun yoo duro ti wọn lasiko isoro yii.
“A gba ladura pe ki Ọlọrun ba wa fori jin awọn eeyan to ku naa, ko si tun duro ti awọn mọlẹbi wọn.
“Al-Jannat Fridaws ni Ọlọrun yoo pese fun awọn eeyan naa nigba ti o tẹwọ gba wọn nitori oju ọna ẹsin Islam.”
Obìnrin méje kú, èèyàn méje míì farapa nígbà tí bọ́ọ̀sì akérò gbiná
Eniyan meje lo ti jẹ Ọlọrun nipe ninu ijamba mọto to waye ni opopona Sagamu si Benin.
Ijamba naa lo waye ni orita Odogbolu nigbati ọkọ ayọkẹlẹ Mazda kan, ti nọmba idanimọ rẹ jẹ AGL 886 YD sadede gbina.
Epo ẹnjini ọkọ naa lo gba ina lojiji, ti eeyan meje ninu awọn mẹrinla to wa ninu ọkọ Mazda akero naa si ba iṣẹlẹ naa lọ.
Babatunde Akinbiyi, tii se agbẹnusọ fun ajọ to risi akoso isẹlẹ ijamba ni ipinlẹ Ogun ni awọn meje tori ko yọ ninu ijamba naa ni wọn wa ni ile iwosan pẹlu ọgbẹ orisirisi lara wọn.
Iṣẹlẹ ijamba naa lo waye ni deede aago mẹta ku iṣẹju mẹwa ọsan ọjọru.

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ọkọ bọọsi Mazda to gbina ọhun ko awọn ọmọ ẹgbẹ to n lọ fun idanilẹkọ
Akinbiyi ni ọkọ ayọkẹlẹ Mazda naa ko ero marundinlogun pẹlu dirẹba, ti mẹrinla ninu wọn si jẹ ọdọmobinrin.
Ori ko awon mejọ yọ ninu wọn, ti awọn meje to sẹku si ba iṣẹlẹ naa lọ
Ọkọ ayọkẹlẹ naa lo n bọ lati agbegbe Kosofe nipinlẹ Eko, ti o si morile agbegbe EPE fun idanilẹkọ kan.
Awọn to farapa ninu iṣẹlẹ naa ni wọn gbe lọ si ile iwosan ijọba ipinle Ogun to wa ni Ijebu Ode.
















