Uji kó sí gbaga ọlọ́pàá fẹ́sùn pé ó ju òkú ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ sínú igbó lẹ́yìn tó ṣekúpa tán

Oríṣun àwòrán, JERRY B ACHIRKPI
Obinrin kan nipinlẹ Enugu, Madam Uji ni wọn fi ẹsun iṣekupani kan pe o ṣekupa ọmọ ọdọ rẹ to jẹ ọmọ ọdun mẹwaa, Precious Korshima, to si tun ju ọku ọmọ naa sinu igbo.
Iroyin lori iku ọmọde naa bọ sori ayelujara lẹyin ti baba ọmọ naa, Jerry B Achirkpi pariwo sita, to n bere fun iranlọwọ awọn ọmọ Naijiria.
Achirkpi ni obinrin naa fi ẹnu ara rẹ so pe oun ṣekupa ọmọdebinrin naa to si tun ju oku rẹ sinu igbo.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Enugu, Daniel Ndukwe sọ fun ileeṣẹ BBC pe otitọ ni pe isẹlẹ naa waye, ti afurasi ọhun si ti wa ni atimọle ileeṣẹ ọlọpaa.
Ndukwe ni awọn yoo tẹsiwaju ninu iwadii awọn lati tẹ imọlẹ si ọrọ naa
Bawo ni isẹlẹ ṣe waye?
Baba ọmọ ọhun, Achirkpi ni ninu oṣu kẹta ọdun 2022 ni oun fun Madam Uji ni ọmọ ko ma ṣe isẹ ọmọ ọdọ.
O ni obinrin ṣe ileri lati ran ọmọ oun lọ si ile ẹkọ nigba ti ọmọ oun n ba tọku ọmọ rẹ tuntun to ṣeṣe bii.
“Ọmọ mi wa lọdọ Madam Uji titi di oṣu kọkanla ọdun yii, sugbọn awọn ajinigbe kan pe mi awọn ti ji Ujunwa, ọmọ rẹ ati ọmọ mi ti wọn si bere fun ogun milọnu naira owo itusilẹ.
“Lọjọ kẹdogun, ẹgbọn Uji pe mi pe awọn ti tun wọn si lẹ. Nigba ti mo pe Uji, o sọ fun mi pe awọn adigunjale yibọn lu ọmọ mi, ti w#on si ni ki ma bọ ni agọ ọlọpaa.
“Nigba ti mo bere pe oku ọmọ mi da, Uji ni ẹru n ba oun lo oun fi ju oku ọmọ mi sinu igbo ni agbegbe Ituku Ozalla.”
Achirkpi ni awọn ara agbegbe ọhun ni awọn ti sin oku ọmọ nigba ti oorun gbalẹ.
Kini Ileeṣẹ Ọlọpaa sọ?
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Enugu, Daniel Ndukwe fi idi isẹlẹ naa fun ileeṣẹ BBC.
Ndukwe ni ọwọ ti tẹ obinrin ọhun sugbọn iwadi si n lọ lọwọ lori isẹlẹ naa
“Lọwọ ti a wa bayi, a ko le ti sọ ohun kohun lori isẹlẹ naa.
“Iwadii si n lọwọ lori isẹlẹ naa.”















