Obasanjo lọ́wọ́ sí ìdíje Peter Obi àti Labour party – Akin Osuntokun

Oríṣun àwòrán, Peter Obi
Adari tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan fun igbimo ipolongo ibo aarẹ fun ẹgbẹ oṣelu Labour ni Naijiria, Akin Ọṣuntokun ti sọ pe aarẹ Naijiria tẹlẹ Oluṣẹgun Obasanjọ n ṣe atilẹyin fun ero ipolongo ibo, oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu naa, Peter Obi.
Alagba Ọṣuntokun sọ eyi di mimọ nigba to n dahun ibeere lori eto ileese Mohunmaworan abẹle kan ni Naijiria, Channels Television.
Ọṣuntokun ni ọwọ atilẹyin Obasanjọ wa lara Peter Obi.
Lojo Iṣẹgun ni wọn kede Akin Ọṣuntokun gẹgẹ bí adari tuntun fun igbimọ ipolongo ẹgbẹ oselu Labour ti Peter Obi ti n dije, lẹyin ti Doyin Okupe to di ipo naa mu tẹlẹ kọwe fipo silẹ pẹlu bi Ile ẹjọ gíga apapọ kan nilu Abuja daa lẹjọ lọjọ kọkandinlogun oṣu kejila pe o jẹbi ẹsun kiko owo ilu na l’ọna ti ko tọ.
Ọṣuntokun ni ibanujẹ to dapọ mọ ayọ ni ọrọ ifiposilẹ Okupe jẹ paapaajulọ bi eeyan ba wo ọna to gba jade.
Ta ni Akin Osuntokun, alákòsóo àgbà tuntun fún ìpolongo ìbò Peter Obi?

Oríṣun àwòrán, Labour Party
Ẹgbẹ oṣelu Labour ti kede iyansipo Akin Osuntokun gẹgẹ bi alakoso agba fun ikọ ipolongo fun ipo aarẹ ninu ẹgbẹ oselu naa.
Akọwe agba fun ẹgbẹ oṣelu Labour, Julius Abure, lo kede iyansipo naa lẹyin ipade ti awọn olori ẹgbẹ Labour ṣe pẹlu oludije ṣipo aarẹ, Peter Obi.
Osuntokun lo tí figba kan jẹ amugbalẹgbẹ ọrọ oṣelu fun aarẹ tẹlẹri, Olusegun Obasanjo.
Oun si lo n rọpo Doyin Okupe to kọwe fipo naa silẹ laipẹ yii lẹyin ti ile ẹjọ giga kan ni Abuja fi ẹsun iwa ibajẹ kan.
Ṣaaju iyansipo naa, Osuntokun jẹ alaga ipolongo ẹgbẹ oṣelu Labour fun ẹkun guusu.
Akin Osuntokun tii se ẹni ọgọta ọdun, ni baba rẹ ti jẹ minisita ri labẹ Oloye Obafemi Awolowo ati oloye Ladoke Akintola.
Akin Osuntokun tii se ọmọ bibi ilu Ekiti, lo kẹkọọ gboye ninu ẹkọ nipa imọ oṣelu.
O si ti fi igba kan jẹ alakọso eto idibo aarẹ lọdun 2007 nigbati Umaru Musa Yar'Adua dije du ipo aarẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ṣaaju ni Doyin Okupe ẹniti o jẹ alakọso eto ipolongo fun ipo aarẹ ẹgbẹ Labour kọwe fi ipo rẹ silẹ ni ogunjọ oṣu kejila ọdun yii lẹyin ti ile ẹjọ kan ni Abuja fi ẹsun iwa ibajẹ kan.
Ninu iwe ifiposilẹ rẹ, Doyin Okupe rọ ẹgbẹ Labour lati yan ẹlomiran, ki oun le raye wẹ ara oun mọ ninu awọn ẹsun ti ajọ EFCC fi kan...















