Ọba eléré bọ́ọ̀lù àti èmi: Àwọn ohun mánigbàgbé nípa akọni agbábọ́ọ̀lù

Pele

Ìgbà ìkẹyìn tí mà á rí Pele nígbà tí a pàdé ní ẹ̀yìn káńtà ilé oúnjẹ Subway ní Central London níbi tó ti ń gbìyànjú láti fi sàláàdì sínú búrẹ́dì.

 Inú oṣù karùn-ún ọdún 2015 ni àmọ́ kìí ṣe wí pé ìgbà ti yí padà sí àìda fún èèkàn agbábọ́ọ̀lù yìí, àjọmọ̀ ilé oúnjẹ yìí tí Pele ń ṣiṣẹ́ fún gẹ́gẹ́ bí aṣojú lẹ́yìn tó fi gbígbá bọ́ọ̀lù sílẹ̀ ni. 

Nígbà náà èmi àti Pele ti pàdé dáadáa tó jẹ́ wí pé ó máa ń rẹ́rìn-ín sími nígbà tó bá pàdé mi láàárín àwọn akọ̀ròyìn débi tó gbà láti ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú mi.

 Ohun kan tó dùn mọ́mi nínú jùlọ ní ọ̀sán ọjọ́ náà ni pé Pele pẹ̀lú ọjọ́ orí rẹ̀ ní ẹni ọdún mẹ́rìnléláàdọ̀rin ṣì wà ní àláfíà pípé.

Mo sọ fún pé ó kó àwọn ènìyàn sínú ìpayà pẹ̀lú òwò ilé ìwòsàn tó ń ṣe ni.

 Ó fún mi lésì pẹ̀lú ẹ̀rín pé ṣé o gbàgbé pé ìlú Tres Coracoes (ọkàn mẹ́ta ní ara Pọtugí) ni wọ́n bími sí. Ó sọṣòro láti fi ẹ̀yìn ènìyàn tó ní ẹ̀mí mẹ́ta janlẹ̀. 

Pele

Ọdún kan lẹ́yìn rẹ̀, nígbà tó kópa níbi ayẹyẹ kan tí àjọ FIFA ṣe ní Zurich, Pele dàbí ẹni tó ti ń ṣe àárẹ̀ fún ọjọ́ pípẹ́ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn akọ̀ròyìn tó wà níbẹ̀ sì ń rò ó pé bóyá kò ní pẹ́ tí ọlọ́jọ́ fi máa dé.

 Àṣẹ̀yìnwá àṣẹ̀yìnbọ̀ Pele ti ń bá àìsàn kidinrin fínra èyí tó peléke si nítorí pé ó ti pàdánù kíndìnrín kan láti ìgbà èwe rẹ̀ ní 1970 nígbà tó ń gbá bọ́ọ̀lù ní ojú méjèèjì.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

 Láti ìgbà náà tí a bá ti pàdé ni mo máa ń rò ó pé kí ló ṣẹlẹ̀ gan.

 Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olólùfẹ́ eré bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá pàápàá fún àwọn olólùfẹ́ orílẹ̀ èdè Brazil, agbábọ́ọ̀lù tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Edson Arantes do Nascimento jẹ́ àkàndá ẹ̀dá àfi bí ẹni wí pé òun nìkan ló kọ́kọ́ gbá bọ́ọ̀lù rí.

 Pele gan ni wọn ò bá máa pè ní bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá gan.

 Pele ni agbábọ́ọ̀lù tó gbégbá orókè níbi ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé ní ẹ̀ẹmẹ̀ta gẹ́gẹ́ tó sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún nígbà tí wọ́n gba àkọ́kọ́ ní ọdún 1958.

 Ọdún méjìlá lẹ́yìn rẹ̀ ni orílẹ̀ èdè Brazil tún gba ife ẹ̀yẹ náà ní orílẹ̀ èdè Mexico.

 Ọ̀kan lára àwọn tó gbóríyìn fún ipa Pele ni ọ̀rọ̀ tí ọmọ orílẹ̀ èdè Italy, Tarcisio Burgnich tí wọ́n fún níṣẹ́ pé kò má jẹ̀ ẹ́ kí Pele rí ọ̀nà lọ.

 "Mo sọ fún ara mi ní ìbẹ̀rẹ̀ eré pé ṣebí ènìyàn ni òun náà bíi ti àwọn yòókù àmọ́ irọ́ gbá à nítorí ó yàtọ̀ gédégédé síwọn.

 Pele jẹ góòlù kan tó sì tún fàyè méjì sílẹ̀ bí Brazil ṣe gba ife ẹ̀yẹ àgbáyé fún ìgbà kẹta. Góòlù kan tó jẹ náà ju ọ̀pọ̀ góòlù tí yóò tún jẹ níbi àpapọ̀ bọ́ọ̀lù tí yóò tún gbá ní ayé rẹ̀.

Jíjẹ ògo orílẹ̀ èdè

Pele

Pele fi àpẹẹrẹ tó kọjá bọ́ọ̀lù lásán èyí tó mú kí Andy Warhol yí ọ̀rọ̀ rẹ̀ padà pé sẹ́ńtúrì mẹ́ẹ̀dógún ni òkìkí Pele yóò lò dípò ohun tó kọ́kọ́ sọ pé kò lè ju ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún lọ.

 Pele ti fi gbígbá bọ́ọ̀lù fún orílẹ̀ èdè rẹ̀ kalẹ̀ ṣáájú kí wọ́n tó bími ní ọdún 1973 ṣùgbọ́n gbígbé tí mo gbé ní Brazil jẹ́ kí n máa gbọ́ ìròyìn àwọn ipa tó kó sí eré bọ́ọ̀lù.

 Ní àfikún sí ṣíṣe ìrànwọ́ fún bí Brazil láti di orílẹ̀ èdè tó ṣe àṣeyọrí nípasẹ̀ bọ́ọ̀lù, Pele tó jẹ́ adúláwọ̀ tún ṣe ohun tó tayọ: ó di ohun àlùṃọ́nì fún orílẹ̀ èdè tó jẹ́ wí pé òwò ẹrú àti ìyàsọ́tọ̀ ló jẹ́ ohun tí wọ́n mọ̀ wọ́n mọ́ láyé àtijọ́.

 Òun ni ọmọ orílẹ̀ èdè Brazil tó gbajúmọ̀ jùlọ. Gbogbo ibi tí mo bá dé - láti New York lọ sí ilẹ̀ adúláwọ̀ - òun ni àwọn ènìyàn kọ́kọ́ máa ń bèèrè rẹ̀ lọ́wọ́ mi nígbà tí mo bá ti sọ ibi tí mo ti wá fún wọn.

 Pele náà ni àwọn tó jẹ́ alátakò rẹ̀. Àwọn kan wà tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ pé ó yẹ kó sọ̀rọ̀ lòdì ìjọba ológun tó fi ọwọ́ líle tukọ̀ Brazil láàárín ọdún 1964 sí 1985.

Pele

Nínú eré sinimá Netflix kan lọ́dún 2021, Pele sọ pé kò sí nǹkankan tí agbábọ́ọ̀lù kankan le ṣe nígbà náà láti mú àyípadà kan títẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lójú lábẹ́ ìṣèjọba ológun ìgbà náà.

 "Tí mo bá sọ wí pé mi ò mọ̀ nípa gbogbo àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ nígbà náà, á jẹ́ wí pé irọ́ ni mo ń pa àmọ́ kò sí ẹni tó mọ nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ ní pàtó.

Ètò òṣèlú

Pele

Pele ni ìdí tí òun kò ṣe gbá bọ́ọ̀lù fún orílẹ̀ èdè òun lọ́dún 1974 jẹ́ ojúnà láti fẹ̀hónúhàn lórí ìjọba ológun. 

 Ní ọdún 2014, ọ̀pọ̀ èèyàn ló bu ẹnu àtẹ́ lu Pele pé ó ń tí ìwà elẹ́yàmẹ̀yà lẹ́yìn níbi ìdíje eré ìdárayá Brazil kan pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tó sọ pé onírúurú ìwà elẹ́yàmẹ̀yà tó yẹ kó mú òun dá gbígbá bọ́ọ̀lù dúró àmọ́ tí òun kò ṣe bẹ́ẹ̀.

 Bákan náà ni ọ̀rọ̀ ìgbésí ayé tirẹ̀ náà máa ń fa onírúurú awuyewuye - ìgbà tí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin Edson wà ní àhámọ́ fẹ́sùn gbígbé egbògi olóró àti kíkọ̀ láti sọ ohunkóhun sí gbígba Sandra gẹ́gẹ́ bí ọmọ tí ẹnì kan bí fún-un nígbà tó wà ní èwe ni ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1960.

 Nínú eré onítàn Netflix náà, Pele gbà wí pé òun ni ìbálòpọ̀ pẹ̀lú onírúurú obìnrin nígbà tí òun wà ní èwe tí òun kò sì le sọ ní pàtó iye ọmọ tí òun bí.

 Ní ọdún 1977 ni Pele juwọ́ ó dìgbà sí bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá lẹ́yìn tó fìdí rẹmi níbi ìdíje bọ́ọ̀lù tó jẹ́ ti orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà kan.

 Kò padà láti máa ṣe àkóso bọ́ọ̀lù mọ́ láti ìgbà náà.

 Láàárín ọdún 1995 sí ọdún 1998 ló ṣe Mínísítà féré ìdárayá Brazil, tó sì tún máa ń kópa nínú àwọn sinimá àgbéléwò bíi Escape to Victory.

 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Iléeṣẹ́ ìjọba àti Iléeṣẹ́ ńláńlá ni Pele polongo fún ní èyí tó máa ń bọ́ sí yẹ̀yẹ́ nígbà mìíràn bíi ìgbà tó polówó fún òògùn àìlèṣedédé ọmọkùnrin ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2000.

 Pele jẹ́ eléré ìdárayá tí àwọn akọ̀ròyìn máa ń lọ láti wí tẹnu rẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà nítorí kìí ṣe ìgbéléwọ̀n ọ̀rọ̀ rẹ̀ kó tó sọ ọ́ kódà bí yóò ba ta bá àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ tó gbajúmọ̀.

 Ọ̀kan nínú àwọn agbábọ́ọ̀lù Brazil kan Romario nígbà kan sọ wí pé akéwì ni Pele nígbà tó bá dákẹ́.

 Bákan náà ló máa ń sọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí kò ní wá sí ìmúṣẹ.

 Pele ló sọ ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1970 pé orílẹ̀ èdè adúláwọ̀ yóò gba ife ẹ̀yẹ àgbáyé kó tó di ìbẹ̀rẹ̀ sẹ́ńtúrì Kọkànlélógún ṣùgbọ́n títí di àsìkò yìí, orílẹ̀ èdè adúláwọ̀ kan ló ṣẹ̀ṣẹ̀ dé ipele tó kángun sì abala àṣekágbá.

 "Ipa tí mo ti kó nínú eré ìdárayá gbà mí láyè láti sọ ohun tó bá wà ní ẹ̀mí mi síta."

 Láti ìgbà tí Lionel Messi ti wọ agbo eré bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá ni àwọn ènìyàn kan ti ń sọ pé ó ti gba ipò agbábọ́ọ̀lù tó dáńtọ́ jùlọ láyé lọ́wọ́ Pele àmọ́ Pele ní ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀.

 "Mo lè fi orí jẹ góòlù, mo lè lo ẹsẹ̀ méjèèjì àmọ́ ẹsẹ̀ òsì nìkan ni Messi le lò, ó nílò láti jẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ góòlù náà," Pele sọ ní ìlú London.

 Ó wù mí kí n lè sọ fún Pele pé Argentine kò ì tíì gba ife ẹ̀yẹ àgbáyé ní ẹ̀ẹ̀mẹ̀ta.

 Ọ̀rọ̀ yìí máa ń mú Pele rẹ́rìn-ín. Mà á ṣe àfẹ́kù ẹ̀rín yìí gidi.