Wo àwọn àṣà tó gbalẹ̀ kan lọ́dún 2022

Awon asa odun 2022

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Gbogbo ọdun lo n wa pẹlu awọn aṣa ti awọn eeyan maa n da. Awọn aṣa wọnyi lo gbalẹkan laarin ọdun 2022.

Awọn aṣa bẹẹ le waye latipasẹ orin, sinima ọjọ pipẹ tabi awọn ọrọ ori ayelujara tabi itakurọsọ to di agbatung a lori ayelujara.

Bi odun yii ṣe n pari lọ, a ni ka mu awọn aṣa to gbalekan lọdun naa wa si eti igbọ yin.

Shey you dey whine me ni

Shey u dey whine me ni

Oríṣun àwòrán, Instagram

Aṣa yii ko ni pato orisun kan, awọn agbero si kun awon to lo o ju lọdun 2022.

Aṣa yii pada jẹyọ nigba ti akọrin ẹmi Austin De Bull tun jade pẹlu orukọ kan naa loṣu kẹwaa ọdun 2022.

Aṣa yii gbilẹ pẹlu orin rẹ ninu awọn itakurọsọ ori ayelujara ati ibagbepọ.

Dem never see me coming

Dem never see me coming

Oríṣun àwòrán, Twitter

Gbajumọ akọrin takasufe, ti gbogbo eeyan mọ si Asake lo jẹ ki aṣa yii gbilẹ pẹlu bi o ṣe fi kọrin ninu orin “bandana” ti Fireboy kọ.

Igba ti eeyan kan ba n sọrọ nipa ohun kan ti wọn se ti wọn fi ya eeyan kan lẹnu ni wọn ti maa n lo ede yii. Ohun gan la le sọ pe wọn fi rọpo aṣa “e shock you” to gbilẹ tẹlẹ.

Dey Play

Aderininposonu

Oríṣun àwòrán, Tiktok

Ori ayelujara leyi ti kọkọ jẹyọ laarin awọn eekan ilumọọka ori ayelujara nigba ti wọn ba n ṣe ajọyọ lori awọn dukia wọn.

Fun apẹrẹ, bi wọn ba ṣẹṣẹ ra ile, wọn le pariwo “Just dey play”

O tumọ si pe bo ba wu ẹ maa tẹpamọṣẹ, o ko le laluyọ bii tiwọn.

Emi Lo kan

Emi lo kan

Oríṣun àwòrán, Instagram

Oludije fun ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC, Bọla Ahmed Tinubu lo lo ọrọ yii ninu ọrọ apilẹkọ kan to ka ni ipinlẹ Ogun loṣu kẹfa ọdun 2022 ti awọn eeyan si ti n lo kaakiri.

Miracle no dey taya Jesus

Aso miracle no dey tire Jesus

Oríṣun àwòrán, Twitter

Inu orin ẹmi kan ti akọrin ẹmi, Mayor Thompson gbe jade lọdun 2021.

Amoṣa nigba ti ọdun ba fẹ pari ni aṣa yii maa n gbalekan lati toka sí awọn aṣeyọri wọn laarin ọdun.

Awọn kan n lo o gẹgẹ bi ẹri ọpẹ, awọn miran n fi ṣe awada lasan ni.

Something hooge

Something huge is coming

Oríṣun àwòrán, Twitter

Gbajumọ adẹrinpoṣonu ori ayelujara, Sabinus lo gbe asa yii ga ninu ere awada rẹ kan lo ti rọ onileeṣẹ POS kan pe ko di ATM oun mu lati fi ya oun lowo nitori pe oun n reti nnkan rabandẹ kan ti o pe ni something hooge.

So pe Otilo

Asa otilo

Oríṣun àwòrán, Twitter

Eyi jẹyọ jade ninu orin Otilọ (Izz Gone) ri Poco lee ati HotKid gbe jade.

"Dem don dey carry me go wia I no know"

Olopaa to bere dem dey carry me go wia I no know

Oríṣun àwòrán, Instagram

Ninu orin Otilọ ni aṣa "Dem don dey carry me go wia I no know" pẹlu ti jade. Eyi lee tumọ si rukerudo tabi ti onimọto ba n gbe ewyan kọja ibi to n lọ.

Fidio ori ayelujara kan to ṣe afihan obinrin olopaa kan ti n pariwo e ki wọn da ọkọ to wọ nibi to fẹ da ọkọ naa duro.

God abeg

oogun God abeg

Oríṣun àwòrán, Twitter

Portable, akọrin takasufe lo sọ eyi nigba to n kọ orin rẹ kan.

Fidio yii lo wa gbilẹ lori ayelujara ti awọn eeyan sii gba a tọwọ tẹsẹ.

Japa

Awon ero ni paspako ofurufu

Oríṣun àwòrán, Instagram

Laipẹ yii, aṣoju ijọba ilẹ Faranse ni Naijiria, Madam Emmanuelle Blatmann n beere pe ki ni itumọ “Japa” lawọn ọmọ Naijiria kan ba fẹ da a lori ru pe ẹmi ijafafa lẹnu iṣẹ lo n jẹ bẹẹ.

Japa n tọka si bi awọn ọmọ Naijiria ṣe n sare lo si oke okun. Lẹnu lọwọ yii ọpọ ọmọ Naijiria lo n sare lọ si oke okun lati wa ọna abayọ fun Aye wọn.

Naira Marley, gbajumọ akọrin ọmọ Naijiria lo sọ aṣa yii di gbajugbaja ninu orin Japa to kọ lọdun 2018.

O tun ti Zeh

Portable olorin Za Zu Zeh

Oríṣun àwòrán, Twitter

Gbajumọ akọrin takasufe, Portable lo gbe eyi kalẹ. Nigba ti nnkan ayọ ti eeyan ko f’ọkan si ba ṣẹlẹ ni aṣa yii saba maa n jẹyọ. nigba yii lawọn eeyan maa n pariwo pe “O tun ti zhe o.” Ninu awo orin rẹ, Zazu Zhe.

Àkọlé fídíò, Florence Ajimobi: Ọkọ mi fẹ́ ká rántí òun bíi Bàbá ìpínlẹ̀ Oyo tuntun

Woto Woto

Aṣa yii jẹ aṣa awọn ọmọ ita lẹkun aringbungbun gusu Naijiria.

Lọdun 2022 lasa yii tun gbilẹ kọja ẹkun naa bayii. Awọn ewyan bẹrẹ si nii lo o lati ṣe apejuwe nnkan to pọ

Breakfast

“E don cast, last-last, na everybodi go chop..."

Ounjẹ aarọ loyinbo n pe ni breakfast ṣugbọn ni Naijiria bayii aṣa breakfast ti yii eyi pada.

ọrọ yii ni wọn n lo fun ipinya laarin awọn ololufẹ meji

gbajumọ olori Burnaboy lo fi eyi kọrin.

E plenti

Burna boy lo tun fi eyi kọrin ninu awo orin rẹ ninu awo orin rẹ Damini.

Bi eeyan ba fẹ kan sara si nnkankan, bi aṣọ, ẹwa ati bẹẹbẹ lọ ni aṣa yii maa n waye.

As e dey pain dem

Eni to n jo sorin as e dey pain dem e dey sweet us

Oríṣun àwòrán, Twitter

Oselu lo mu aṣa yii wa.

"As e dey pain dem e dey sweet us".

Lasiko ọrọ apilẹkọ kan ti gomina ipinlẹ Rivers, Nyeaom Wike sọ nibi eto oselu kan bayii lorin yii ti jade

Gbajumọ akọrin Timaya tun wa gbe awo orin kan jade lori rẹ.

 Nigba ti awọn eeyan ba fẹ sọrọ nipa pe awọn eeyan n jowu aṣeyori wọn ni won maa n sọ ọrọ yii.

Nibo la tun ja si yii

Lara asa tuntun to tun gbilẹ lọdun 2022 ni asa nibo la tin ja si yii?

Akoko ti nnkan ti kii saba sẹlẹ ba waye ni awọn eeyan too maa sọrọpe nibo la tun ja si yii.

Asa yii si lo maa n wọpọ ti eeyan kan ba sadede sọrọ sita eyi ti ko ba ohun ti wọn n sọ mu