Nǹkan ńlá tí ọkọ mi ṣe fún mi jùlọ ní ìgbéyàwó ta ṣe ní ṣọ́ọ́ṣì lẹ́yìn ọdún 21 ta ṣe ìgbéyàwó ní kóòtù - Florence Ajimobi

Àkọlé fídíò, Florence Ajimobi: Ọkọ mi fẹ́ ká rántí òun bíi Bàbá ìpínlẹ̀ Oyo tuntun
Nǹkan ńlá tí ọkọ mi ṣe fún mi jùlọ ní ìgbéyàwó ta ṣe ní ṣọ́ọ́ṣì lẹ́yìn ọdún 21 ta ṣe ìgbéyàwó ní kóòtù - Florence Ajimobi

Florence Ajimobi: Ọkọ mi fẹ́ ká rántí òun bíi Bàbá ìpínlẹ̀ Oyo tuntun, n kò fẹ́ kí orúkọ rẹ̀ parẹ́

Odu ti kii se aimọ fun oloko ni Oloye Florence Ajimobi nitori oun ni aya gomina ana nipinlẹ Oyo to ti di oloogbe, Abiola Ajimobi.

Oun si ni obinrin akọkọ nipinlẹ Oyo lasiko ti ọkọ rẹ jẹ gomina fun saa meji nipinlẹ Oyo laarin ọdun 2011 si 2019.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Florence Ajimobi salaye bi oun ati ọkọ rẹ pade ati ajọsepọ to wa laarin wọn.

Bakan naa lo salaye ohun to waye laarin ijọba ipinlẹ Oyo ati idile Ajimobi lasiko isinku ọkọ rẹ.

Oloye Ajimobi tun sọrọ lori isejọba gomina Seyi Makinde, to si tun sọrọ nipa ẹni ti ipo aarẹ Naijiria tọ si.

Florence Ajimobi

"Abiola Ajimobi tún mi gbé nínú ìgbéyàwó alárinrin ní ṣọ́ọ́ṣì lẹ́yìn ọdun mọkanlelogun ta se igbeyawo ni kootu"

Oloye Florence Ajimobi salaye pe ohun kan soso to dun mọ oun ninu julọ ni bi ọkọ oun se se igbeyawo alarinrin fun oun ninu ijọ Katoliki.

O ni kootu ni awọn ti kọkọ se igbeyawo lọdun mẹẹdogun saaju ki awọn to lọ si sọọsi.

Gẹgẹ bo ti wi, Musulumi ni awọn ẹbi Ajimobi amọ Kristẹni ni oun, ti wọn si bẹ oun pe kootu ni awọn yoo ti se igbeyawo.

"Mo gba fun wọn bi o tilẹ jẹ pe ọrọ naa ko dun mọ mi ninu amọ lẹyin ọdun mọkanlelogun igbeyawo wa, ọkọ mi bi mi pe ki ni mo fẹ ki oun se fun mi.

Mo sọ fun pe oun to n wu mi julọ nigba naa ni pe ko se igbeyawo fun mi ninu sọọsi, ki emi naa wọ asọ funfun nitori iru igbeyawo ti ijọ Katoliki mọ ree."

Aya Ajimọbi ọkọ oun gba, tawọn si se igbeyawo ni sọọsi, koda o ni o tun se apejẹ nla fun oun lẹyin tawọn kuro ni sọọsi.

Abiola ati Florence Ajimobi

Oríṣun àwòrán, Florence Ajimobi

"Emi ni mo tilẹkun ile lọjọ isinku ọkọ mi, n ko mọ pe igbakeji gomina Oyo n bọ"

Nigba to n salaye ohun to waye lasiko isinku ọkọ rẹ, ti igbakeji gomina ipinlẹ Oyo nigba naa ko fi raye wọle sibẹ, Florence Ajimobi ni ọrọ ko ri bawọn eeyan se ro o.

O ni wọn ko fi to oun leti pe igbakeji gomina tabi asoju ijọba ipinlẹ Oyo n bọ rara, oun kan ti ẹnu ọna ile ni nigba ti adura fẹ bẹrẹ.

O ni inu apamọwọ ohun to wa loke ile ni ohun fi kọkọrọ ẹnu ọna ile naa si, ni kete ti wọn si wa pe oun pe igbakeji gomina ti de ni oun dide lọ silẹkun naa.

Amọ o ni wọn ti lọ sile nigba ti oun yoo fi silẹkun, ohun to waye naa kii si se amọọmọ se.

"Mo ti kọwe si wọn lati salye ohun to sẹlẹ lọjọ naa, mo si ti bẹ wọn pe ki wọn mase binu bi o tilẹ jẹ pe n ko mọ tẹlẹ pe wọn n bọ.

A ti bẹrẹ adura ki wọn to de, wọn si ti gba ẹbẹ mi, awa ati awọn naa si ti n se daadaa pada."

Abiola Ati Florence Ajimobi

Oríṣun àwòrán, Florence Ajimobi

"N ko le fi ijọba Makinde we ti Ajimobi, eto aabo gbopọn lasiko isejọba ọkọ mi ju bayii lọ"

Oloye Florence Ajimobi lasiko to n salaye isejọba ọrọ rẹ ni awọn lo ipo gomina fun ọdun mẹjọ lati se anfaani fun ọpọlọpọ eeyan.

O ni se ni awọn fi ipo naa ran ọpọ eeyan lọwọ, ti igba ọkọ oun si tu gbogbo eeyan ipinlẹ Oyo lara.

Amọ nigba to n se afiwe isejọba Abiola Ajimobi si ti gomina Seyi Makinde to wa nipo lọwọlọwọ bayii, Aya Ajimọbi ni oun ko mọ ohunkohun nipa isejọba Makinde.

O ni amọ o da oun loju pe eto aabo fẹsẹ mulẹ lasiko isejọba ọkọ oun ju bo se wa lasiko yii lọ.

"Ọkọ mi se daadaa nidi ipese eto aabo eyi ti ko si mọ bayii, emi ati Makinde ko si ninu ẹgbẹ oselu kannaa, n ko si le sọrọ nipa isejọba rẹ."

Florence Ajimobi

"N ko fẹ ki orukọ ọkọ mi parẹ, o fẹ ka ranti oun bii baba ipinlẹ Oyo tuntun"

Oloye Florence Ajimobi ni o se ni laanu pe ọkọ oun ko raye sọ itan ara rẹ fun araye lati se akọsilẹ rẹ, ki iku to mu lọ\.

Amọ o ni sibẹ, sibẹ, oun ko fẹ ki orukọ Abiola Ajimobi parẹ nitori ipa ribiribi to ko si idagbasoke ipinlẹ Oyo ati Naijiria lapapọ.

"Ọkọ mi nikan ni gomina to kọkọ lo ọdun mẹjọ nipo gomina nipinlẹ Oyo, idi si ree ti wọn fi n pe ni Kosẹlẹri.

O se gudugudu meje ati ya ya mẹfa nigba naa lati mu agbega ba ipinlẹ Oyo.

Ohun to si fẹ ni pe ta ba ranti rẹ, ka maa ranti rẹ bii Baba ipinlẹ Oyo tuntun."

Asiwaju Bola Tinubu ati Abiola Ajimobi

Oríṣun àwòrán, Florence Ajimobi

"2023 ni yoo sọ boya Naijiria yoo tubọ dojuru ni tabi yoo toro sugbọn Tinubu nikan ni oludije aarẹ to kajuẹ"

Lori eto idibo aarẹ ti yoo waye lọdun to n bọ, Florence Ajimobi ni idibo naa ni yoo sọ boya Naijiria yoo tubọ dojuru ni tabi yoo to.

O ni yoo san ta ba fẹ ki Naijiria toro, kawọn araalu dibo fun Oloye Bola Ahmed Tinubu nitori pe oun nikan soso lo kaato laarin awọn oludije yoku lati dari orilẹede yii.

"Ẹ jẹ ka dibo fun Tinubu nitori ninu awọn eeyan to n dupo aarẹ, oun nikan lo le se.

O loju aanu, o lawọ, bẹẹ si tun lo ni ọpọlọ pipe.