Ta ló pa ọmọ ẹgbẹ́ PDP l‘Oyo èyì tó fẹ́ fa wàhálà sílẹ̀ láàrin PDP àti APC?

Seyi Makinde ati Teslim Folarin

Ẹgbẹ oṣelu PDP ni fi ẹsun kan ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Oyo pe wọn lọwọ ninu iku ọmọ ẹgbẹ rẹ kan, Hakeem Mudashiru.

PDP ni awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC naa lo ṣekupa ọkunrin naa niluu Oyo.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Oyo, Akeem Olatunji fi lede, o ni ile mọlẹbi oloogbe naa ni awọn aṣekupani naa ti gba ẹmi Hakeem Mudashiru.

O ni laipẹ yii ni awọn pariwo sita lori bii awọn kan ṣe n paarọ paali ipolongo ibo Gomina Seyi Makinde, ti wọn si gbe ti oludije sipo aarẹ APC sibẹ.

Ọna ti ẹgbẹ APC n gbà ṣe oṣelu l‘Oyo le fa rogbodiyan - PDP

Ẹgbẹ oselu PDP nipinlẹ Oyo wa yan pe awọn osojumikoro to wa nibi isẹlẹ naa sọ fun ẹgbẹ pe, awọn janduku ọhun lo jẹ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC.

Olatunji wa kede orukọ olori awọn janduku to lewaju awọn janduku naa wa ṣekupa Hakeem Mudashiru.

Ẹgbẹ oṣelu PDP tẹsiwaju pe bi APC ṣe n ṣe oṣelu ipinlẹ Oyo lo ‘ṣeeṣe ko fa gbọnmisi-omioto’ nipinlẹ Oyo, ti ofin ko ba tete dide si wọn.

Olatunji ni gbogbo erongba APC ni lati da eto alafia to daa nipinlé Oyo ru.

Àkọlé fídíò, Quest University Ghana: Ìyá àti ọmọ bọ́ sọ́wọ́ gbájúẹ̀ fásitì torí ìyanṣẹ́lódì ASUU

Ija oselu kọ lo pa ọmọ ẹgbẹ PDP, àwọn janduku ni - Ọlọpaa

Wayi o, Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti sọrọ sita lori iku ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ Oyo, Hakeem Mudashiru, to padanu ẹmi rẹ lowurọ Ọjọru niluu Oyo.

Mudashiru ni iroyin ti n tan kiri pe awọn ọmọ ẹgbẹ oṣẹlu APC lo ṣe ikọlu si, ti wọn si gba ẹmi rẹ nigba ti ede ayede waye laarin wọn.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Olawale Osifeso, ninu atẹjade to fi lede ni ede ayede kan lo waye laarin oloogbe ati awọn janduku kan, ti wọn si gba ẹmi rẹ.

O tẹsiwaju pe baba oloogbe, Jimoh Agala lo fi to ẹka ileeṣẹ ọlọpaa ni Durbar leti ni dede ago kan abọ lọjọru.

"Ọwọ ti tẹ afurasi mẹsan an pẹlu obinrin kan lori iku Hakeem Modashiru"

Osifeso ni iwadi awọn fihan pe awọn janduku kan lo ṣekọlu si Mudasiru, ẹni to ti ba wọn ni ede ayede tẹlẹ.

“Ọwọ ti tẹ awọn afurasi mẹsan an bayi pẹlu obinrin kan ti wọn ni ẹjọ lati ro lori iku Hakeem Modashiru.

“A ti gbe ẹjọ lọ si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n ri si iwadi nipa iwa ọdaran, a si tẹsiwaju lori iwadi naa.

“Bakan na ni kọmisọna ọlọpaa nipinlẹ Oyo wa kesi awọn ọlọpaa lati wa ni agbegbe ti isẹlẹ naa ti waye .”