Wo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ gbankọgbì tó wáyé lọ́dún 2022

Ọ̀pọ̀ òjò ló ti rọ̀ tí ilẹ̀ ti fà mu. Ọ̀pọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ ló wáyé ní ọdún 2022 tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ rẹ̀ kò sì dùn mọ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà nínú.
Yàtọ̀ sí àwọn ọmọ Nàìjíríà, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọdún 2022 da omi tútù sí ọ̀pọ̀ lọ́kàn káàkiri àgbáyé tó fi mọ́ ilẹ̀ adúláwọ̀.
Láti orí eré ìdárayá, ètò òṣèlú, ètò ọrọ̀ ajé àti àyípadà ojú ọjọ́ ni ìṣẹ̀lẹ̀ ọdún 2022 fi ọwọ́ bà.
Bákan náà ni onírúurú ìjákulẹ̀, ikú àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ló tún wáyé lọ́dún 2022.
Bí àwọn orílẹ̀ èdè kan ṣe ń sapá láti lé iwájú ni àwọn mìíràn túnbọ̀ ṣì ń tẹ̀síwájú tí wọ́n ń gòkè àgbà si.
Bí ó ṣe ku ọjọ́ kan kí ọdún 2022 wá sí òpin, àwọn ènìyàn kan ṣì ní ìgbàgbọ́ pé oòrùn tó wà lókè ṣì lè sá aṣọ gbẹ, àyípadà ọ̀tún le wáyé láàárín wákàtí tó kù tí a ó fi bọ́ sínú ọdún tuntun.
Lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé nìwọ̀nyí
Ọ̀pọ̀ ènìyàn jápa kúrò ní Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Twitter
Kò dájú láti fìdí iye ènìyàn tó kúrò ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lọ sí ilẹ̀ òkèrè múlẹ̀ ní pàtó àmọ́ ohun tó dájú ni pé ọ̀pọ̀ èèyàn fi orílẹ̀ èdè yìí sílẹ̀.
Àwọn mìíràn lọ kàwé ní àwọn ilẹ̀ òkèrè yìí tó sì jẹ́ wí pé àwọn mìíràn kó gbogbo ẹbí wọn láti lọ bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé tuntun.
Oríṣiríṣi ìdí ló mú àwọn ènìyàn jápa kúrò ní Nàìjíríà àmọ́ kò sí ẹni tó lè jiyàn rẹ̀ pé àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ló jẹ́ kí ọ̀pọ̀ wọn fi orílẹ̀ èdè yìí sílẹ̀.
Ìkọlù Russia sí Ukraine

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Kò sí ẹni tó le gbàgbọ́ wí pé ogun le wáyé níbikíbi ní orílẹ̀ ayé níbi tí ojú là dé ní òde òní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ orílẹ̀ èdè a máa tá ohun síra wọn ṣùgbọ́n kì í sábà kọjá bẹ́ẹ̀.
Ní ìparí ọdún 2021, U. S., Britain àti àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn ń ṣèkìlọ̀ pé ó dàbí pé Russia fẹ́ kó ògùn ja Ukraine àmọ́ ọ̀pọ̀ ni kò ka ìkìlọ̀ náà sí.
Kódà Ààrẹ Ukraine fúnra rẹ̀, Volodymyr Zelensky kò gbàgbọ́ wí pé ogun ń bọ̀ wá ká òun mọ́.
Ní ọjọ́ Kẹrìnlélógún oṣù kejì ọdún 2022, Russia bẹ̀rẹ̀ ìkọlù sí Ukraine èyí tí wọ́n ní àwọn fi yọwọ́ àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ òkèrè kúrò ní Ukraine.
Bí Ukraine ṣe gbèrò láti dá ààbò bo ara wọn ló ṣokùnfà tí ìkọlù fi di ogun tó ṣì ń tẹ̀síwájú títí di àsìkò tí à ń kó ìròyìn yìí jọ.
Ìyanṣẹ́lódì ASUU

Oríṣun àwòrán, Twitter
Kì í ṣe ohun tuntun ní Nàìjíríà fún àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga Fásitì tó jẹ́ ti ìjọba láti máa yan iṣẹ́ lódì nígbà tí wọ́n bá ń bèèrè nǹkan lọ́wọ́ ìjọba.
Bẹ́ẹ̀ náà ló rí ní ọdún 2022 nígbà tí àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga Fásitì lábẹ́ ẹgbẹ́ wọn ASUU bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì lọ́jọ́ kẹrìnlá oṣù kejì ọdún 2022 láti ṣèkìlọ̀ fún ìjọba lórí àdéhùn tí ASUU àti ìjọba àpapọ̀ tọwọ́ bọ̀ ní ọdún 2009 èyí tí kò ì tíì wá sí ìmúṣẹ.
Oṣù mẹ́jọ gbáko ni ASUU fi gùnlé ìyanṣẹ́lódì yìí bí wọ́n ṣe ń fi ọjọ́ kún un ní gbogbo ìgbà kí wọ́n tó kéde ìyanṣẹ́lódì aláìní gbèdéke nígbà tí ìjọba kò dá lóhùn àwọn ìbéèrè wọn.
Ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Kẹwàá ọdún 2022 ni ASUU tó ṣẹ́wélé ìyanṣẹ́lódì náà lẹ́yìn tí ìjọba àpapọ̀ wọ ASUU lọ sí ilé ẹjọ́ tí ilé ẹjọ́ sì dájọ́ pé ASUU kò ní ẹ̀tọ́ láti gùnlé ìyanṣẹ́lódì.
Nàìjíríà kò pegedé láti kópa nínú ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Nàìjíríà ṣe dáadáa ní ìbẹ̀rẹ̀ ìdíje láti kópa níbi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé ọdún 2022 àmọ́ síbẹ̀ ikọ̀ Super Eagles kò kópa níbi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà.
Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ tó wáyé láàárín Ghana àti Nàìjíríà ló já Nàìjíríà kulẹ̀ nígbà tí Ghana fi ìyè góòlù tí wọ́n ti jẹ gbé Nàìjíríà.
Ètò ìdìbò abẹ́nú ẹgbẹ́ òṣèlú láti dupò Ààrẹ Nàìjíríà lọ́dún 2023

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ọ̀kan-ò-jọ̀kan ni àwon ohun ìyàlẹ́nu tó wáyé níbi ètò ìdìbò abẹ́nú àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú láti yan ẹni tí yóò gbé àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú wọn dání láti dupò Ààrẹ Nàìjíríà lọ́dún 2023 nígbà tí Ààrẹ Buhari bá parí sáà rẹ̀.
Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ló gbégbá orókè níbi ètò ìdìbò abẹ́nú APC lẹ́yìn tó fẹ̀yìn igbákejì Ààrẹ, Ọ̀jọ̀gbọ́n Yemi Osinbajo àti Mínísítà fétò ìrìnnà Rotimi Amaechi janlẹ̀.
Onírúurú awuyewuye ló tún ń wáyé nígbà tí Tinubu mú gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ Borno, Kassim Shettima gẹ́gẹ́ bí igbákejì rẹ̀ nítorí pé àwọn méjèèjì jẹ́ mùsùlùmí.
Bákan náà ni Atiku Abubakar jáwé olúborí níbi ètò ìdìbò abẹ́nú PDP tí ìyànsípò gómìnà Ifeanyi Okowa gẹ́gẹ́ bí igbákejì rẹ̀ sì ń wá wàhálà nínú ẹgbẹ́ PDP títí di àsìkò tí à ń kó ìròyìn yìí jọ.
Gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ Anambra, Peter Obi ni ìyànsípò bá àwọn ènìyàn lójijì bó ṣe fi ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sílẹ̀ lọ sí Labour Party.
Ọ̀pọ̀ ènìyàn ni kò gbàgbọ́ pé olùdíje kan gbòógì tún le jáde yàtọ̀ sí àwọn ti ẹgbẹ́ òṣèlú PDP àti PDP tó ti gbajúmọ̀.
Làásìgbò ètò òṣèlú ilẹ̀ UK
Kì í ṣe ohun tó dùn-ún gbọ́ sétí pe ẹnu ń kun ètò ìṣèjọba ní sáà olóòtú ìjọba orílẹ̀ èdè kan ṣùgbọ́n wọn ò rí ọgbọ́n dá si ní UK lọ́dún 2022.
UK tó jẹ́ àwòkọ́ṣe fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè káàkiri àgbáyé nípa ètò òṣèlú yàn olóòtú ìjọba mẹ́ta láàárín oṣù méjì.
Kò dín ní àwọn àádọ́ta Mínísítà tó kọ̀wé fipò wọn sílẹ̀ lásìkò Boris Johnson tí òun náà sì pàpà kọ̀wé fipò rẹ̀ sílẹ̀ èyí tó mú ìyànsípò Liz Truss gẹ́gẹ́ wáyé.
Liz Truss náà kò lò oṣù méjì lórí oyè tó fi kọ̀wé fipò rẹ̀ sílẹ̀ nítorí kò le ṣàlàyé àwọn ètò ọrọ̀ ajé tí ìjọba rẹ̀ gbé dání tó sì ń ṣàkóbá fówó pọ́ùn.
Lẹ́yìn tí Truss kọ̀wé fipò sílẹ̀ ni wọ́n yan Rishi Sunak gẹ́gẹ́ bí olóòtú ìjọba tuntun.
Ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí ọmọ ilẹ̀ òkèrè yóò jẹ olóòtú ìjọba UK nítorí ọmọ orílẹ̀ èdè India ni Rishi Sunak.
Ikú Ọbabìnrin Elizabeth

Nínú oṣù Kẹsàn-án ọdún 2022 ni ọbabìnrin Elizabeth kejì, tó jẹ́ ọba tó pẹ́ lórí òye ọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì jùlọ dágbére fáyé.
Ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ̀rún ni ọbabìnrin Elizabeth lò lókè eèpẹ̀ tó sì jẹ ọba fún àádọ́rin ọdún láti ọdún 1952.
Àkọ́bí ọmọ rẹ̀, Oba Charles kẹta ló gbà ipò ìyá rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba UK láti ìgbà tí ọbabìnrin ti papodà.
Ọ̀pọ̀ àwọn olórí orílẹ̀ èdè káàkiri àgbáyé ló kópa níbi ètò ìsìnkú ọbabìnrin Elizabeth.
Ilé ẹjọ́ tú Nnamdi Kanu, olórí ikọ̀ IPOB sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, Others
Nínú oṣù kẹwàá ọdún 2022 ni ile ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn kan tó wà ní ìlú Abuja da ẹjọ́ tí ìjọba àpapọ̀ pè tako Nnamdi Kanu tó jẹ́ olórí ikọ̀ tó ń pè fún ìdásílẹ orílẹ̀ èdè Biafra nù.
Ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni mẹ́ta tí adájọ́ Jummai Hannatu ṣáájú rẹ̀ ní ilé ẹjọ́ gíga tó kọ́kọ́ dájọ́ Nnamdi Kanu kò ní ẹ̀tọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí ìjọba àpapọ̀ kò gba ọ̀nà tó tọ́ láti fi mú Kanu wá sí Nàìjíríà.
Bákan náà tún ni ilé ẹjọ́ kò ní àṣẹ láti máa fi Kanu sí àhámọ́ àmọ́ ìjọba ní Kanu ṣì máa wa ní àhámọ́ nítorí àwọn ṣì ń lọ sí ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ.
NDLEA ṣàwárí oògùn olóró tó pọ̀ jùlọ ní Nàìjíríà
Àjọ tó ń gbógun ti egbògi olóró ní Nàìjíríà, NDLEA, ṣàwárí egbògi olóró olówó iyebíye ní ilé kan ní agbègbè Ikorodu ní ìpínlẹ̀ Eko.
NDLEA ní egbògi olóró tó pọ̀ jùlọ tí àwọn máa ṣàwárí rẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo nìyí èyí tí owó rẹ̀ lé ní igba mílíọ̀nù dọ́là.
Ní agbègbè Badagry ní ìpínlẹ̀ Eko ni NDLEA ti dáná sún lára àwọn egbògi náà lẹ́yìn tí wọ́n rí àṣẹ ilé ẹjọ́ gíga gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀.
Alaafin Oyo, Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi Kẹta waja

Oríṣun àwòrán, Alaafin of Oyo/Facebook
Ọjọ Abamẹta, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹrin, ni Alaafin Lamidi Olayiwola Adeyemi III waja.
Ọdun mejilelaadọta lo lo lori itẹ.
Se ni gbogbo orilẹede Naijiria ati awujọ agbaye rọ kẹkẹ lori bi ọba nla naa se papoda.
Aisan ranpẹ lo se Ọba Adeyemi to fi dara pọ awọn baba nla rẹ, ti wọn si fi iyoku ara si iboji awọn ọba Oyo yoku ni Bara.
Davido pàdánù ọmọ rẹ̀, Ifeanyi

Oríṣun àwòrán, Others
Ẹ̀ka eré ìdárayá Nàìjíríà pàdánù àwọn ènìyàn ní ọdún yìí púpọ̀. Ikú gbajúgbajà olórin èmi Osinachi Nwachukwu tó kọrin Ekwueme, Rico Swavey àti Sammie Okposo da àwọn ènìyàn sínú ìbànújẹ.
Àmọ́ èyí tó da omi tútù sí àwọn ènìyàn lọ́kàn tó sì gbalẹ̀ káàkiri àgbáyé ni ìpapòdà ọmọ gbajúgbajà olórin tàkasúfèé Davido, Ifeanyi Adeleke.
Ìròyìn ní nínú adágún omi tó wà ní ilé Davido tó wà ní Banana Island ní Eko ni wọ́n ti bá òkú ọmọ náà.
Ìdíje ẹ̀yẹ àgbáyé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé tó wáyé ní Qatar ni a fi kásẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ gbankọgbì tó wáyé lọ́dún 2022 nílẹ̀.
Orílẹ̀ èdè Argentina ló gba ife ẹ̀yẹ náà lẹ́yìn tí wọ́n na orílẹ̀ èdè France níbi àṣekágbá rẹ̀.
Ìdíje yìí ni ọ̀pọ̀ ènìyàn gbà pé ohun ló dùn jù láti ìgbà tí wọ́n ti ń gbá ife ẹ̀yẹ àgbáyé.
Pele, akọni agbabọọlu jade laye
Ogbotanrigi agbabọọlu tẹlẹ fun orilẹede Brazil, Pele, ti jade laye lẹni ọdun mejilelọgọrin.
Pele, ti orukọ abisọ rẹ n jẹ Edson Arantes do Nascimento, ni wọn bi saye lọjọ kẹtalelogun ọdun 1940 ni Três Corações, lorilẹede Brazil
Pẹle nikan ni agbabọọlu to gba ife ẹyẹ agbaye fun ikọ Brazil ni igba mẹta ọtọtọ, lọdun 1958, 1962 ati lọdun 1970.

















