Bobrisky bu ẹnu àtẹ́ lu Jay Boogie lórí iṣẹ́ abẹ tó ṣe láti fọn ìdí tó bẹ́yìn yọ
Bobrisky bu ẹnu àtẹ́ lu Jay Boogie lórí iṣẹ́ abẹ tó ṣe láti fọn ìdí tó bẹ́yìn yọ

Oríṣun àwòrán, @bobrisky222 @jayboogie/INSTAGRAM
Gbajúmọ̀ tí òun náà jẹ́ akọ tó máa ń ṣebí abo, Idris Okuneye tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Bobrisky náà ti dá sí ọ̀rọ̀ Jay Boogie.
Bobrisky ní o jẹ́ ohun tó kọ òun lóminú pé Jay Boogie le lọ sí ilé ìwòsàn tí kìí ṣe ti akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ lẹ́yìn tó ti máa ń lẹ́nu pé òun kò lè ṣe iṣẹ́ láti mú kí ara òun rẹwà ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.
Ó ní Jay Boogie fi òun ṣe yẹ̀yẹ́ nígbà tí òun ṣe iṣẹ́ abẹ àti pé kò sí ọ̀rọ̀ tí kò fẹ́ ẹ̀ sọ sí òun tán nígbà tí òun ṣiṣẹ́ abẹ́ láti le mú kí ìdí òun tóbi.
“Kò sí ọ̀rọ̀ tí ọmọkùnrin yìí kò sọ sí mi tán nígbà tí mo ṣe iṣẹ́ abẹ́ láti mú kí ìdí mi tóbi.
“Ó ní òun ní ara tó rẹwà àti pé òun kò lè ṣiṣẹ́ abẹ láéláé àṣé àbọ̀ ń bọ̀ láìpẹ́ fún òun náà.”

Oríṣun àwòrán, @tosinsilverdam/Instagram
Gbajúmọ̀ akọ to máa ń ṣebi abo, Daniel Anthony Nsikan tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Jay Boogie ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí gbogbo ọmọ Nàìjíríà láti ran òun lọ́wọ́ lẹ́yìn tí iṣẹ́ abẹ tó ṣe láti fọn ìdí rẹ̀ gbòdì.
Ní ọjọ́ kìíní oṣù Kọkànlá ọdún 2023 ni Jay Boogie fi sórí Instagram rẹ̀ pé iṣẹ́ abẹ tí òun ṣe ní ilé ìwòsàn kan kò lọ bó ṣe yẹ àti pé ẹsẹ̀ kan ayé ẹsẹ̀ kan ọ̀run ni òun wà báyìí.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jay Boogie kò sọ irú iṣẹ́ abẹ tó ṣe ní pàtó, ó ní tó ohunkóhun bá ṣẹlẹ̀ sí òun, dókìtà kan nílé ìwòsàn náà ní kí àwọn ènìyàn nawọ́ gán.
Bákan náà ló sọ wí pé ilé ìwòsàn tí òun ti ṣe iṣẹ́ abẹ náà gbọ́dọ̀ jẹ́ nǹkan tí àwọn ènìyàn gbọdọ̀ nàka àléébú sí.
Ó ṣàlàyé iṣẹ́ abẹ tí àwọn ṣe náà kò lọ bó ṣe yẹ àti pé dóktó wà nídìí iṣẹ́ abẹ náà fẹ́ pa òun.
Dókítà mìíràn láti orílẹ̀ èdè Namibia tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Dr Loveth náà fi sórí ayélujára rẹ̀ pé láti ọjọ́ méjì ti Jay Boogie kò ti rí ìtọ̀ tọ̀ lẹ́yìn tó ṣiṣẹ́ abẹ láti fọn ìdí.
Ìpè fún ìrànlọ́wọ́ látọwọ́ Jay Boogie yìí ti ń mú kí àwọn ènìyàn máa fi èrò wọn hàn lórí iṣẹ́ abẹ tó ṣe náà.
Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ló ń bu ẹnu àtẹ́ lu Jay Boogie pé ó ń tú iṣẹ́ Ọlọ́run ní ìwà tó ń wú láti pààrọ̀ ara rẹ̀ láti ọkùnrin dí obìnrin.
Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn mìíràn ń ní kò yẹ kí àwọn ilé ìwòsàn tí kò bá nípa iṣẹ́ abẹ máa dágbá lé e nítorí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ le ṣokùnfà dídá ẹ̀mí àwọn ènìyàn légbodò lọ́nà àìtọ́ tàbí dá egbò àdáàjiná sí wọn lára.
Àwọn ènìyàn Jay Boogie ní tí nǹkan tó ń ṣe é bá fi lè agbára àwọn máa gbé ilé ìwòsàn tó ń ṣe ìtọ́jú rẹ̀ lọ sílé ẹjọ́.
Ṣíṣe iṣẹ́ abẹ láti ṣe àtúnṣe ẹ̀yà ara
Ṣíṣe iṣẹ́ abẹ láti fi ṣe àtúnṣe ẹ̀yà ara kìí ṣe ohun tuntun ní àwùjọ pàápàá nílẹ́ àwọn orílẹ̀ èdè ilẹ̀ òkèrè.
Àmọ́ àṣà yìí ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gbajúmọ̀ nílẹ̀ adúláwọ̀ pàápàá ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Lára àwọn iṣẹ́ abẹ tí wọ́n máa ń ṣe ni Brazilian Butt Lift (BBL), Liposuction, Tummy tuck àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ló máa ń ṣe iṣẹ́ abẹ́ yìí láti mú àyípadà bá ẹ̀yà ara wọn èyí kò bá wọn tẹ́wọn lọ́rùn lórí bí Ọlọ́run ṣe dá wọn.
Èyí tó wọ́pọ̀ lóde òní pàápàá láàárín àwọn gbajúmọ̀ ni ṣíṣe àtúnṣe ìdí, ikùn àti ọyàn èyí tí wọ́n máa ń forí ayélujára.
Ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin tó jẹ́ gbajúmọ̀ lágbo àmúlùúdùn ni wọ́n máa ń ṣe ìdí láti lè mú ìdí wọn tóbi ju bí Ọlọ́run ṣe dáwọn lọ.
Bákan náà ni àwọn mìíràn máa ń kó ọ̀rá kúrò nínú ikùn wọn sí ẹ̀yà ara mìíràn láti kí ikùn wọn lè pẹlẹbẹ si.














