Àwọn agbébọn kọlu àwọn Àgbẹ̀ l'Ondo lórí ọ̀rọ̀ ilẹ̀, lọ̀rọ̀ bá di bóò lọ yàgò

Aworan agbebọn ti ọwọ tẹ

Awọn agbebọn lo ti ṣe akọlu si awọn agbẹ kan ni igbo-ọba Oluwa nijọba ibilẹ Odigbo nipinlẹ Ondo, ti wọn si ba oko wọn jẹ.

Awọn agbebọn ọhun ni a gbọ pe wọn ya wọ igbo-ọba naa ti wọn si ba ọpọlọpọ oko koko jẹ ni aba Temidire.

Adari awọn agbẹ naa, Abayomi Isinleye, to sọrọ lakoko ti wọn n fẹhonu han nilu Akure to jẹ́ olu-ilu ipinlẹ Ondo wi pe awọn agbebọn ọun ni wọn di ihamọra ogun ti wọn si bẹrẹ si nii yin ibọn lakọ-lakọ lati fi le awọn eniyan oun sẹyin.

Abayomi tesiwaju pe, sibẹ, awọn gbiyanju lati gba ibọ meji lọwọ awọn agbebọn naa, ti wọn si tun ri ọkan ninu wọn mu ti wọn si ti faa lọwọ awọn awọn ọlọpaa nilu Ore.

Abayomi fi ẹsun kan ileeṣẹ kan to n jẹ SAO Agro-Allied Services ti ijọba ipinlẹ naa ti fun nilẹ oko naa pe awọn lo wa lẹyin akọlu ọun.

Gẹgẹ bo ṣe wi, “ileeṣẹ yii kọ lati tẹle aṣẹ ile-ẹjọ to ni ki ẹnikẹni ma gbe igbesẹ kankan lori ilẹ naa titi ẹjọ yoo fi pari”.

Abayomi wi pe Onidajọ Aderemi Adegoroye ti ile-ẹjọ giga ipinlẹ naa to wa nilu Ondo ti paa laṣẹ ṣaaju pe ki gbogbo ẹni to nii ṣe ninu ẹjọ ilẹ naa, to fi mọ SAO Agro-Allied, o dẹkun biba oko koko to wa lori ilẹ naa jẹ.

Alaga awọn agbẹ naa wi pe awọn wi fun awakọ katakata to waa ba oko naa jẹ pe ko lẹtọ lati ṣe bee amọ niṣe lo ni ki awọn pe awọn alaṣẹ SAO Agro-Allied.

“Nigba ti oju wa ko gba bi wọn ṣe n ba iṣe ọwọ wa jẹ ni a gbiyanju lati doju kọ wọn taa si gba ibọn meji lọwọn wọn.”

Agbẹjọro awọn agbẹ naa, Tope Temokun, to kesi gomina Oluwarotimi Akeredolu lati fi ewe ọmọ mọ adari ileeṣẹ SAO Agro-Allied leti wi pe iru iwa ti ileeṣẹ naa n hu yi lee domi alaafia ipinlẹ naa ru.

Ohun tí àwọn ọlọ́pàá sọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà rèé

Agbẹnusọ ajọ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Funmilayo Odunlami-Omisanya, ṣe alaye fun BBC News Yoruba pe “lootọ ni awọn kan mu ẹni kan wa si agọ wa nilu Ore pẹlu ibọn meji pe wọn muu nibi to ti n ba oko wọn jẹ.

Lẹyin eyi ni ẹni to gba ọkunrin naa siṣẹ waa sọ fun wa pe ọlọdẹ ileeṣẹ oun ni ọkunrin naa ati pe ko ba dukia ẹnikẹni jẹ.

Ati ọtun atosi la ti fiwe pe ka le gbọ tẹnu wọn ni bi iwadi ṣe n tẹsiwaju”.