Iná sọ nílé ọ̀kan lára àwọn Alfa mẹ́ta tí ọlọ́pàá ká orí èèyàn mọ́ lọ́wọ́ n'Ibadan

Niṣe ni ọrọ di bo o lọ ko yago fun mi fawọn olugbe awọn ara agbegbe Alapata ni ilu Ibadan, olu ilu ipinlẹ Oyo nigba ti ina nla kan ṣẹyọ ni ile afurasi kan ti wọn ba ẹya ara lọwọ wọn.
Iyalẹnu lo jẹ fun awọn eeyan naa latari pe ko si ẹnikẹni to mọ bi ina naa ṣe bẹrẹ nile Taofeeq Olalekan, ẹni to wa ni ahamọ awon agbofinro ipinlẹ Oyo pẹlu awọn afurasi meji miiran fẹsun pe wọn ba ori eeyan lọwọ wọn laipẹ yii.
Yatọ si Taofeeq Olalekan Kabelohun, Rahmon Opeyemi Muibi, ẹnii tawọn eeyan tun mọ si Alubarika ati Tayo Akinrinola lo wa ni ahamọ awọn ọlọpaa naa fẹsun kan naa.
Ileeṣẹ ọlọpaa Oyo ni awọn mẹtẹẹta gbimọ pọ lati pa oṣiṣẹ wọnlẹwọnlẹ kan ti wọn ni ko tẹle awọn lọ si ibi kan ni agbegbe Moniya ni ijọba ibilẹ Akinyele ki wọn to da ẹmi rẹ legbodo.


Iroyin ni awọn afurasi mẹtẹẹta lo jẹ onile ni agbegbe Apete ni ilu Ibadan.
Ọga ọlọpaa, Akande Rufus Adegoke to fidi ọrọ naa mulẹ fawọn akọroyin ni awọn ti gbe ẹjọ naa lọ si ẹka to n mojuto iwa ọdaran to wa ni Iyaganku fun iwadii to peye.
Ni ọjọru ni ọrọ tun gba ọna miiran yọ nigba ti ile ọkan lara awọn afurasi naa ti o wa ni agbegbe Alapata loopopona Apete si Akufo ni ijọba ibilẹ Ido ni ina aimodi jo.
Lara awọn ara agbegbe ọhun ṣalaye fun BBC News Yoruba pe ni nnkan bii aago meje irọlẹ si aago meje aabọ ni awọn kan ṣadede ri ti ina naa bẹrẹ.
Wọn ni iyalẹnu lo jẹ fun awọn nitori awọn ko le sọ pe ohun to ṣokunfa ina naa ni pato niyi nitori ẹẹkan naa ni awọn kan ri ti ina burẹkẹ jade lati aarin ile ọhun.
Ohun ti a ṣakiyesi rẹ ni pe ọpọ awọn ara agbegbe naa ti ilẹkun ile wọn pa, ti wọn si n bẹru lati ba alejo tabi akọroyin sọrọ lori isẹlẹ naa.
Ọlọ́pàá ká orí èèyàn mọ́ Alfa mẹ́ta lọ́wọ́ n‘Ibadan, ariwo sọ

Oríṣun àwòrán, Nigerian Tribune
Ọwọ palaba afurasí Alfa mẹta ti segi pẹlu bi awọn agbofinro ṣe mu wọn lori ẹsun pe wọn ka ori ọkunrin kan mọ wọn lọwọ.
Adugbo Moniya nilu Ibadan ni wọn sọ pe awọn afurasi yii ti ge ori ọkunrin ọhun, to jẹ osisẹ wọnlẹ-wọnlẹ, ti a mọ si Surveyor.
Alukoro fun ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Wale Oyefeso si ti fidi isẹlẹ naa julẹ fun BBC Yoruba.
Amọ o ni ẹkunrẹrẹ iroyin nipa isẹlẹ naa yoo jade sita latọdọ ọlọpaa laipẹ.
Sugbọn ileesẹ iroyin Tribune jabọ pe ọkan ninu wọn afurasi Alfa naa la gbọ pe o jẹ Baba onile ladugbo Alapata ni Moniya.
Ile larinlọọdi yii ni iroyin sọ pe ko jina si ọfisi arakunrin awọnlẹta ti wọn ge ori rẹ yi.
A gbọ pe ọpọ eeyan lo mọ awọnlẹ ta yii ladugbo tori a maa ba ọpọ eeyan ra tabi ta ilẹ wọn.
Ṣe la gbọ pe awọn mẹta yi tan arakunrin naa to ti ba ọkan lara wọn ṣiṣẹ tẹlẹ ti wọn si sọ fun pe awọn fẹ gbe iṣẹ fun.
Inu igbo kan lẹba Moniya ni wọn tan arakunrin naa lọ ti wọn si bẹ ori rẹ lẹyin ti wọn pa.
Awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn sọ pe ni agbegbe Sango ni ijọba ibilẹ ariwa Ibadan ni wọn ti mu awọn afurasi yi.
Eleyi lo mu ki ọpọ awọn eeyan maa ṣe eemọ lori iṣẹlẹ yi ladugbo Alapata.
Pupọ lọrọ naa jẹ iyalẹnu fun ti wọn si sọ pe ọkan lara awọn afurasi yijẹ alufaa onilawani ara ọtọ ti ọpọ eeyan si mọ lẹlẹsin ladugbo Alapata.
Ọga agọ ọlọpaa to wa ni Alapata CSP Akande Rufus Adegoke,ni ileeṣẹ iroyin Tribune lo fidi ọrọ yi mulẹ sọ pe awọn afurasi wọnyi jẹ onile ara wọn ladugbo wọn ni Alapata ṣugbọn Moniya ni wọn ti hu iwa buruku yi.
O ṣalaye pe awọn ti gbe ẹjọ yi lọ si ẹka iwadii iwa ọdaran ọlọpaa to wa ni Iyaganku fun itẹsiwaju iwadii lori rẹ.













