Ilé ẹjọ́ gíga pa ẹjọ́ tí Tani-Olohun pé láti ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀rọ̀ béèlì rẹ́

Ile ẹjọ giga to kalẹ si ilu Ilọrin, ipinlẹ Kwara ti da ẹbẹ fun beeli Abdulazeez Adegbọla ti ọpọ mo si Tani Ọlọhun nu.
Eyi waye lọjọbọ, ọjọ keji osu kọkanla ọdun 2023 latari beeli ti ile ẹjọ Majisireeti fun eekan onisẹse naa ni ọgbonjọ osu kẹwaa.
Saaju, ile ẹjọ Majisireeti nibi ti Tani-Ọlọhun to n jẹjọ lori ẹsun ibanilorukọjẹ ti ẹgbẹ Ogo Ilorin fi kan an ti kọkọ da ẹbẹ fun beeli rẹ nu lori awọn kudiẹ kudiẹ to wa ninu iwe beeli ọhun.
Eyi lo faa ti agbẹjọro to n duro fun un, Ademola Banks fi tọ ile ẹjọ giga lọ ni ọjọ kẹtadinlọgbon osu Kẹwaa lati gba beeli onibaraa rẹ, sugbon ilé ẹjọ naa sun igbẹjọ si ọjọbọ ọjọ Keji oṣù Kọkanla.

Ki lo sẹlẹ nile ẹjọ loni? Alayee ree
Nibi igbẹjọ toni, Ademola Banks fi to ile ẹjọ leti wi pe oun fẹ gbe iwe beeli naa kuro niwaju adajọ nitori pe ko ṣe koko mo.
O ṣ alaye wi pe, ile ẹjọ Majisireeti to kọ lati fun onibara oun ni beeli ni igbiyanju akọkọ ti pada fun un ni ọgbonjọ osu yii.
Agbẹjọro alatako, Oseni Sanni sọ wi pe ohun ko tako ẹbẹ naa nitori pe o ba oun lara mu.
Adajọ ile ẹjọ naa, Justice Funshọ Lawal gba si awon agbẹjọro mejeeji lẹnu. O si pa iwe beeli naa rẹ.
Ninu ifọrọwerọ pẹlu Ademola Banks leyin igbẹjọ, o sọ ọ di mimọ pe ominira onibara oun ni o ṣe koko si oun.
O ni oun n gbiyanju lati gba beeli rẹ bakan naa ni ile ẹjọ kẹta ti o tun ti n jejọ lati ri pe o di ominira patapata.
Ilé ẹjọ́ gba béèlì Tani-Ọlọhun lẹ́yìn ọjọ́ márùndínlọ́gọ́rin làhámọ́ ṣùgbọ́n...

Ile ẹjọ Majisireeti ti fun Abdulazeez Adegbọla ti inagi rẹ n jẹ Tani-Ọlọhun ni beeli to si tun gba oniduro fun un.
Tani-Ọlọhun n jẹjọ lori ẹsun ibanilorukọjẹ ti ẹgbẹ kan ti wọn pe ni Association of Proud Sons and Daughters of Ilorin (Ogo Ilorin) fi kan an.
Ti ẹ o ba gbagbe, ni ọjọ kẹtadinlogun osu yii ni ọkan lara awon agbẹjọro to n duro fun onisẹse naa, Muftau Olobi gbe iwe beeli rẹ wa si ile ẹjọ.
Amọ,Ademola Banks ti ohun naa n duro fun un takoo pẹlu iwe atako si ofin wi pe ile ẹjọ ko ni agbara lati gbọ ẹjọ naa.
Tori atako to waye yi, Adajọ Muhammad Ibrahim ko ribi gbe igbesẹ lori iwe beeli naa, to si ni ki awon agbẹjọro mejeeji yi lọ gbọ ara wọn ye ko to di igbẹjọ to tẹlee.
Nibi igbẹjọ to waye lonii ọjọ Aje tii ṣe ọgbọnjọ oṣu Kẹwaa, agbẹjọro Olobi kọkọ gbe iwe atako ọhun kuro niwaju adajọ, o si rọ ile ẹjọ lati gba oniduro fun onibara rẹ nitori pe o ti rawọ ẹbẹ si awọn ti ọrọ kan.
Agbẹjọro to n soju ogo Ilorin, Oseni Sanni ko tako ẹbẹ yii sugbon o gba ile ẹjọ ni iyanju lati gbe awon ilana ti yoo mu olujẹjọ naa maa yọju si ile ẹjọ ni gbogbo ọjọ igbẹjọ kalẹ.
Magistrate Muhammad Ibrahim gba si awon mejeeji lẹnu sugbon o kọkọ ba awọn agbẹjọro olupẹjọ mejeeji wi naa.
Adajọ Muhammad ni ominira onibara wọn lo yẹ ko jẹ wọn logun ju atako ara wọn ti ko se anfani kan fun ẹni ti wọn n ṣoju rẹ.
Ki lohun to rọ mọ beeli ti adajọ gba fun Tani Ọlohun
Awọn iṣẹṣẹ kankan ko yọju sile ẹjọ nibi ti adajọ ti gba beeli Tani Olohun.
Ko si ṣẹyin wi pe wọn ni ko tẹ awọn lọrun bo ṣe tọrọ aforijin lọwọ awọn to fẹsun kan pe o bawọn lorukọ jẹ.
Lẹhinwa ni adajọ fun olujẹjọ naa ni beeli ni odiwon igba ẹgbẹrun Naira, N200, 000 ati oniduro meji ti ọkan ninu wọn gbọdọ jẹ ibatan rẹ.
Gẹgẹbi Magistrate Muhammad Ibrahim ti laa kalẹ, awon oniduro yii gbọdọ maa gbe ni arọwọto ile ẹjọ.
Bakan naa Tani Olohun naa si gbọdọ maa farahan ile ẹjọ ni ẹẹkan laarin ọjọ mẹrinla.
Adajọ pada sun igbẹjọ si ọjọ kokanlelogun osu to n bọ tii.
Ṣe Tani Olohun ti wa lanfaani lati lọ sile bayii?
Ibi ti ṣugbọn wa ree nipa gbigba beeli ati oniduro Tani Olohun.
Ko yi si anfaani fun lati pada sile titi ti awọn agbẹjọro rẹ yoo fi pari gbogbo eto beeli ọhun.
Bi wọn ba tiẹ pari eto gbogbo lori beeli rẹ, ko ni le kuro lahamọ tori pe awọn ẹjọ miran ṣi wa ti adajọ ko tii gbọ lori ẹsun ibanilorukọjẹ ti wọn fi kan an.
Yoo ṣi wa ni ahamọ lọdọ awọn oṣiṣẹ ọgba ẹlẹwọn titi ti yoo fi pari ẹjọ ẹlẹẹkẹẹta ti Sheikh Labeeb fi kan lori ẹsun ibanilorukọjẹ niwaju majistereeti mii ni ilu Ilorin.
Boti lẹ jẹ wi pe Sheikh Labeeb ni oun ti fori ji Tani Olorun wọn yi ni lati pari gbogbo eto labẹ idari ile ẹjọ
Lasiko ti wọn kọkọ bẹrẹ igbẹjọ lori ẹsun yi, Tani Olohun ko ni agbẹjọro ti yoo ṣoju fun.
Bi o ba ti wa yanju ọrọ agbẹjọro, yoo nilati de iwaju adajọ ki wọn to le fẹnu ko lori gbigba beeli rẹ tabi ki wọn si tu silẹ pe ko lẹjọ ro ti ẹni to ba fẹsun kan an naa ba gba pe oun ko ṣẹjọ mọ.
Ki a ma gbagbe pe o tun yi ni ẹjọ miran ti Ọjọgbọn Abubakar Aliagan naa pe lori ẹsun to nii ṣe pẹlu jijo Al Quran nina.
Bi ọrọ ba yanju tan lori awọn ẹjọ wọnyi la to le sọ pato boya yoo kuro lahamọ ti yoo si pada sile rẹ.












