Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tako ìdájọ́ tó rọ Soun Ogbomosho tuntun lóyè

Oríṣun àwòrán, Free World TV
Ijọba ipinlẹ Oyo ti pe ẹjọ kotẹmilọrun tako idajọ ile ẹjọ to rọ Soun ilu Ogbomosho, Oba Ghandi Afolabi Olaoye, loye.
Yatọ si ẹjọ kọtẹmilọrun yii, ijọba tun bẹbẹ pe ki ile ẹjọ maṣe gba ki wọn yọ ori ade ọhun loye titi ti yoo fi gbọ ẹjọ ti awọn pe.
Olupẹjọ naa tun n bere pe ki awọn to pe ẹjọ akọkọ, eyii ti ile ẹjọ da lare maṣe ṣe ohunkohun lati yọ Ghandi loye lasiko yii.
Ti ẹ ko ba gbabe, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun 2023 yii ni Adajọ K. A. Adedokun da ẹjọ naa laarin ọmọba Muhammed Olaoye ati ijọba ipinlẹ Oyo atawọn mọkanla mii, ninu eyii to ti ni kudiẹkudiẹ wa ninu iyansipo ọba Ghandi Olaoye, nitori naa ko fi ipo naa silẹ.
Lẹyin idajọ ọhun ni Akin Onigbinde, SAN, pe ẹjọ kotẹmilọrun lorukọ gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde atawọn mii ti ọrọ naa kan nipinlẹ lori idajọ to gba ade Ọba lori Soun tuntun.
Ipẹjọ yii ni agbẹjọro ijọba ti fa koko mẹfa yọ ninu eyii to ti tako idajọ ile ẹjọ akọkọ.
O ni awọn ẹri to wa nilẹ tako idajọ to waye pe Ghandi ko yẹ loye Soun ilu Ogomosho.
Lara awọn ti ijọba pe lẹjọ kotẹmilọrun yii ni agbẹjọro Oladapo Atanda, ijọba ibilẹ ariwa Ogbomosho ati igbimọ afọbajẹ Ariwa Ogbomosho.
Awọn to ku ni agbẹjọro S.A. Mohammed, ileeṣẹ Mohammed & Mohammed & Co., Mobolaji Chambers, Kola Fatoye, Oloye Samuel Otolorin, Oloye Salawu Ajadi, Oloye Tijani Abioye, Oloye David Adeniran Ojo, atawọn mii.














