NDLEA mú olókoòwò méjì òni fayawọ́ egbògi olóró,wo nkán tí wọ́n yà n'ìgbẹ́

Aworan afurasi oniṣowo onifayawo egboogi oloro

Oríṣun àwòrán, NDLEA

Awọn osisẹ ajọ to n gbogun ti lilo oogun oloro ni Naijiria NDLEA ti kede bawọn se ri oogun oloro orisi tawọn olubi kan gbiyanju lati gbe jade lati Naijiria lọ si ilẹ okere.

Ninu awọn ti ọwọ ajọ yi tẹ la ti ri awọn oniṣowo meji ti wọn n lọ si Hong Kong ati orileedee France pẹlu oofgun oloro ti wọn gbe mi sikun.

Ẹni akọkọ ThankGod Chimamkpa Emenike to jẹ ẹni ọdun mejidinlogoji ti wọn si mu lọjọ Ẹti ogunjọ Oṣu Kẹwaa nigba to fẹ wọ baalu lọ si ilẹ Faranse.

Ọjọ keji ọjọ ti wọn mu ThankGod ni okete boru fun ẹni ọdun mọkanlelogoji, Agbo Chidike Prince to fẹ wọ baalu Ethiopian Airline lọ si Hong Kong gba Addis Ababa.

Lẹyin ti wọn fi wọn si ahamọ, alukoro ajọ naa Femi Babafemi sọ ninu atẹjade pe ẹni akọkọ ya oogun oloro heroin mejilelaadọrin ti iwọn rẹ si to kilo 1.171.

Chidike to jẹ ẹni keji gẹgẹ bo ṣe wi ya igbẹ oogun oloro cocaine mọkandinlaadọta ti iwọn rẹ si to giraamu 998.53.

Ninu ọrọ rẹ, Babafemi sọ pe Chidike jẹwọ pe oniṣowo to n ta ẹya ara ọkọ,spare parts, loun ni ọja Alaba International to wa ni Eko.

''O fikun ọrọ rẹ pe miliọnu mẹta ati abọ Naira ni wọn yoo san fun oun toun yoo si fi owo yi ra ọja pada wa si Naijiria lati Hong Kong''

Ọwọ tẹ arakunrin mii to fẹ gbe skunk lọ si Oman

Aworan awọn oogun oloro ti NDLEA ri gba

Oríṣun àwòrán, NDLEA

Femi Babafemi tẹsiwaju ninu atẹjade rẹ pe lọjọ Kẹẹdọgbọn oṣu Kẹwaa awọn tun mu arakunrin mii to fẹ gbe oogun oloro skunk lọ si Oman.

Babafemi ṣalaye pe Agbo Celestine lorukọ afurasi yi to si sọ pe oun sipo pada lati Naijiria lọ si Oman loṣu Kaarun ọdun yi toun si n ṣiṣẹ ni ile itura kan lati igba naa koun to pada wa ya sidi fayawọ oogun oloro.

Idi mejidinlọgọta skunk ti iwọn rẹ jẹ 29.10kg ni wọn ka mọ lọwọ.

Ẹwẹ, Ajọ naa s pe awọn tun ri skunk ti apapọ iwọn rẹ to 2,197 kg gba lọwọ awọn eeyan ni ipinlẹ Ondo laarin ọjọ mẹrin.

Awọn ibomiran to ni ọwọ awọn tun ti oogun oloro ni :

  • Ipinlẹ Oyo,giraamu 160 Igbo, ati giraamu 332kg igbo yi bakanaa ni adugbo Nalend
  • Ipinlẹ Eko,ajọ naa ribi gba oogun oloro ''Loud'' lọjọ Kejidinlọgbọn oṣu Kẹwaa ti awọn kan gbe sinu ọkọ ladugbo Ajah ti iwọn rẹ si to 209kg.
  • Gombe, awọn oṣiṣẹ NDLEA ribi gba idi igbo 401 ti iwọn rẹ to kilo 392 ati idi Tramadol capsuu ẹgbẹrrun mọkanlelogun 21,000 ladugbo Tumfure ni Gombe.
  • Ipinlẹ Edo, NDLEA wọ igbo Utese ni ijọba ibilẹ Ovia North ti wọn sdsi ribi gba iwọn kilo 2,931.3 igbo ninu aaye tawọn kan ko pamọ si.