Ọwọ́ NDLEA tẹ bàbá ẹni ọdun 67 tó gbé ọgọ́rùn ún òkèlè 'cocaine' mì

NDLEA

Oríṣun àwòrán, NDLEA

Ọwọ ajọ to n gbogun ti egboogi oloro, NDLEA, ti tẹ baba ẹni ọdun mẹtadinlaadọrin kan, Chukwuemeka Clement, lori ẹsun pe o gbe oogun oloro ‘cocaine.’

Papakọ ofurufu Nnamdi Azikwe to wa niluu Abuja ni ọwọ ti tẹ ọkunrin ọhun pẹlu okele ‘cocaine’ọgọrun to ti gbe mi ṣaaju.

Afurasi naa ni oun gbe oogun oloro ọhun lọna ati kowojọ lati fẹ iyawo tuntun.

Ọkunrin ọhun sọ pe apapọ ọgbọn ni oun lo lorilẹ-ede Brazil, Ethiopia ati Thailand lai ri nnkankan mu pada wa si Naijiria.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ NDLEA, Femi Babafemi fi lede, o ni iye iwọn gbogbo oogun oloro ọgọrun ti ọkunrin naa gbe mi jẹ 2.195kg.

Afurasi naa ni oun ti kọkọ fẹ iyawo tẹlẹ amọ obirin naa jade laye lai bi ọmọ kankan fun oun.

O ni eredi ree ti oun ṣe gbe oogun oloro lati fẹ iyawo miran, ki oun si bẹrẹ igbeaye ọtun.

Ọwọ NDLEA tẹ awọn afurai mii

Yatọ si baba yii, NDLEA tun ni ọwọ awọn tẹ obinrin ẹni ọdun marundinlaadọta kan, Bilikisu Mohammed Bello, lasiko to n rinrinajo lọ si Saudi Arabia.

Obirin ọhun jẹwọ fun NDLEA pe ilu Kano ni oogun oloro ti oun gbiyanju lati gbe rinrinajo wa ki oun to gbe oogun naa mi.

Nigba to mu NDLEA de ile ti oogun naa wa ni Kano, wọn ba awọn iyoku oogun oloro naa ninu ile ọhun.

Ẹwẹ, NDLEA, pẹlu ajọṣẹpọ ileeṣẹ ọmọ ogun, Amotekun atawọn ẹṣọ alaabo miran ti dana sun oko kan ti wọn ti n gbin igbo niluu Ogunmakin, to wa ni ijọba ibilẹ Owode, nipinlẹ Ogun.

NDLEA ni iye iwọn igbo ti wọn bajẹ ninu oko naa le ni tọọnu mẹwaa.