NURTW yan MC Oluomo ní alága fìdíhẹ fún gbogbo ilẹ̀ Yoruba

Oríṣun àwòrán, @kingmcoluomo
Awọn aṣoju ẹgbẹ awakọ, NURTW, ti ẹkun keji ni ilẹ Yoruba ti yan Musiliu Akinsanya ‘MC Oluomo,’ gẹgẹ bii adele alaga fun ẹgbẹ naa nilẹ Yoruba.
Awọn aṣoju ọhun tun rọ awọn gomina ipinlẹ bii Oyo, Ondo ati Osun lati gba ẹgbẹ NURTW laaye lati pada ṣi awọn gareji rẹ ni awọn ipinlẹ wọn.
Nigba to n sọrọ nibi ipade ẹgbẹ naa to waye niluu Osogbo, akapo agba gbogbogbo fun ẹgbẹ naa nigba kan ri, Nasiru Komolafe sọ pe Oluomo ni yoo maa dele gẹgẹ bi alaga titi wọn yoo fi dibo ipọ alaga.
Komolafe ninu ọrọ rẹ rọ awọn Gomina ipinlẹ ti wọn ti wọgile NURTW pe ki wọn jẹ ki ẹgbẹ naa pada si ni ṣisẹ pada nitori ilẹ Yoruba ni Aarẹ ẹgbẹ ọhun n bọ bayii.
O fi kun ọrọ rẹ pe ẹgbẹ naa ko le ṣe ipade gbogbogbo nitori pe ipinlẹ meji lo n ṣiṣẹ ninu ipinlẹ mẹfa to wa nilẹ Yoruba.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, ofin ko gba awọn laaye lati ṣe ipade gbogbogbo to yẹ ki wọn maa ṣe.

Oríṣun àwòrán, @kingmcoluomo
Komolafe ni “Nitori naa a fẹnuko lati sun ipade gbogbogbo gusuu iwọ-orun si ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 2022.”
“Eredi igbesẹ naa ko ṣẹyin ipade gbogbogbo ti yoo waye ni ọjọ kẹẹdogun, oṣu kẹwaa, ọdun 2023.
“Nitori naa mo fi asiko yii bẹ gbogbo gomina mẹrin to ku lati jẹ ki NURTW bẹrẹ isẹ pada nipinlẹ wọn.”
“O ṣe pataki fun lati ṣe bẹẹ ki ilẹ Yoruba ma ba padanu ipo Aarẹ ẹgbẹ naa.”













