Kílódé tí Ìjọba àpapọ̀ fí wọ́gilé N-Power fún ìgbà díẹ̀?

Aworan Asia N-Power

Oríṣun àwòrán, N-Power

O to milọnu kan eeyan to ti padanu isẹ wọn kete ti ìjọba apapọ kede pe awọn ti wọgile eto ìjọba N-Power to n pese fun araalu.

Eto ìjọba N-Power ni ijọba da silẹ lasiko eto isejọba Aarẹ ana, Mohammadu Buhari lati gbe ogun ti airisẹ awọn ọdọ, ti wọn si n san ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira fun awọn ọdọ naa ni owo oṣu wọn.

Ọdun meje sẹyin ni ijọba apapọ da eto silẹ lati gbe ogun ti bi awọn ọdọ ko ṣe ri isẹ lorilẹede Naijiria.

Minisita fun igbayegbaju araalu, Betta Edu lo kede ọrọ naa lasiko to n kopa ninu ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu ileeṣẹ tẹlẹfisan TVC lana salaye pe ijọba gbe igbesẹ yii lati ṣe iwadi lori bi awọn olori eto ṣe na owo ijọba.

Bakan naa ni Minisita bu ẹnu atẹlu bi awọn ọdọ kan ṣe kuna lati ṣe ojuṣe won lori eto ti ijọba pese ti pupọ si gba owo ijọba nikan sapo.

“A ni lati pada si N-Power lati ṣe atunṣe ati lati mọ isoro to n da lamu. Bayii, a wogile fun igba diẹ lati le ṣe iwadi to jina lori bi wọn ṣe n na owo ti ijọba pese fun eto N-Power.

“A fẹ mọ iye awọn eeyan ti wọn n jẹ anfani yii lọwọlọwọ bayii, iye awọn ti a jẹ lowo ati iye ti ajẹ wọn, A fẹ ṣe atunṣe nla si eto N-Power, a si fẹ ko kari;e ati oko.

“Ọpọ igba ni a ma kesi ile ẹkọ ti a fi awọn ọdọ yii, sugbọn wọn ko si nibẹ, bẹẹni wọn sọ pe a jẹ awọn ni owo oṣu mẹjọ si mẹsan an.

“O to ida ọgọrin ọdọ ti wọn ṣe isẹ kankan bayii sugbọn wọn fẹ gba owo oṣu lọwọ ijọba”

Bawo ni N-Power ṣe waye?

Ọjọ kẹjọ oṣu kẹfa ọdun 2016 ni ijọba apapọ gbe eto N-Power kalẹ lati tan isoro airisẹ ati lati pese iranlọwọ fun awọn ọdọ lorilẹede Naijiria.

Awọn ọdọ lati ọdun Mejidinogun si ọdun marundinlogoji lo ni anfani si eto yii.

Ọdun meji ni ijọba yoo fi san owo fun awọn ọdọ ti wọn ba gba sisẹ.

Ijọba pin eto naa si isọri mẹfa; N-Teach, N-Health, N-Agro, N-Build, N-Creative ati N-Tech.