"Owó gọbọi là ń san lórí àwọn ọmọ wa àmọ́ ìgbéayé ẹlẹ́wọ̀n ni wọ́n ń gbé nílé ẹ̀kọ́ wọn"

Oríṣun àwòrán, bbc
Àwọn òbí àti alagbatọ awọn ọmọ ile ẹkọ ìjọba àpapò, Federal Science and Technical College, Usi Ekiti, ipinle Ekiti ti ṣe ifẹhonuhan alafia nínú ọgbà ilé ẹ̀kọ́ náà lórí ìtọ́jú àti ètò ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ wọn.
Àwọn obí àti alagbató náà fariga lórí ọ̀nà tí olùdarí ilé ẹ̀kọ́ ọhun, Balogun Adisa Olateju fi ń se akoso àti ìtọ́jú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà tí wọn sì ni awọn fẹ ki ijọba gbe kuro ni ile eko naa ni kankan.
Nígbàtí alága ẹgbẹ́ àwọn obi ilé ẹ̀kọ́ naa Bangbose Taiwo sọrọ, o fi ẹsun kan oludari ilé ẹkọ ọhun pe ko ṣe àmójútó rẹ daradara gẹ́gẹ́ bí àwọn tí wọn ṣáájú rẹ ṣe ń ṣe.
Àwọn olufẹhonuhan náà lọ káàkiri inu ọgbà ilé ẹ̀kọ́ ọhun pẹlu orisirisi patako lọwọ wọn.
Lara wọn akọle ti wọn kọ si awọn patako ni “A n fẹ oludari míràn,” “Adisa Balogun ma pa FSTC Usi run,” “Àwọn ọmọ wa kò rí itọju dáadáa ní FSTC Usi,” Eto ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ wa nílò ayipada lọwọ Balogun, ìjọba àpapò ẹgba wá.”
Àwọn òbí náà sọrọ lori bí agbegbe ilé ìdáná àti ibùsùn àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà kò ṣe bá ìgbà mú, tí wọn ní kó yàtọ̀ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n.

Oríṣun àwòrán, bbc
Wọn tilẹ sọ pé ọgbà ẹ̀wọ̀n gan dára ju ibi tí wọn kó awọn ọmọ àwọn sí, tí wọn sì ní oúnjẹ tí wọn n fún wọn gan kò ṣara loore fún idagbasoke tó péye.

Oríṣun àwòrán, bbc
Adewumi Temidayo àti Olatuji Bamisile tí wọn jẹ obi ní láti nnkan bíi ọsẹ mẹ́ta tí àwọn akẹkọọ ti pada sile ẹkọ ni wọn kò ti gbà ìwé tí àwọn òbí san owó rẹ.
Wọn tún ní gbogbo inú yàrá ibùsùn ni kò dára mọ rárá pẹlu owo yanturu tí àwọn òbí ń ṣàn.

Oríṣun àwòrán, bbc
Lára àwọn akẹkọọ tó bá akọroyin BBC Yoruba sọrọ tí wọn kò fẹ dárúkọ ara wọn ní kó sì omi, ilé igbónsẹ̀ tó dára ati iná ijọba ninu ọgbà ile ẹkọ náà.
Wọn sọ siwaju si pe oúnjẹ tí àwọn oludari n fún àwọn ko dara rárá, wọn tun bù ẹnu àte lu bí gbogbo òrùlé ilé ẹ̀kọ́ ṣe maa n jo ni ọpọlọpọ ìgbà ti ojo bá rọ.
Lẹyin naa ni wọn ràwọ ẹ̀bẹ̀ si ìjọba àpapọ̀ láti tètè wá bá àwọn mójútó gbogbo ìwà ibajẹ ati iwa aibikita ti wọn ni olùdarí ilé ẹkọ náà n wu.
Nígbàtí akọrin BBC Yoruba kan sì olùdarí ilé ẹ̀kọ́ ọhun lórí ẹrọ ibanisọrọ rẹ, ni oun kò tii gbó nkankan lórí iwọde ọhun.












