Ìlú Ifon àti Ilobu tọwọ́ bọ ìwé àdéhùn àlàáfíà pé kò ní sí wàhálà mọ́

Oríṣun àwòrán, Ijọba ipinlẹ Osun
Awọn olori Ilu Ifon ati Ilu Ilobu to wa ni ijọba ibilẹ Orolu ati Irẹpondun nipinlẹ Osun ti tọwọbọ iwe adehun alaafia pẹlu ijọba ipinlẹ Osun lati gba alaafia laye ati lati doju id ogún kọlẹ ni wàrà sesa.
Bakan naa ni ijọba ipinlẹ Osun yoo boju wo igbesẹ ofin kole ko gbele ti ijọba kede niluu mejeeji.
Gẹgẹ bí ẹ ti mọ pe bí ọjọ melo kan seyin ni ilu Ifon ati ilu Ilobu ni ìjọba ibílẹ Orolu ati Irepodun tún bẹrẹ awọ ija ilẹ eyi ti o mu ki ọpọlọpọ padanu ẹmí ati dukìa wọn.

Oríṣun àwòrán, Ijọba ipinlẹ Osun
Eyi lo si jẹ ki Gomina Ademola Adeleke paṣẹ konile ko gbele fun wákàtí mẹrinlelogun ojojumọ niluu mejeeji.
Ní alẹ Ọjọ Jimoh ọjọ kẹfa Oṣu Kẹwa ni Kọmisanna fun iroyin nipinlẹ Osun, Kolapo Alimi gbẹnusọ fun Gomina Ademola Adeleke fún awọn òfin yí.
Fífi ọwọ si iwe Àlaafia waye ninu ipade to waye laarin ìjọba Ìpínlẹ Osun ati Ìlú Mejeji ní alẹ ọjọ Jimoh.
Lara awọn to wa ni kalẹ lasiko naa ni Igbakeji Gomina Ipinle Osun Omooba Kola Adewusi, Akowe ̀ipinlẹ Osun Hon. Teslim Igbalaye ati awọn alakoso ijọba mii.
Àwọn tí wọ́n fara han nínú fífi ọwọ siwe àlàáfíà ni Otun Olobu, Oloye Jimoh Waliyu, Esa ti ilu Ifon, Oloye Babatunde Oyetunji ati asoju ìlú Olokanl, Bashiru Azeez pẹlu awọn Meji lati ilu mejeji ni wọ́n fọwọ́ siwe àlàáfíà fun ìlú wọn.
Gomina wa dupẹ lọwọ ìlú mejeeji bí wọn se fọwọ́ siwe alaafia ti wọn si setan lati dagbere fún Ogun ati lati gba alaafia laye.
Pẹlu bi wọn ṣe tọwọbọ iwe adehun naa, pfin konile gbele yoo si tẹsiwaju titi ijọba yoo fi ri alaafia .
Ijọba wa kilọ pe bí ẹniḳẹni tabi ẹgb́ẹ kan ba tun sọ eyi to yat̀ọ si ìwe adehun alaafia naa, iru eeyan tabi ẹgbẹ naa yoo fimu ko ọta ofin ijọba

Oríṣun àwòrán, Ijọba ipinlẹ Osun















