Àwọn ẹbí tí wọ́n ṣe ẹlẹ́yàmẹ̀yà sí nínú ìdíje "gymnastics" ní ẹ̀bẹ̀ wọn kò wúlò
Awọn ọmọ ilẹ Afrika ti awọn alasẹ gymnastics lorilẹede Ireland kọ lati fun ni ami ẹyẹ lasiko ayẹyẹ ami ẹyẹ gymnastics ti wọn ko tẹwọgba ẹbẹ awọn alasẹ naa rara.
Fọnran kan to jade si ori ayelujara lo safihan bi ọkan lara awọn alasẹ to n pin ami ẹyẹ ṣe kọ lati fun ọdọmọbinrin naa ni ami ẹyẹ naa ilu Dubia lọdun to kọja, to si jẹ pe oun nikan ni alawọ dudu laarin awọn akẹkọọ naa.
Iya ọmọ naa ni ibanujẹ ọkan fun oun, to si bu ẹnu atẹlu iwa na.
Awọn alasẹ Gymnastics lorilẹede Ireland ti wa tọrọ aforijin lọwọ awọn mọlẹbi.

Ninu atẹjade ti wọn fi lede, ni awọn tọrọ aforijin, ti oun yoo si se oun to tọ lati ma jẹ ki irufẹ isẹlẹ naa tun waye mọ.
Sugbọn Iya ọdọmọbinrin naa ni ku diẹ kato pe awọn alasẹ sẹsẹ n tọrọ aforijin lẹyin oṣu mejidinlogun ti isẹlẹ naa ti waye nitori pe gbogbo agbaye pariwo mọ wọn.
“Ẹbẹ ko ni ipa kankan, wọn ko ponwa le rara.
”O ti to oṣu mejidinlogun to ti da bi pe a n fipa mu wọn lati tọrọ aforijin.
“Mo sunkun fun igba pipẹ, ti ogunlọgọ eeyan si ni lati ma ba mi sunkun ki n to le gba ohun to waye mọra."













