George Weah ń du ipò Ààrẹ Liberia lẹ́ẹ̀kejì àmọ́ inú ọ̀pọ̀ aráàlú ni kò dùn sí ìjọba rẹ̀

Oríṣun àwòrán, EPA
- Author, Azeezat Olaoluwa & Yūsuf Akínpẹ̀lú
- Role, BBC News, Monrovia
Agbabọọlu orilẹ-ede Liberia tẹlẹ, George Weah n du ipo Aarẹ ilẹ naa lẹẹkeji bo tilẹ jẹ pe ko ṣe awọn ohun kan ti awọn araalu n fẹ.
Lara awọn nnkan ti awọn eeyan naa n bere fun ti Weah ko ṣe ni lati ṣagbekalẹ ile ẹjọ ti yoo gbọ ẹjọ nipa eto ọrọ aje ati eyii ti yoo ṣedajọ awọn to lọwọ ninu ogun abẹle to waye nilẹ naa lọpọ ọdun sẹyin.
Ẹni ọdun mẹtadinlọgọta naa gori itẹ pẹlu ileri lati pese iṣẹ, lati tu aye awọn eeyan ilu ṣe ati lati gbe awọn ile ẹjọ naa kalẹ.
Amọ lẹyin to gbajọba lọdun 2018, o ni ko yẹ ki orilẹ-ede naa tun pada boju wo awọn nnkan to ti waye sẹyin nitori ko le mu itẹsiwaju wa.
Amọ ọrọ yii ko dun mọ awọn kan bii Frederick Tulay, ẹni ọdun mẹrinlelogun ninu.

Oríṣun àwòrán, Frederick Tulay
O sọ fun BBC pe oun ko ni dibo fun Weah lọtẹ yii nitori ọrọ naa.
Frederick Tulay dibo fun Weah ninu ibo to kọja amọ o ni oun ko ni ṣe aṣiṣẹ kan naa mọ ninu ibo ti yoo waye bayii.
Ọdun meji sẹyin ni Tulay padanu iṣe rẹ lẹyin ti ọga rẹ ko lagbara lati maa san owo oṣu rẹ mọ.
Iṣẹ ọkọ akero aarin igboro ni Tulay n ṣe bayii amọ isẹ naa ko lọ dede.
Ọrọ ọdọknrin naa n ṣepajuwe ohun ti ọpọ awọn eeyan ilẹ naa la kọja lẹyin ogun ọdun ti ogun abẹle meji ọtọtọ ba orilẹ-ede ọhun finra, ninu eyi ti 250,000 eeyan ti jade laye.
Ni ti Peterson Sonyah, to jẹ ẹni ọdun mọkandinlaadọta, o ni bi ijọba ilẹ naa ṣe kọ lati ṣe idajọ ododo lori awọn ohun to ti ṣẹlẹ ṣeyin ni itẹsiwaju ko ṣe de ba wọn.

Ọmọ ọdun mẹrindinlogunni Sonya wa nigba ti awọn ologun ṣeku pa baba rẹ ninu ṣọọṣi kan ti wọn sa pamọ pẹlu eeyan 600 mii.
O sọ fun BBC pe “Idajọ ododo gbọdọ waye ni kankan.”
“Awọn eeyan kan tilẹ ti n sọ fun mi pe ti ko ba si idajọ ododo, a ni lati lọ ra ibọn funra wa.”
Eeyan mọnkandinlogun mii lo n ba Weah du ipo Aarẹ ọhun ti idibo rẹ yoo waye lọjọ Iṣẹgun to n bọ.

Oríṣun àwòrán, AFP
Lara awọn ni Joseph Boakai, Alexander Cummings ati Tiawan Gongloe.
Ọpọ awọn olugbe ilẹ naa lo gbagbọ pe ijọba wọn gbọdọ ṣagbekalẹ awọn ile ẹjọ ti wọn n bere fun ilọsiwaju orilẹ-ede wọn.
Ẹwẹ, ẹnikan to jẹ alatilẹyin Weah, Wleh Potee sọ pe kii ṣe orilẹ-ede Liberia nikan ni iṣẹ ati iya n ba finra.
Bo tilẹ jẹ pe ọja rẹ ko lọ dede, o ni inu awọn oniṣowo miran dun si Aarẹ Weah fun akitiyan rẹ.

Oríṣun àwòrán, Moses Garzeawu
Awọn onimọ nipa eto oṣelu ilẹ adulawọ ti sọ pe awọn eeyan Liberia lanfani lati sọrọ bo ṣe wu wọn labẹ iṣẹjọba Weah ju ti atijọ lọ.
Ẹwẹ, Sonyah ti sọ pe ireti oun n pe ẹnkẹni ti araalu ba fi ibo wọn gbe wọle yoo tẹti si awọn lati maa ṣe ohun to yẹ fun wọn.
O ni “Alaafia lai si idajọ ododo da bii tii lai si ṣuga.”












