Liberia Election: Dídènà ogun abẹ́lé jẹ́ ohun pàtàkì fún mí - Alexander Cummings

Àkọlé fídíò, Dídènà ogun abẹ́lé jẹ́ ohun pàtàkì fún mí - Alexander Cummings

Oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Alternative National Congress, Alexander Cummings ti jẹ ko di mimọ pe didena ogun abẹle lorilẹede Liberia jẹ ohun pataki fun oun lati ṣe ti ilu ba dibo yan oun gẹgẹ bi Aarẹ ninu eto idibo to n bọ.

Cummings tu kẹkẹ ọrọ lasiko to n ba ileeṣẹ BBC sọrọ lori awọn erongba to ni lọkan lati ṣe fun orilẹede Liberia to ba di Aarẹ ilẹ naa.

O tesiwaju pe o ṣe koko ki ijọba da ileẹjọ ti yoo ma dasẹri fun awọn eeyan to ba lọwọ ninu ogun abẹlẹ lorilẹede naa.

“Mo ro pe o si ṣeto ileẹjọ to n gbọ ẹjọ nipa ogun abẹle lati a le se ijiya, nipa ti le fihan pe ijiye yoo wa fun ẹnikẹni to ba lọwọ ninu ogun abẹle.

Aworan Alexander Cummings

“O ṣe koko fun wa lati le fi opin si itan orilẹede wa yii, ki a si tẹsiwaju si omiran. Fun idi eyi, bẹẹni a yoo ṣe eyi sugbọn yoo da lori ẹri ati iwadi to jina.

“A yoo finukonu lori ilana ti a yoo tọ nigba ti a a ba da silẹ ati igba ti a yoo da silẹ.

Bakan naa ni Cummings bu ẹnu atẹlu ọrọ ti awọn ololufẹ ẹgbẹ oṣelu alatako kan n sọ pe ti oludije kan ko ba bori gẹgẹ bi Aarẹ, o ṣeese ki opin de ba orilẹede Liberia.

“Mo ro pe o jẹ ẹru ati itaniloju fun eyikeyi olori orilẹede yii lati sọ asọye naa, ti o mọ itan ti orilẹede wa, ti o mọ ohun ti a lakọja ọdun mẹrinla lasiko ogun abele.

“O to igba ọmọ orilẹede Liberia to padanu ẹmi wọn. Mo ro pe o jẹ iwa aibikita.

“Mo ro pe o jẹ iwa ti ko bojumu. Oju-iwoye wa ni gbogbo ohun ti a fẹ ni nigbati awọn abajade ba jade, o ṣe afihan ifẹ ti awọn eniyan Liberia. Nigbati iyẹn ba ṣẹlẹ, ma gba abajade naa.”