Àwọn 'sisitá' tó ń ṣòwò igbó múra sí àdúrà torí àìtà ọjà
- Author, Ahmed Ambali
- Role, Broadcast Journalist
$1m làwọn ‘sisitá onígbó’ ń pa lọ́dún àwọ́n àìtà ọjà ló fa ìpàdé àdúrà

Aramọnda, ki ni iru eyi ni iroyin yii jẹ, paapaa fawọn ọmọ Naijiria ti iwa gbingbin, tita ati mimu igbo tako ofin lorilẹede wọn.
Amọ bi eeyan ba de ọkan ninu ile tawọn sista to wa ninu apilẹkọ yii n gbe, ko fẹ ẹ si ohun to mu ile naa yatọ si awọn ile mii layika rẹ.
Amọ bi eeyan ba ti n sunmọ ibẹ, ni yoo ri tawọn obinrin yii n sun turari, ti wọn si n kọ orin ẹmi.
Orukọ ijọ awọn sista yi ni ''Sister of the Valley'' tawọn eeyan mọ si apejẹ orukọ ''awọn sista onigbo''
Ko si nkankan to tọka si pe awọn sistaonigbo yii ni nkan ṣe pẹlu igbo, bi eeyan ba ri wọn.
Labẹ akoso olori wọn, Sister Kate, awọn obinrin yi jẹ ọmọ ijọ to pe ara wọn ni oluwosan ati ajafẹtọ obinrin.
Sugbọn ni pataki wọn ri ara wọn gẹgẹ bi oniṣowo igbo.
Ẹsin awọn sista onigbo yatọ si awọn eleyi taa mọ
Awọn sista onigbo kii sọ pe ẹsin bayi ni pato ni ẹsin tawọn n tẹle.
'Sister Kate to jẹ olori wọn sọ pe ''Mo yan ẹka to ṣe pe nkan ko ṣe deede pẹlu rẹ''
O fi kun ko daju pe oun ko ni maa ri awọn ipenija lorisirisi bi oun ba ti n ba iṣẹ naa lọ.
Ohun to n mẹnu ba si ni bi ofin ipinlẹ California ti ṣe lawọn abala to ta koko, lori ọrọ ẹka to n pese igbo.
California jẹ ipinlẹ kan gbogi ti gbingbin ati tita igbo ti burẹkẹ.
O jẹ ipinlẹ akọkọ ni Amẹrika ti wọn ti faaye gba igbo lilo fun itọju ilera ni 1996.
Ṣugbọn ofin taa n wi yii ni ọpọ kudiẹkudiẹ, eyi to tumọ si pe, ofin to de gbingbin igbo lawọn ileto kan si omiran yatọ si ara wọn ni ipinlẹ naa.

"Ọga ọlọpaa mọ igbo gbingbin nita ko bofin mu amọ o faaye gba wa"
Tori naa, pẹlu bi ofin ti faaye gba lilo igbo ni ipinlẹ California, ida meji ninu ida mẹta awọn ilu ni ipinlẹ naa, lo fofin de owo igbo tita.
Koda, awọn ilu miran nipinlẹ Califonia jẹ ko ṣoro fun ẹni ba fẹ gba iwe aṣẹ lati ṣe iṣẹ yi.
A si le sọ pe bi awọn ijọ Sisters of the Valley se n n gbin igbo wọn ni ita gbangba jẹ nkan ti ko bọ si abẹ ofin.
Sister Kate jẹwọ pe ''Ọga ọlọpaa mọ pe ko ba ofin mu ṣugbọn o kan faaye gba wa lati maa gbin igbo wa nita ni''
O fi kun pe ''lootọ lawọn alaṣẹ mọ pe awọn ko lẹtọ lati gbin igbo ṣugbọn ohun to daju ni pe bi wọn bba tako wa, a o kan pe wọn lẹjọ lati yi ofin yi pada ni''
Igbo miliọnu kan dọla o le diẹ lawọn sista onigbo n pa lọdọọdun
Igbo tawọn Sister yi n ta, a maa mu owo tabua wọle fun wọn ṣaaju asiko ti ajakalẹ Covid-19 bẹrẹ.
Nkan bii miliọnu kan le diẹ dọla ni wọn maa n pa lọdọọdun ṣugbọn ọja ko ya lẹnu lọọlọ yi.
Eyi lo mu ki wọn kun fun adura pe ki aje bu igba wọn jẹ, ki awọn to n ra igbo tubọ pọ ju ti tẹlẹ lọ.















