Mo gbíyànjú títí kí ọmọ mi jáwọ́ nínú òògùn olóró àti ọtí kó tó kú àmọ́ ... - Ebenezer Obey

Ebenezer Obey ati ọmọ rẹ, olayinka to di oloogbe

Oríṣun àwòrán, Others

"Nkan to ṣẹlẹ si ọmọ oun yii, lo mu ki n pinnu lati da ajọ kan silẹ, ti yoo ma ṣe iranlọwọ fun awọn obi to ba ni iru ọmọ to n mu oogun oloro ati ọti".

Agba akọrin Juju, Oloye Ebenezer Obey-Fabiyi, ti fesi lori iku ọkan lara awọn ọmọ rẹ, Olayinka Olalekan, to jade laye ni ọjọ Ẹti, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Keje, ọdun 2022, ni ẹni ọdun mejidinlaadọta.

Wọn si ti sin oku rẹ ni ọjọ keji, ọjọ Satide Ọgbọnjọ, oṣu Keje, ọdun 2021.

Ninu atẹjade to fi sita fun awọn akọroyin ni ọjọ Iṣẹgun, Oloye Obey-Fabiyi sọ pe oṣu mẹfa sẹyin ni awọn dokita ti sọ fun oun pe Olayinka ko ni to oṣu mẹfa ti yoo lo laye mọ.

“Iroyin ibanujẹ gbaa ni, ti baba ko gbọdọ gbọ nipa ọmọ rẹ.”

Obey to dupẹ lọwọ awọn eeyan nile ati nilẹ okeere, to n baa kẹdun iku ọmọ rẹ ọhun, sọ pe ọmọ naa ku latari ipa ilokulo oogun oloro ati ọti.

O ṣalaye pe gbogbo igbiyanju oun lati mu ki ọmọ naa dẹkun ‘ṣugbọn’ aye rẹ, lo ja si ofo.

O ni nkan to ṣẹlẹ si ọmọ oun yii, lo mu ki oun pinnu lati da ajọ kan silẹ, ti yoo ma ṣe iranlọwọ fun awọn obi to ba ni iru ọmọ bẹẹ.

“Nigba ti awọn dokita sọ asiko ti Yinka yoo ku fun mi, mo ba Ẹmi Mimọ sọrọ, lati kọ mi ni nkan ti ma a ṣe lori ọrọ rẹ. Ṣugbọn idahun to fun mi ni pe ki n da ileeṣẹ iranṣẹ silẹ fun ipolongo tako ọti amupara ati ilokulo oogun oloro.”

Oloye obey sọ pe ileeṣẹ iranṣẹ naa, "Freedom from Alcohonism and Drug Addiction Ministry", yoo jẹ akitiyan oun lati gbogun ti ọti amuju, ati lilo oogun oloro, paapaa laarin awọn ọdọ ni Naijiria ati awọn to wa nilẹ okeere.

O ni lootọ ni oun mọ riri ibanikẹdun awọn eeyan, ṣugbọn oun fẹ ki wọn o sọ awọn ibanikẹdun ti wọn ba tun fẹ ṣe, di adura ati atilẹyin fun iṣẹ iranṣẹ tuntun naa, fun idande awọn to wa ninu ewu amuju ọti ati oogun oloro lilo.

Yatọ si eyi, o ni iṣẹ iranṣẹ FADAM, yoo tun ma a ṣe iranlọwọ fun awọn obi ati ẹbi awọn ọmọ tabi ọdọ ti oogun oloro ati ọti ti sọ di idakuda, ki wọn o le di eeyan gidi ni awujọ.