Mi ò kú o, ko ko ko lára ọ̀ta mi le! Ohun tí mo sọ fáwọn tó ń pè mi nìyí – Kabiyesi Onjo ti ìlú Okeho

Oríṣun àwòrán, Mustapha Mufeed Adeola Dallax
“Aa ki n gbọ́ iku ọkọ, ai gbọ iku ada, ko ko ko lara ta maa n le” ni ọrọ to n jade lati aafin Onjo ti ilu Okeho.
Lodi si iroyin to kun gbogbo ilu ti o si ti n fo lọ lọtun losi lori awọn oju iwe iroyin kan pe Oriade ti ilu Okeho, Onjo ilu Okeho, Ọba Abdulrafiu Mustapha Osuolale Adeitan Keji ti waja, Kabiyesi gan ti fi ohun sita pe irọ patapata gbaa ni o.
Loju opo facebook akọroyin kan to gbera kan lọ si ilu Okeho lẹyin to ni gbogbo eeyan bẹrẹ si ni pe oun kaakri agbaye, Mustapha Mufeed Adeola Dallax fi fidio ipo ti Kabiyesi hun wa sita fun araye lati mọ.
Bawo ni Aafin Onjo ti Okeho ṣe ri lonii?

Oríṣun àwòrán, Mustapha Mufeed Adeola Dallax w
Ninu aafin Onjo, ṣe ni awọn araale tu jade ti awọn araalu naa si lọ aafin lati farahan pẹlu Ọba wọn pe irọ ni awọn iwe iroyin ti wọn ka ọhun pa o.
Ṣe ni awọn iwe iroyin kan n gbe iroyin pe Ọba alaye naa ti ṣe bẹẹ re iwalẹ aṣa pe baba ti tẹri gbasọ.
Ẹwẹ, Kabiyesi ni bo tilẹ jẹ pe ojojo ṣe oogun lẹnu ọjọ mẹta yii ti oun si gba itọju ni ileewosan ti ijọba, UCH Ibadan.
“Lootọ, o tẹ mi diẹ ti wọn si gbe mi lọ si ileewosan UCH ni Ibadan, wọn tọju mi, mo si kuro ni ọjọ Kẹrinlelogun Oṣu Keje”.
O ṣalaye pe lati igba ti oun ti de ile naa tun ni awọn dokita ti n ṣe itọju oun.
“Nkankan o ṣe mi o, mo wa laye o, emi naa gbọ laarọ yii ti wọn ni ọta awọn ti ku amọ irọ nla emi o ku o, mi o si ni ku”.
Gbogbo araalu to wa laafin naa si pariwo aṣẹ. Kabiyesi ni gbogbo awọn araalu to n wa naa lo n ba oun lori ijoko ni aafin.
Oba Elero ti Ilero naa wa si Aafin ilu Okeho lati fara kin Ọba akẹgbẹ rẹ sọ faraye pe aaye ni baba wa.
Bakan naa ni awọn amugbalẹgbẹ Ọba ti wọn n baa gbe ti wọn si n sun si aafin rẹ sọ iriri rẹ pẹlu gbogbo awọn to n pe wọn lati UK atawọn orilẹede mii.
















