'N87,000 là ń ra egungun agbárí òkú'- Wo bí Hamza se dèrò ẹ̀wọ̀n fẹ́sùn ṣíṣòwò ẹ̀yà ara ènìyàn ní Ilorin

Àwòrán orí ènìyàn

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT

Ilé ẹjọ́ Májísírèètì kan ní ìlú Ilorin ìpínlẹ̀ Kwara ti ju afurasí kan, Ibrahim Hamza sí ọgbà ẹ̀wọ́n fẹ́sùn ṣíṣe òwò ẹ̀yà ara ènìyàn.

Ní nǹkan bí ọ̀sẹ̀ méjì sẹ́yìn ni àwọn ọlọ́pàá nawọ́ gán Hamza ní ibùdó ọkọ̀ kan ní agbègbè Balogun Fulani, ìlú Ilorin.

Agbárí òkú ènìyàn ni wọ́n bá lọ́wọ́ ẹ̀ nígbà tí wọ́n fi mu u.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá fẹ̀sùn kan Hamza, ẹni ọdún mọ́kànlélógójì pé ó ń ṣòwò títà àti ríra ẹ̀yà ara ènìyàn, èyí tó máa ń wáyé láàrín Ilorin sí Eko.

Wọ́n ní ìwádìí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé afurasí ọ̀hún jẹ́wọ́ pé Awal kan tó ń gbé ìlú Eko ló fi egungun orí ènìyàn tí wọ́n ti fọ́ sí wẹ́wẹ́ náà ránṣẹ́ sí òun gba ti ọkọ̀ èrò.

Bákan ni wọ́n fi kun un pé ó ní òun máa ń lo egungun náà láti fi ṣe ògùn owó àti láti kórè oko tó pọ̀.

Ọlọ́pàá fi kun pé ó jẹ́wọ́ wí pé ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínláàdọ́rùn-ún náírà ló ná òun láti fi ra egungun agbárí òkú, ti tẹṣin àti ìnàkí.

Ó ní àwọn nǹkan wọ̀nyí ni òun máa ń gún papọ̀ láti fi ṣe ajílẹ̀ fún oko òun.

Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ni ìwádìí ṣì ń lọ lọ́wọ́ láti fi póró òfin gbé Awal.

Nígbà tí wọ́n ka ẹ̀sùn Hamza si léti ní ilé ẹjọ́, ó tọrọ ojú àánú lọ́wọ́ adájọ́ ṣùgbọ́n adája kọ̀ láti gba ẹ̀bẹ̀ rẹ̀, tó sì ní kí wọ́n lọ fi sí àhámọ́ títí ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ yóò fi tẹ̀síwájú,