Ohun tí a mọ̀ rèé nípa àwọn ibùdó tí Amẹrika ní ó ṣeé ṣe kí Iran sèkọlù sí ní Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images/Bola Ahmed Tinubu/X
Olu ileeṣẹ orilẹede Amẹrika ni Naijiria ti kilọ fawọn eeyan orilẹede naa to wa ni Naijiria wi pe ki wọn ṣọra ṣe tori o ṣee ṣe ki Iran ṣe ikọlu sawọn ibudo Amẹrika ati awọn ile ẹkọ to n ṣiṣẹ pọ pẹlu ilẹ naa to wa ni Naijiria.
Olu ileeṣẹ Amẹrika to wa niluu Abuja kilọ fawọn ọmọ Amẹrika ninu atẹjade kan to fi sita wi pe ki wọn wa lojufo nigba kugba ti wọn ba wa ni olu ileeṣẹ naa tabi lawọn ile ẹkọ to ni ibaṣepọ pẹlu Amẹrika.
Ikilọ jade ninu atẹjade ọhun papaa julọ fawọn to ba fe lọ si olu ileeṣẹ Amẹrika to wa niluu Abuja ati ilu Eko pe wọn gbọdọ mu eto aabo wọn ni ọkun-kundun.
Olu ileeṣẹ Amẹrika gbawọn ọmọ ilẹ naa ti wọn wa ni Naijiria ni imọran wi pe ki wọn ma gba ọna kan ṣoṣo lọ sibi ti wọn ba n lọ.
Imọran tun jade wi pe kawọn ọmọ Amẹrika ni Naijiria ṣe ayipada akoko ti wọn ba fẹ lọ si ibi kibi, ati pe ki wọn wa lojufo nibi kibi ti wọn ba lọ.
Amẹrika tun gbawọn eeyan ilẹ naa ni imọran wi pe ki wọn ma wọ aṣọ nla lọ sibi kankan lasiko yii.
Bakan naa ni olu ileeṣẹ Amẹrika tun gbawọn ọmọ Amẹrika ni imọran wi pe ki wọn ma duro si aarin ọpọ eeyan tabi nibi ti ifẹhonuhan ti n ṣẹlẹ.
Olu ileeṣẹ Amẹrika tun sọ awọn ọmọ Amẹrika ni Naiiria pe ki wọn ri pe ina wa lori foonu wọn nitori iṣẹlẹ pajawiri to le waye.
Wọn tun ni kawọn ọmọ Amẹrika mọ ọna ti wọn le gba jade nibi kibi ti wọn ba wa tori iṣẹlẹ pajawiri to le ṣẹlẹ.
Amọ, Amẹrika sọ pe olu ileeṣẹ awọn niluu Abuja ati ilu Eko yoo si wa ni ṣiṣi bo tilẹ jẹ pe Iran ti dunkoko lati ṣekọlu si Naijiria.
Olu ileeṣẹ Amẹrika sọ pe kawọn ọmọ Amẹrika to wa ni Naijiria si maa lọ sori ikanni olu ileeṣẹ Amẹrika fun iroyin atigba degba.
Ikilọ yii jẹyọ latari ogun to n lọ lọwọ laaarin Amẹrika, Israel ati Iran.
Ni ọjọ kejidinlọgbọn oṣu Keji ni ogun naa bẹrẹ, tawọn orilẹede mẹtẹẹta ọhun si ti n ju oriṣiiriṣii ado oloro sira wọn lati igba naa titi di akoko yii.
Ogun pẹlu Iran yoo pari laipẹ - Trump
Ẹwẹ, Aarẹ Donald Trump ti sọ pe ogun to n lọ lọwọ pẹlu Iran yoo pari laipẹ.
Oriṣiiriṣii ado oloro ni Amẹrika ti ju si Iran lati ọjọ kejidinlọgbọn oṣu Keji, nigba ti Iran naa si n ṣe ikọlu sawọn ibudo ologun Amẹrika to wa lawọn orilẹede to wa ni ayika wọn.
Ọjọ akọkọ ti Amẹrika yin ado oloro si Iran ni adari orilẹede naa, Ayatollah Ali Khamenei, ku.
Ni bayii ti ogun naa ti wọ ọsẹ keji, Trump ni ogun naa le pari laipẹ tori Amẹrika ti ṣe aṣeyọri nla pẹlu ikọlu ti wọn ṣe ni Iran.
Aarẹ Amẹrika ni awọn ọmogun orilẹede naa ti ṣiṣẹ ribi ribi lorilẹede Iran.
Trump sọ pe ko din ni ida ọgọrin nnkan ija oloro ti Iran fi n yin ado oloro tawọn ọmọgun Amẹrika ti bajẹ.
Aarẹ ni Amẹrika tun ti ba awọn ọkọ oju omi ijagun Iran jẹ
O ni ile aye yoo dun gbee sii lẹyin ti Amẹrika ba pari ogun ti o n ja ni Iran tan.
Iran tako ọrọ ti Trump sọ pe ogun to n lọ yoo pari laipẹ
Orilẹede Iran ti tako ọrọ ti Aarẹ Donald Trump Amẹrika sọ pe ogun to n lọ lọwọ laarin orilẹede mejeeji ati Israel le pari laipẹ.
Ọrọ yii jade lẹyin ti Trump sọ fawọn eeyan nibi iwọde kan ni Florida wi pe Amẹrika ti ṣe oniruuru aṣeyọri pẹlu ikọlu ti wọn ṣe si Iran.
Trump tun sọ pe Iran n gbero lati ṣekọlu si Amẹrika, amọ, o ni ko si ẹri to daju to le fidi eyi mulẹ.
Bakan naa tun ni Trump sọ pe Iran ti n gbiyanju lati ṣe itaji ibudo ija oloro rẹ.
Nigba ti wọn beere lọwọ Trump bo ya Amẹrika yoo ṣe ikọlu si adari Iran tuntun, Ayatollah Mojtaba Khamenei, aarẹ Amẹrika ni oun ko le sọ ṣugbọn inu oun ko dun iyansipo rẹ.


























