A gbọ́dọ̀ gba ilẹ̀ wa padà lọ́wọ́ àwọn agbèṣùmọ̀mí - ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá Tunji Disu fọnmú

Ọga ọlọpaa Naijiria, Tunji Disu ati Kọmiṣanna Ọlọpaa Kwara, Adekimi Ojo
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, Olatunji Ridwan Disu ti ni o pọn dandan lati gba ipinlẹ Kwara pada lọwọ awọn agbeṣumọmi ti wọn n yọ ọ lẹnu.

Disu sọ eyi ninu ọrọ rẹ nigba to ṣe abẹwo si ilu Ilorin, olu ilu ipinlẹ Kwara lori ipo ti ipinlẹ naa wa lori eto aabo.

Ẹ o ranti pe lati bii ọdun diẹ sẹyin bayii ni ipinlẹ Kwara ti n koju ijinigbe, ipaniyan ati awọn iwa ọdaran mii eyi to ti sọ ọpọ awọn olugbe ipinlẹ naa sinu inu fu aya fu.

Ikọlu awọn onisẹ ibi yii si gbilẹ debi pe ko fẹ ẹ si ọjọ kan si meji ti a o ni gbọ iroyin ijinigbe tabi ipaniyan ni ilu kan tabi omiran ni ipinlẹ Kwara.

Iwadii tilẹ fidi rẹ mulẹ pe, yatọ si aarin gbungbun ipinlẹ naa to jẹ Ilorin ati agbegbe rẹ, ko fẹ ẹ si ibi ti eeyan ti le sun oorun a sun diju lawọn ilu kan ni ẹkun guusu ati ariwa Kwara.

'A maa pese gbogbo ohun inilo lati ṣẹgun awọn agbebọn ti wọn n da omi alaafia ipinlẹ Kwara ru'

Ọga agba ọlọpaa, Tunji Disu sọ pe, oun ṣe abẹwo si ipinlẹ Kwara nitori oun mọ awọn ipenija ti ipinlẹ naa n koju lasiko yii.

O ni abẹwo oun ko ṣẹyin lati wo awọn ọmọ ogun oun lẹnu iṣẹ ati lati awọn ọna ti oun le gba ran wọn lọwọ lati ri pe wọn bori ogun yii atawọn ipenija ti wọn n koju naa.

O sọ pe oun ti ba Kọmiṣanna ọlọpaa Kwara sọrọ, oun si tun setan lati tẹti si ẹdun ọkan rẹ siwaju sii.

O wa ṣeleri pe igba ti oun ba pada si Abuja, oun yoo pese gbogbo ohun ti wọn nilo ni Kwara lati ṣẹgun awọn agbebọn ti wọn n da omi alaafia ipinlẹ naa ru.

Bakan naa lo woye pe igba ọtun ti de bayii fawọn ọlọpaa nitori oun n ti ṣeto lati ri pe igbayegbadun wọn gbe pẹẹli si.

"Mo mọ Ipinlẹ Kwara, mo si mọ ohun to n sẹlẹ.

"A gbọdọ gba ilẹ wa pada, awọn ọdaran yii o gbudọ le wa kuro ni ile wa.

"Awa la o le wọn tefetefe, ti a o si gba ilẹ ati agbegbe wa pada.

"Kwara ni ipinlẹ akọkọ ti maa ṣe abẹwo si lẹyin ti mo di ọga agba ọlọpaa ni Naijiria.

IG ṣèlérí ìgbà ọ̀tun fún àwọn ọlọ́pàá

Disu tun ni oun maa gbiyanju agbara oun lati ri pe awọn ọlọpaa ri ẹtọ wọn gba ki igbayegbadun wọn si lọ soke si.

O woye pe iṣẹ ọlọpaa jẹ iṣẹ ẹlẹgẹ nitori pe ti ọlọpaa ba n dagbere nile pe oun lọ si ibi iṣẹ, ko le sọ boya oun yoo pada wale laaye nitori bi iṣẹ naa ṣe lewu si.

"Fun idi eyi, o ṣe pataki fun wọn lati gbe igbeaye irọrun. Ko si tun ni da ki wọn maa jẹya leyin ifẹyinti."

Tunji Disu ti wá láti parí isẹ́ tó bẹ̀rẹ̀ - Kọmiṣanna ọlapaa Kwara

Ninu ọrọ idupẹ rẹ, Kọmiṣanna ọlọpaa ni Kwara, Adekimi Ojo sọ pe, Tunji Disu ti ṣaaju ṣabẹwo si Kwara nigba to wa ni igbakeji ọga ọlọpaa Naijiria, AIG to si ti bẹrẹ iṣẹ lori lile awọn agbeṣumọmi kuro ni ipinlẹ naa.

O ni oun gbagbọ pe bayii to tun ti ṣabẹwo si ipinlẹ Kwara gẹgẹ bii ọga agba patapata fun ọlọpaa ni Naijiria, yoo pari iṣẹ to ti bẹrẹ.