Ẹ ṣọ́ra ṣe lórí èròngbà yín láti yọ Buhari nípò - Kwankwaso

Oludije fun ipo aarẹ ninu ibo ọdun 2023, labẹ asia ẹgbẹ NNPP, Rabiu Kwankwaso ti kilọ fun awọn aṣofin to ba n gbero lati yọ Buhari nipo pe ki wọn o ṣọra ṣe.
Iwe iroyin Daily Trust jabọ pe Kwankwaso sọ eyi lasiko abẹwo rẹ si gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazak, nilu Ilorin.
O ni ki awọn aṣofin naa o ma ṣe fi ikanju gbe igbesẹ lori erongba wọn.
Kwankawaso ti oun funra rẹ ti fi igba kan jẹ minisita fun eto aabo ni Naijiria, sọ pe lootọ ni ibẹru wa nipa aabo ni Naijiria, o ni ṣugbọn ko bojumu bi ijọba ko ṣe gbọ igbe araalu lati wa ọna abayọ.
Ọjọru, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Keje, ni awọn aṣofin kan lati inu ẹgbẹ alatako, sọ pe awọn fun Aarẹ Muhammadu Buhari ni gbedeke ọsẹ mẹfa lati wa ojuutu si iṣoro to n koju eto aabo ni Naijiria, bi bẹẹ kọ, awọn yoo yọ ọ nipo.
Wọn ni dandan awọn fẹ ‘pass motion’’ ti yoo kan an ni ipa fun aarẹ Buhari lati bojuto aabo to dẹnukọlẹ kaakiri Naijiria.
Eyi mu ki awọn aṣofin ni ẹgbẹ alatako naa parapọ jade kuro ninu Ile Aṣofin naa, ti wọn si n paruwo aarẹ Buhari gbọdọ kuro nipo aarẹ
Amọ ileeṣẹ aarẹ, lati ẹnu agbẹnusọ fun Buhari, Garba Shehu, sọ pe awọn aṣofin naa n fi akoko wọn ṣofo ni pẹlu erongba wọn.
Ninu ọrọ to kọ sori Twitter, Shuhu ni, igbesẹ to dara ni bi aarẹ ile aṣofin, Sẹnetọ Ahmad Lawan, ṣe kọ aba ‘apani lẹrin’ naa.
O ni gbogbo ipa ni Buhari n ṣa lati wa ọna abayọ si ipenija aabo.













