Olùdíje tó bá ṣèlérí láti ṣe àtúntò Nàìjíríà la máa ṣe àtìlẹyìn fún – Afenifere

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT
Ẹgbẹ́ Afenifere ilẹ̀ Yorùbá ti ṣàlàyé ẹni tí wọ́n máa ṣe àtìlẹyìn fún níbi ètò ìdìbò ọdún tó ń bọ̀.
Nígbà tí iléeṣẹ́ BBC News Yorùbá kàn sí ẹgbẹ́ Afenifere láti mọ ìpinnu wọn gangan lórí ìròyìn tó ń jà ràìnràìn káàkiri wí pé olùdíje sípò Ààrẹ lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party, Peter Obi ni olórí ẹgbẹ́ náà fẹ́ tì lẹ́yìn níbi ètò ìdìbò tó ń bọ̀.
Agbẹnusọ Afenifere, Jare Ajayi sọ fún BBC Yorùbá pé kí àwọn tó le yan ẹnìkan ṣojú tàbí ṣe àtìléyìn fún olùdíje kankan, àwọn gbọ́dọ̀ mọ ohun tí ẹni náà ní fún àwọn ọmọ orílẹèdè̀ Nàìjíríà.
Ajayi ní ohun tí àwọn ti ń jà fún gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ láti bí ọjọ́ mẹ́ta ni bí àyípadà ọ̀tun ṣe ma bá Nàìjíríà, fún ìdí èyí olùdíje tó bá le ṣe ìlérí irú àyípadà bẹ́ẹ̀ fún àwọn ni ẹgbẹ́ ma tẹ̀lé.
Ó ní ó pọn dandan kí àwọn ṣe ìpádé pẹ̀lú gbogbo àwọn olùdíje láti jọ fi ẹnu jóná lórí ohun tí wọ́n ma ṣe lórí àtúntò Nàìjíríà kí àwọn tó mọ́ ẹni tí àwọn ma gbé àtìlẹyìn àwọn fún.
Ó tẹpẹlẹ mọ ọ́ wí pé ohun tó jẹ ẹgbẹ́ Afenifere lógún jùlọ ni bí àtúntò yóò ṣe bá Nàìjíríà, tí agbára yóò sì pín káàkiri ẹsẹ̀ kùkú, tí tọmọdé tàgbà ma lè jẹ́ mùdùn-múndùn ìjọba àwaarawa.
Ajayi sọ síwájú pé nígbà tí àwọn bá ṣe ìpádé pẹ̀lú àwọn olùdíje kọ̀ọ̀kan, èyí tó bá le ṣèlérí àwọn nǹkan wọ̀nyí fún àwọn ni ẹgbẹ́ máa tẹ̀lé gẹ́gẹ́ bí olùdíje sípò Ààrẹ.
“Ìdásílẹ̀ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀, bí wọ́n ṣe máa pín Nàìjíríà sí ẹlẹ́kùnjẹkùn ṣe pàtàkì, tí gbogbo nǹkan ma ma lọ bó ṣe yẹ ko lọ.”
“Tó jẹ́ wí pé gbogbo àwọn nǹkan ọrọ̀ àti àlùmọ́nì tí Ọlọ́run fi sí ilẹ̀ kálukú àwọn tó ni í ló ma kọ́kọ́ jẹ àǹfàní rẹ̀ ná ni a ma gbé síwájú àwọn tó ń díje.”
“Ẹní tó bá wá le fihàn wá pé ètò ti òun ní nípa àwọn nǹkan wọ̀nyìí, nípa iná, omi, ẹ̀kọ́, àláfíà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ni a ma wá jíròrò lórí ẹ̀ wí pé ibi tí à ń lọ nìyí.”
Bàbá Adebanjo kọ́ ló sọ̀rọ̀ tó wà ní Twitter o
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ìròyìn tó wà lórí ayélujára Twitter adarí ẹgbẹ́ Afenifere pé Tinubu ma tẹ̀síwájú pẹ̀lú àwọn ìpèníjà tí ìṣèjọba Ààrẹ Buhari kojú, Ajayi ní ojú òpó náà kìí ṣe ti bàbá Adebanjo.
Ajayi fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé lóòótọ́ ni adarí àwọn ń ṣe àtìlẹyìn fún Peter Obi, ṣùgbọ́n kìí ṣe nítorí ìdí tó wà lórí àtẹ̀jáde Twitter náà.
Nínú àtẹ̀jáde kan tí Jare Ajayi fi ṣọwọ́ sí BBC Yorùbá ní ìdí tí bàbá Adebanjo ní àwọn fi ń tẹ̀lé Obi kò kọjá ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn àti àlàkalẹ̀ ìwé òfin Nàìjíríà.
Bákan náà ló là á mọ́lẹ̀ pé bàbá Adebanjo kò ní ojú òpó kankan lórí ayélujára nítorí náà kí àwọn ṣọ́ra láti máa gbé ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ lórúkọ bàbá.
Ohun tí Tinubu fẹ́ ṣe tó fi ń ran kankan mọ́ pé ó fẹ́ di ààrẹ rèé - Pa Adebanjo

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT
Ṣáájú láti kọ́kọ́ mú ìròyìn kan tó gba orí ayélujára kan èyí táwọn oníròyìn bẹ̀rẹ̀ sí ní gbé pé Ààrẹ ẹgbẹ́ Afenifere ilẹ̀ Yorùbá, Pa Ayo Adebanjo ti ṣàlàyé ìdí tí kò ṣe fẹ́ kí Asiwaju Bola Ahmed Tinubu di Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Pa Adebanjo ló ti ń ṣe àtìlẹyìn fún olùdíje ẹgbẹ́ ò’sèlú Labour Party, Peter Obi.
Nínú àtẹ̀jáde kan tí a rí lórí Twitter tó ní orúkọ Bàbá Adebanjo ní ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Àbámẹ́ta, oṣù Keje, ọdún 2022, ó ní Tinubu maa tẹ̀síwájú àìkún ojú òṣùwọ̀n ààrẹ Muhammadu Buhari.
Adebanjo náà tún ní gbogbo àwọn ìpèníjà tó kún ìṣèjọba ààrẹ Muhammadu Buhari náà ni Tinubu náà ma tẹ̀síwájú nípa rẹ̀ ní èyí tí kò sí ní so èso rere fún Nàìjíríà.
Adebanjo ní àwọn mọ Peter Obi dada wí pé kò ní já àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè lulẹ̀.
Ó ní kí àwọn ènìyàn gbé ti ẹlẹ́yàmẹ̀yà tì sí ẹgbẹ́ kan wí pé Obi ló le tú ọkọ̀ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà dé èbúté ògo.
Bàbá Adebanjo ní báyìí, òun ti bẹ̀rẹ̀ ṣíṣe ìpolongo fún Peter Obi káàkiri Nàìjíríà, kí àwọn ènìyàn sì ṣe àtìlẹyìn fún òun láti SỌ Obi di Ààrẹ Nàìjíríà lọ́dún 2023.
Ó fi kun pé ó dá òun lójú wí pé Peter Obi ma ṣe dada tó bá dé ipò Ààrẹ ju Tinubu lọ.
Ó tẹ̀síwájú wí pé òun kò ní ìfọkàntán nínú Bola Tinubu àti pé ó tẹ́ òun lọ́rùn kí Obi ṣe ààrẹ ju Tinubu lọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
Ẹ̀yà Igbo ni ààrẹ Nàìjíríà kàn
“Nígbà tó jẹ́ wí pé gbogbo ìgbà ni à ń pè fún dọ́gba-n-dọ́gba, mo rò wí pé àsìkò ti tó kí àwọn ẹ̀yà Igbo ṣe Ààrẹ Nàìjíríà, fún ìdí èyí, Peter Obi ni mò ń ṣe àtìlẹyìn fún.
Ṣaájú àkókò yìí ni ẹgbẹ́ Afenifere ti ń bèèrè fún ṣíṣe àtúngbéyẹ̀wò ìwé òfin Nàìjíríà.
Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n tún pè fún àtúntò Nàìjíríà gbogbo ìpèníjà tó ń bá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà fínra.















