Wo bí ìdá márùn ún nínú ọgọ́rún 5% tí ìjọba Naijiria fi kún owó orí ìpè, àtẹ̀jíṣẹ́ àti Data ṣe kàn ọ́

Ẹni to mu foonu dani

Oríṣun àwòrán, Techpoint africa

Minisita eto ẹnawo ati iṣuna ni Naijiria, Zainab Ahmed, sọ pe awọn ọmọ Naijiria yoo ni afikun ida marun-un owo ori lori

O ṣalaye ọrọ naa nibi ipade ijororo kan to waye nilu Abuja l’Ọjọbọ pe owo ori tuntun na yoo gun owo ipe, atẹjiṣẹ, data, ati awọn nkan mii ti araalu n sanwo rẹ fun awọn ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ.

Arabinbrin Ahmed sọ pe lati ọdun 2020 ni Aarẹ Muhammadu Buhari ti buwọlu ofin naa, ṣugbọn idaduro ba a nitori ijiroro ti ijọba n ṣe pẹlu awọn alẹnulọrọ.

Ẹni to ṣoju rẹ nibi ipade naa, Frank Oshanipin, sọ pe oṣooṣu ni owo naa gbọdọ ma a wọle, o pẹju ọjọ kọkanlelogun.

O ni nkan to hàn si gbogbo eeyan ni pe owo to n wọle fun ijọba ko to o gbọ bukaata Naijiria mọ, nitori naa ni ‘a ṣe n wa owo lori awọn nkan ti kii ṣe eporọbi.

“Ojuṣe gbogbo wa ni lati pese owo ti ijọba yoo ma a ná.”

Ẹni to jẹ alaga fun ẹgbẹ awọn to ni ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ ni Naijiria (ALTON), Gbenga Adebayo, sọ pe awọn onibara awọn ni yoo tu ẹru afikun ida marun-un owo ori tuntun naa.

O ni pẹlu afikun naa, ida mejila abọ ni owo ori ti awọn onibara ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ yoo ma san bayi.

Adebayo sọ pe awọn ileeṣẹ naa ko ni le gbọ bukaata ida marun-un naa, nitori owo ori ọna mkandinlogoji ti wọn n san fun ijọba lọwọlọwọ, ati obitibi owo ti awọn n na lori epo diesel nitori ina mọnamọna ti ko duro deedee.

aworan foonu kan

Oríṣun àwòrán, other

Ninu ọrọ tiẹ naa, oludari agba fun ajọ to n mojuto ibaraẹnisọrọ, Ọjọgbọn Umar Garba Danbatta sọ pe ijọba apapọ n foju wo ajọ naa lati ko ipa pataki ninu ipese owo fun ijọba lati gbọ bukaata owo isuna, ati ojuṣe rẹ si awọn ọmọ Naijiria.

Ofin tuntun yii wa lara awọn nkan ti ijọba la kalẹ lati ma a gba owo lori wọn, ti wọn n pe ni excise duty.

Excise duty ni owo ori ti ijọba n gba lọwọ ileeṣẹ fun ọja ti wọn ṣe. O tun jẹ ọna lati san owo ori fun ijọba lori awọn nkan ti o ba n ra tabi sanwo fun gẹgẹ bi araalu.

aworan foonu kan

Oríṣun àwòrán, other

Lara iru awọn ọja bẹẹ ni tobacco, ọti lile, tẹtẹ, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Laipẹ yii ni ijọba fi awọn nkan ẹlẹrindodo, ati nkan mimu ti ko ni ọti ninu, kún wọn.

Ireti wa pe owo to to aadọjọ biliọnu Naira ni ijọba yo ma a ri lori awọn nkan yii, ti ofin eto iṣuna tuntun ti Aarẹ Buhari buwọlu lọdun 2020.