Ààrẹ fí ọwọ́ òsì júwe ilé fún Mínísítà tó ń gba owó oṣù láì ṣiṣẹ́

Aworan

Oríṣun àwòrán, Ghana government/Sarah Adwoa Safo/Facebook

Aarẹ orilẹede Ghana ti fi ọwọ osi juwe ile fun minisita fun ọrọ obinrin, ọmọde ati eto aabo awujọ, Sarah Adwoa Safo ni kiakia.

Adari eto iroyin ni ileeṣẹ aarẹ, Eugene Arhin lo kede igbeṣẹ aarẹ naa ninu atẹjade.

Ninu atẹjade naa ni aarẹ ti sọ pe awọn ti yan minisita fun ọrọ gba-ilu-mọ ati ipese omi lati duro ni ipo fidiẹ titi oun yoo fi yan eniyan miran sibẹ.

Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe kii wa si ibi iṣẹ ti a si ma n fi awọn fidio igbadun rẹ si ori ayelujara.

Amọ minisita ti wọn yọ nipo naa ni ara ọmọ oun ti ko da lo fa ki ohun ma wa si ibi iṣẹ, ti oun si wa ni oke okun lati lọ sẹ aduroti ọmọ oun.

Oṣu mẹsan an ni minisita ko fi wa si ibi iṣẹ

Lara ẹsun ti wọn fi kan minisita naa ni pe osu mesan an ni ko fi wa si ibi iṣẹ fun oun to niiṣe pẹlu ara rẹ.

Ọdun to kọja ni wọn bẹrẹ si ni gbe igbeṣẹ lori aiyọju si iṣẹ rẹ, ki ijọba to gbe igbeṣẹ lori rẹ.

Wọn ni aisi ni ibi iṣẹ rẹ ko fi aye silẹ fun awọn eniyan lati ṣe iṣẹ ni ẹka naa bi o ṣe jẹ.

‘’Minisita tiktok’’

Lasiko ti wọn n sọrọ nipa aisi ni ibi iṣẹ rẹ ni minisita naa n ṣe fidio lori ẹrọ ayelujara

Ninu fidio naa ni wọn ti ri ti yoo ma kọrin ti yoo si maa jo.

Amọ eyi mu ki awọn eniyan bẹrẹ si ni sọrọ si pe ko naani iṣẹ ijọba to n ṣe.