Ọ̀nà mẹ́sàn án láti yọ ààrẹ Naijiria nìyìí...

Oríṣun àwòrán, Google
Ẹgbẹ alatako lorilẹede Naijiria ni Ile Aṣofin agba ni Naijiria ti fun aarẹ Muhammadu Buhari ni gbedeke lati satunse eto aabo to dẹnukọlẹ ni Naijiria abi ki wọn yọ ni ipo.
Ni Ọjọru ni awọn aṣofin naa ṣe bẹbẹ ni ile Asọfin lẹyin ti wọn ni dandan awọn fẹ awọn fẹ gbe awọn fẹ ‘pass motion’’ ti yoo kan an ni ipa fun aarẹ Buhari lati bojuto aabo to dẹnukọlẹ kaakiri Naijiria.
Eyi mu ki awọn aṣofin ni ẹgbẹ alatako naa parapọ jade kuro ninu Ile Aṣofin naa, ti wọn si n paruwo aarẹ Buhari gbọdọ kuro nipo aarẹ
Bakan naa ni wọn kede pe awọn ti fun aarẹ ni gbedeke ọṣẹ mẹfa lati satunṣe eto aabo tabi ki awọn yọọ ni ipo.
Amọ ṣe eyi yoo ṣeeṣe bi?
Iwadii BBC ree lori igbese ati yọ aarẹ ati bi wọn yoo ṣe gbe igbeṣẹ ọhun.
‘’Kii se asiko yii lo yẹ ki wọn ṣẹṣẹ fẹ yọ aarẹ Buhari nipo’’
Onimọ nipa eto ofin lorilẹede Naijiria, Kennedy Osunwa ti sọ bi wọn ṣe le yọ aarẹ orilẹede Naijira ni ipo.
Osunwa sọ fun BBC Pidgn pe kii ṣe asiko yii lo yẹ ki awọn aṣoffin naa ṣẹṣẹ maa sọ wi pe awọn fẹ yọ aarẹ Buhari ni ipo.
O ni ọpọlọpọ nkan lo ti ṣẹlẹ to yẹ ki wọn gbe igbeṣẹ naa amọ wọn ko ṣee.
Kennedy ni ki n ṣe igbeṣe kekere ni lati yọ aarẹ.
Bẹẹ si ni ida meta (two-third) awọn aṣofin lo gbọdọ buwọlu u.
Nkan ti ofin Naijiria sọ niyii nipa yiyọ aarẹ ni ipo
Gẹgẹ bi ẹka iwe ofin Naijiria ni ẹka Section 143 ti iwe ofin ọdun 1999 ṣe sọ, ọna lati yọ aarẹ ni ipo niyii.
Igbeṣẹ akọkọ
Igbese akọkọ ni ki wọn fi ẹsun aṣemaṣe kan aarẹ, ki ọmọ Ile Aṣofin ni Naijiria pẹlu ibuwọlu o kere tan, ida kan ninu ida mẹta awọn aṣofin agba ati kekere ti wọn yoo si gbe lọ fun Aarẹ ile igbimọ Aṣofin Agba.
- Ohun ti aṣemaṣe tunmọ si ni ihuwasi to tako alakale ofin orilẹede Naijiria.
Igbeṣẹ Keji
Lẹyin naa ni Aarẹ Ile Igbimọ Aṣofin laarin ọjọ meje yoo fi iwe ẹsun naa ranṣẹ si aarẹ ati gbogbo ọmọ Ile Aṣofin Naijiria.
Igbeṣẹ Kẹta
Igbesẹ kẹta ni ki aarẹ naa da wọn lohun lori ẹsun aṣemaṣe ti wọn fi kan an abi ki o ma daun, eleyii ti wọn yoo fi ṣọwọ si awọn aṣofin
Igbeṣẹ Kẹrin
Lẹyin ọṣẹ meji naa ni abẹnugan ile aṣofin ati awọn aṣofin yoo gbimọpọ boya iwadii awọn ẹsun naa yoo waye.
Ti yoo ba tẹsiwaju abi bẹ̀ẹ kọ ida meji ninu id mẹta awọn aṣofin lo gbọdọ buwọlu u.
Igbeṣẹ Karun un
Ti ida mẹta awọn aṣofin ko ba buwọlu u, wọn yoo dẹkun itẹsiwaju rẹ amọ ti wọn ba buwọlu u ni aarẹ ile yoo kọ lẹta si olootu eto idajọ lorilẹede Naijiria lati gbe igbimọ dide lati ṣewadii ẹsun ti wọn fi kan an, ti awọn igbimọ naa ko si ni jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu kanakan tabi aṣofin tabi ẹnikẹni to n jẹ labẹ aarẹ naa.
Igbeṣẹ Kẹfa
Lasiko iwadii naa Aarẹ orilẹede Naijiria ni anfaani ni abẹ ofin lati wa si ile aṣofin waro ti ẹnu rẹ lori ẹsun ti wọn fi kan an .
Igbesẹ Keje
Laarin osu mẹta naa ni igbimọ ti wọn ba gbe kalẹ naa yoo fi abajade iwadii wọn lede.
Lẹyin naa ni awọn aṣofin yoo buwọlu boya o jẹbi ẹsun naa tabi bẹẹkọ, eleyii ti wọn sọ boya ki wọn yọọ nipo abi ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.
Igbesẹ Kẹjọ
Ti igbimọ ba ni ẹsun naa ko see ni ẹṣẹ nilẹ, ko ni si ohunkohun ti wọn yoo ṣele lori mọ, amọ ti o ba jẹ ootọ awọn ọmọ ile aṣofin yoo dibo boya ki wọn gba awọle.
Igbesẹ Kẹsan an
Ti wọn ba buwolu u, ti ida meji ninu mẹta ba si faramọ ọ, ọjọ naa ni wọn yoo yọ aarẹ orilẹede Naijiria ni ipo












