Ọwọ́ tẹ àwọn mẹ̀rin tó jí irun, aṣo, bàtà àti aago ọwọ́ òkú

Enyobeni tavern death

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn ọkunrin mẹrin kan ti foju bale ẹjọ ni South Africa lori ẹsun pe wọn ji ẹru lara awọn oku.

Awọn oku naa lawọn ọdọ kan ti iye wọn to mọkanlelogun to jade laye nile ọti kan lagbegbe East London.

Ọjọ ori awọn afurisi naa ko ju ọdun mẹrindinlogun si mọkanlelogun lọ.

Ko si ẹnikankan ninu awọn afurasi naa to tii sọ boya oun jẹbi ẹsun naa tabi bẹẹ kọ nitori iwadi ọlọpaa ṣi n lọ lọwọ.

Ilẹeṣẹ ọlọpaa ni wọn ba lara awọn ẹru naa ti wọn ji ko ninu ile wọn.

Lara awọn ohun ti wọn ji lara awọn oku naa ni irun, bata, aṣọ ati aago ọwọ.

Bi awọn oku ti wọn ji ẹru wọn ṣe jade laye

Inu oṣu to kọja ni awọn ọdọ mọkanlelogun kan lati ilu Scenery Park, to wa ni East London ṣadede ku sinu ile ọti kan ti orukẹ rẹ n jẹ Enyobeni.

Bo tilẹ jẹ pe iwadii ohun to ṣokunfa iku wọn ṣi n lọ lọwọ, awọn oluwadii ṣawari eroja methanol ninu ẹjẹ wọn, eyii to jẹ kẹmika ti wọn fi fọ nnkan.

Ẹnikan ti iṣẹlẹ na ṣoju rẹ sọ pe awọn ọdọ naa kagbako iku ojiji lasiko ti wọn n ṣajọyọ ipari saa ẹkọ wọn lọwọ.

Ẹni to ni ile ọti naa atawọn oṣiṣẹ rẹ meji ti foju bale ẹjọ lori ẹsun pe wọn n ta ọti fun awọn ọjẹ wẹwẹ ti ọjọ ori wọn ko ti to ọdun mejidinlogun.

Iye ọjọ ori awọn to le maa mu ọti ni South Africa ni ọdun mejidinlogun.

Ile ẹjọ ti ni ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹjọ, ọdun yii ni igbẹjọ awọ afurasi ọhu yoo bẹrẹ ni pẹrẹwu.