Wo ìdí tawon agbebọn fi tu mẹta nínú arinrinajo reluwé Abuja sí Kaduna sílẹ̀
Awọn agbebon ti tu mẹta ninu awọn arinrin-ajo reluwee Abuja sí Kaduna ti won jigbe loṣu diẹ sẹyìn silẹ.
Mọlẹbi ọkan lára àwọn ntà ti wọn tú silẹ lọ ṣalaye fún BBC pe lọsan ọjọ Ìṣẹgun ni wọn tú wọn silẹ.
Ọkùnrin Méjì ati obinrin kan ni wọn tú silẹ.
Mọlẹbi miran ninu wọn pẹlu tun fìdí iroyin naa múlẹ fún BBC to sì ni ọna ileewosan lawọn wa bayii lati ṣe àyẹwò ilera èèyàn awọn ti wọn tú silẹ.
Wọn tú wọn silẹ lẹyin ti fidio kan lù sita lori ayelujara eyi to ṣafihan bi awọn agbebọn naa ṣe n yinbọn sí awọn kan lára awọn arinrinajo ti wọn ni gbé naa.
Ni bi a ṣe n sọrọ yii, kò tíì sí ẹkunrẹrẹ iroyin nipa gbedeke ti ijọba tabi awọn mọlẹbi wọn tẹlẹ ki wọn to tu wọn silẹ.
Ni ọjọ kejidinlogun, osu kẹta, ọdún 2022 lawọn agbebọn kọlu ọkọ reluwee kan to n lọ láti Abuja sí Kaduna lalẹ.
Eyi ni igba karun un ti wọn yóò ti lara awọn ti wọn ji gbe silẹ.
Pẹlu èèyàn mẹta ti wọn tú silẹ yii, O ti di ogoji bayii to ku ninu àhámọ́ awọn ajinigbe yii.

Oríṣun àwòrán, @Edrees4P
Awọn wo ni wọn tú silẹ?
Ọkunrin meji ati obinrin kan ni awọn agbebọn naa tu silẹ l’ojo Aje.
Nigba ti akoroyin BBC kan dé ilé ọkan lára wọn, O ni fọfọ ni ile rẹ kún fún àwọn èrò tó wà ki wọn ku oriire akọtọ èèyàn wọn tawon agbebọn tu silẹ naa.
Ninu Fidio kan tawon agbebọn naa fi sita l’ojo Abamẹta to kọja, to ṣafihan bi wọn ṣe n na awọn arinrinajo naa.
O ni lara awọn ti wọn tú silẹ ni Amofin Hassan Usman to wọ asọ olomi buluu ti wọn fún lanfani ati máa sọrọ ninu Fidio naa.
O ṣalaye bi wọn ṣe ji awọn gbe ati bi ijoba ṣe kùnà láti yanju itusile wọn.
Ninu fidio naa, o ké sí awọn ajọ agbaye ati orilẹ-ède agbaye bíi Amẹrika, ile Gẹẹsi ati Faranse lati dide iranwo lori igbesẹ ati tú wọn silẹ.
O ni awọn agbebon to ji awọn gbe ko figba kan níí lokan lati fi awọn pamo fún ìgbà pipẹ.

Oríṣun àwòrán, @Yuli 2022
Àwọn agbésùmọ́mí tú mẹ́ta míì sílẹ̀ nínú àwọ́n tí wọ́n jí gbé lójú ọ̀nà Abuja sí Kaduna
Awọn agbesumọmi ti jọwọ awọn mẹta mii ninu awọn eeyan ti wọn ji gbe loju ọna oju irin Abuja si Kaduna lọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹta, ọdun yii.
Awọn eeyan naa ti wọn jẹ ọkunrin meji ati obinrin kan gba itusilẹ wọn ni nnkan bii aago mọkanla aarọ ọjọ Aje.
Iroyin ni wọn tu awọn eeyan na silẹ ninu igbo kan to wa loju ọna marosẹ Abuja si Kaduna, ti awọn mọlẹbi wọn si lọ pade wọn loju ọna.
Lọwọ yii mejilelogun ninu awọn eeyan ti awọn agbesumọmi naa ji gbe ni wọn ti tu silẹ.
Amọ a ko tii le sọ boya boya awọn agbesumọmi naa gba owo itusilẹ ki wọn to tu awọn eeyan naa silẹ.
Pẹlu awọn ti wọn tu silẹ yii, ogoji ninu awọn eeyan naa lo ṣi wa ni ahamọ awọn agbesumọmi ọhun.
Bi iṣẹlẹ naa ṣe ṣẹ
Ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2022 yii ni awọn agbesumọmi naa ji awọn eeyan ọhun gbe lẹyin ti wọn ju ado oloro si ọkọ oju irin ti wọn wọ, nibi ti wọn ti pa awọn eeyan kan, ti wọn si ji ọpọ awọn mii gbe.
Lọjọ Aiku to kọja yii ni awọn agbesumọmi naa ṣafihan fidio kan lori ayelujara nibi ti wọn ti n na awọn eeyan naa to wa lakata wọn.
Ninu fidio ọhun ni wọn tun ti dunkoko pe awọn yoo ji Aarẹ Muhammadu Buhari ati gomina ipinlẹ Kaduna, Nasir El-Rufia gbe.
Amọ ijọba aapọ ti fesi pe awọn abesumọ naa n mọọmọ tabuku oun pẹlu awọn ohun ti wọn ṣe naa ni.
Ẹwẹ, lẹyin ti fidio naa fa ori ayelujara ya lawọn mọlẹbi awọn eeyan naa ṣe ifẹhonuhan niluu Abuja, eyii ti wọn fi ke si ijọba apapọ pe ko doola awọn ẹbi wọn naa to wa lahamọ.












