Seyi Makinde gba olùkọ́ 129, tí Ajimobi lé lẹ́nu iṣẹ́ padà

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Facebook

Gomina ipinlẹ Oyo, Onimọ-ẹrọ Seyi Makinde ti pasẹ pe ki wọn gba awọn olukọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ mọkandinlaadoje ti ijọba Abiola Ajimobi le kuro lẹnu isẹ pada.

Atẹjade kan ti ileesẹ to n risi ipese ẹkọ ọfẹ kariaye, SUBEB nipinlẹ Oyo, fisita lọjọbọ, lo sisọ loju ọrọ yii.

Nigba to n ki awọn olukọ naa ku oriire, alaga ajọ Subeb nipinlẹ Oyo, Ọmọwe Nureni Adeniran ni laarin ọdun 2011 si 2019 ni wọn yọ awọn olukọ naa lẹnu isẹ.

Amọ o yan pe ijọba Seyi Makinde gba lati da awn osisẹ naa pada sẹnu isẹ wọn pẹlu adehun pe awọn ko ni beere fun ajẹsilẹ owo osu to yẹ ki wọn gba lasiko ti wn fi wa nile.

Adeniran wa mọ riri Gomina Makinde fun oju aanu ati aisi iwa anikanjọpọn to fi n se akoso ipinlẹ Oyo.

 “Afikun nla ni igbesẹ yii jẹ fun ẹka eto ẹkọ, awọn olukọ yii si ni yoo kun awọn olukọ perete to ku nile ẹkọ alakọbẹrẹ.

Bakan naa ni irọrun yoo de ba ọpọ eeyan tawọn olukọ ti wọn gba pada sẹnu isẹ naa n gbọ bukata wọn tẹlẹ.

Awọn eeyan yii si lo ti la isoro ọrọ aje to buru jai kọja nitori bi wọn se gba isẹ lẹnu awọn olukọ naa.”

Alaga ajọ Subeb naa wa gba awọn olukọ ti wọn gba pada sẹnu isẹ yii nimọran lati mọ riri ọwọ oore gomina Makinde, nipa jijara mọ isẹ, ki wn si mu isẹ wọn lọkunkundun.

Iléesẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun kìlọ̀ fáwọn jàndùkú láti jìnà réré sí ìwọ́de NLC àti ASUU tí yóò bẹ́rẹ́ lónìí

Nigeria Police

Oríṣun àwòrán, @TheTrentOnline

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti kilọ fun awọn janduku lati maṣẹ yọju sibi iwọde ti ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ, NLC, yoo ṣe lonii ki wọn ma baa foju wina ofin.

Ifẹhonuhan naa ni NLC gbe kalẹ lati ṣatilẹyin fun awọn olukọ fasiti, ASUU, lori iyanṣẹlodi wọn to ti wọ oṣu marun un bayii.

NLC tun gbe iwọde naa kalẹ lati ke si ijọba apapọ pe ko wa wọrọkọ fi ṣ’ada lori awọn ohun ti ASUU n bere fun.

Oni ọjọ kẹrindinlọgbọn, ati ọla ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Keje, ọdun 2022 yii ni iwọde naa yoo waye lawọn ilu nla ni Naijiria.

Ninu atẹjade kan ti alukoro ileeṣe ọlọpaa Ogun, Abimbola Oyeyemi, fi ṣọwọ si awọn akọroyin, o ni bo tilẹ jẹ ẹtọ awọn oṣiṣẹ naa labẹ ofin ni lati fẹhonuhan, wọn gbọdọ ṣe ifẹhonuhan naa lọna to ba ofin mu.

Ileeṣẹ ọlọpaa tun fi ọkan awọn araalu balẹ ko ni si rogbodiyan kankan ṣaaju, lasiko ati lẹyin ifẹhonuhan naa.

Kele yoo gbe ọmọkọmọ to ba da ilu ru

Oyeyemi ni awọn ko ni gba awọn janduku kankan laaye lati wọ aarin awọn oluwọde naa tabi lo iwọde ọhun lọna ati da alaafia ipinlẹ Ogun ru.

O ni “Bo tilẹ jẹ pe ẹtọ araalu ni lati ṣewọde, ileeṣẹ ọlọpaa fẹ rọ NLC atawọn ẹgbẹ mii to fẹ kopa ninu iwọde ọhun lati ṣe ni ọna to ba ofin mu ki wọn ma baa tẹ ẹtọ awọn araalu mii mọlẹ.”

“A tun fẹ rọ awọn araalu pe ki wọn maa ba iṣẹ wọn lọ lasiko iwọde naa lai si ibẹru kankan tabi idunkoo kankan nitori awọn ọlọpaa atawọn agbofinro mii yoo wa ni ikalẹ lati dẹkun awọn janbduku ti yoo fẹ rapala wọ aarin awọn oluwọde ọhun.”

Lẹyin naa lo rọ awọn obi ati alagbatọ lati kilọ fun awọn ọmọ wọn ti yoo fẹ lo anfani iwọde naa lati da rugudu silẹ ki wọn fa awọn ọmọ wọn leti, nitori kele yoo gbe ọmọkọmọ ti ọwọ ba tẹ pe o da ilu ru.