Obìnrin tó ń pín fídíò ìbálòpọ̀ lórí ayélujára ní Saudi Arabia wọ gàù

Tala Safwan

Oríṣun àwòrán, Tala Safwan

Obinrin kan tii se ọmọ orilẹede Egypt, to n lo oju opo Tik-Tok lọwọ ijọba Saudi Arabia ti tẹ lori ẹsun pe o n pin awọn fidio ti ko wu oju ri.

 Tala Safwan lo ni eeyan miliọnu marun to n ba dọrẹ pọ loju opo naa, to si ni ọrẹ ẹgbẹrin loju opo YouTube rẹ.

 Ohun to se mu ki oju gbogbo eeyan wa lara rẹ ni bo se gbe fidio kan soju opo naa nibi to ti lo ọrọ nipa akọ to n ba akọ se.

 Amọ omidan Safwan ni oun ko se eleyi pẹlu erongba buburu amọ awọn ọlọpaa Saudi Arabia ni fidio naa le se aburu fun awn eeyan miran, ko si maa tan iwa aitọ kiri.

 Irun Tala to lọ si lo maa n fa oju ọpọ eeyan mọra, ti ori ayelujara si maa n gbona lala pẹlu awọn fidio to n lo maa n lo.

Nibẹ naa si lo ti maa n bawọn ololufẹ rẹ sọrọ lori awọn ọrọ to jẹ mọ ifẹ atawọn nnkan miran ti ko tọna lati gbọ.

 Bakan naa lo maa n bawọn alatilẹyin rẹ da apara mọ lọpọ igba ni awn fidio to ba ju sori ayejujara maa n ni itumọ miran.

Eyi si lo mu ki ipolongo gba oju opo Twitter kan nipa ihuwasi rẹ naa, eyi ti wọn lo n bi awọn ninu.

Sugbọn Tala ni awọn eeyan si oun gbọ ni, to si sẹ pe oun ko sọrọ nipa akọ to n fẹ akọ, tii se ẹsẹ nla si ofin orilẹede Saudi Arabia.

O ni wọn ti tọwọ pọ ẹkunrẹrẹ fidio ti oun gbe soju opo ayelujara oun, lati sọ oun ni suna buruku.

Ami idamọ Tik-tok

Bi eruku se wa n sọ lala lori ọrọ yii lori ayelujara, awọn ọlọpa ilu Riyadh ti kede pe ọwọ sinkun awọn ti ba obinrin kan to foju han ninu fidio naa.

 Obirin ọhun ni wọn lo n ba obinrin miran sọrọ ninu fidio yii, eyi to le ba ihuwasi obinrin naa jẹ, ko si tun se akoba fun ọkan araalu pẹlu.