Fayose dèrò ilé ìwòsàn, ó ṣiṣẹ́ abẹ méjì láàrín oṣu márùn ún

Fayose Hospitalized

Oríṣun àwòrán, Linda Ikeji

Gomina ipinlẹ Ekiti nigba kan ri, Ayodele Fayose ti dero ile iwosan bayii lẹyin to ṣiṣẹ abẹ.

Iroyin ni ẹyin Fayose ni wọn ti ṣiṣẹ abẹ naa ti o ṣẹṣẹ ṣe.

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, igbakeji ree ri Fayose yoo ṣe isẹ abẹ laarin oṣu marun un sira wọn.

Bo tilẹ jẹ pe a ko le sọ ile iwosan ti isẹ abẹ naa ti waye, agbẹnusọ Fayose, Lere Olayinka ni iṣẹ abẹ naa waye nitori bo ṣe farapa lẹyin ikọlu ti awọn kan ṣe si lasiko eto idibo ọdun 2018.

 Ninu fido kan to fa ori ayelujara ya lẹyin ikọlu naa lọdun naa lọhun, ni Fayeṣe ti ke gbajare pe oun wa ninu irora ti ko ṣe fẹnusọ, amọ ọpọ eeyan lo ṣe yẹyẹ lẹyin ti wọn ri fidio naa tan.

Gẹgẹ bii ohun ti Lere Olayinka sọ, inu oṣu keji ọdun yii ni iṣẹ abẹ akọkọ waye, nigba ti wọn ṣe iṣẹ abẹ keji bayii.

O ni “Iṣẹ abẹ meji laarin oṣu marun un sira wọn, iṣẹ abẹ akọkọ ni wọn ṣe ni ọrun rẹ loṣu keji, nigba ti wọn ṣiṣẹ abẹ miran bayii ni ẹyin rẹ.”

“Iṣẹ abẹ yii ko ṣẹyin ikọlu ti wọn ṣe si lasiko eto idibo gomina to waye lọdun 2018.”

Lẹyin naa lo ki Fayosem, to si gbadura pe ki Ọlọrun fun ni alaafia ni kankan.

Ayodele Fayose ni gomina ipinlẹ Ekiti laarin ọdun 2003 si 2006 ati ọdun 2014 si 2018.