Wọ́n ti yọ Portable bíi jìgá kúrò nínú àwọn tí yóò gba àmì ẹ̀yẹ ‘Headies’ nítorí wòtòwótò

Oríṣun àwòrán, portablebaeby
Awọn to n ṣagbatẹru ami ẹyẹ Headies, ti yọ orukọ Habeeb Okikiola, ti ọpọ mọ si Portbale kuro lara awọn ti yoo lanfaani lati gba ami ẹyẹ naa lọdun yii.
Ninu atẹjade kan loju opo Instagram ni ileeṣẹ Smooth Promotions Limited, to n ṣagbatẹru eto ami ẹyẹ naa ti fi ikede ọhun sita.
Atẹjade naa ni “A kabamọ lati kede pe lẹyin awọn ọrọ kobakungbe ti ọgbẹni Okikiola, ti ọpọ mọ si Portable n sọ, eyii to mu ki ilẹeṣẹ ọlọpaa Naijiria atawọn araalu maa sọrọ nipa rẹ, a ti pinnu lati yọ Portable kuro lara awọn ti a fẹ fun ni ami ẹyẹ.”
Awọn aṣemaṣe Portable
“Igbesẹ wa lati fofin de ọgbẹni Okikiola ko ṣẹyin awọn iwa kobakungbe kan to n wu lori ikanni ibanidọrẹ lori ayelujara.”
“Lojọ karundinlọgbọ, oṣu Karun un, o dunkoko pe oun yoo pa, ati pe oun yoo ṣe ijamba fun awọn miran ti a fa kalẹ fun ami ẹyẹ naa ti kii ba ṣe oun lo gba ami ẹyẹ ọhun.”
Atẹjade naa tẹsiwaju pe “Lọjọ kejidinlogun, oṣu Keje, ọdun 2022, ọgbẹni Okikiola sọ ninu fidio kan pe oun ni oun da ẹgbẹ okunkun ‘One million boys’to n da ilu ru silẹ.”

Oríṣun àwòrán, @the_headies
“Ko tan sibẹ, lọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2022, ọgbẹni Habeeb Okikiola tun ya ara rẹ ninu fidio kan, nibi to ti paṣẹ fun awọn ọrẹ rẹ lati lu ọrẹ rẹ mii to fẹsun aṣemaṣe kan, iyẹn DJ Chicken, bii bara.”
Lara ami ẹyẹ ti Headies fa Portable kalẹ fun tẹlẹ ni olorin to ta lẹnu julọ larin adugbo ati olorin to ṣẹṣẹ n bọ loke amọ ti irawọ rẹ ti tan.
Iwọnba eeyan perete lo mọ Portable tẹlẹ, amọ irawọ rẹ buyọ lẹyin awo orin ‘Zazoo Zehh’ ti oun ati Olamide ati Pocolee gbe jade.












