Ẹ gbọdọ̀ mú PVC yín wá tí ẹ bá n padà bọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ – Ìjọba Eko kéde ìsinmi ọjọ́ mẹ́rin

Oríṣun àwòrán, Google
Ijọba ipinlẹ Eko ti kede isinmi ọjọ mẹrin fun awọn oṣiṣẹ nipinlẹ Eko fun awọn oṣiṣẹ lati lọ gba kaadi idibo wọn.
Ajọ eleto idibo lorilẹede Naijiria, INEC ti kede Ọjọ kọkanlelọgbọn gẹgẹ bi gbedeke fun awọn eniyan lati gba PVC wọn.
Olori awọn oṣiṣẹ nipinlẹ Eko, Hakeem Muri-Okunola lo kede rẹ ninu atẹjade.
Muri-Okunola ni ọjọ mẹrin aisi iṣẹ naa yoo bẹrẹ ni Ọjọ Kẹrindinlọgbọn, OsuKeje, ti yoo si pari ni Ọjọ Kọkandinlọgbọn, Osu Keje, ọdun 2022, ki gbedeke ajọ INEC to de.
Ijọba ni o pọn dandan ki awọn oṣiṣẹ kopa ninu idibo gbogboogbo to n bọ ni ọdun 2023 nitori ẹtọ wọn gẹgẹ bi ọmọ Naijiria.
Bakan naa ni wọn fikun un pe o pọn dandan fun awọn oṣiṣẹ naa lati mu PVC wọn dani ti wọn ba n bọ pada si ẹnu iṣẹ ni Ọjọ Ajẹ.
Iwadii fihan pe o kere tan eniyan miliọnu meje ni wọn ti fi orukọ wọn silẹ fun gbigba kaadi idibo wọn.
Ijọba ipinlẹ Ogun kede isinmi lẹnu iṣẹ lati gba PVC

Oríṣun àwòrán, Google
Bakan naa ni gomina ipinlẹ Ogun ti kede Ọjọ Iṣẹgun gẹgẹ bi ọjọ isinmi fun awọn oṣiṣẹ lati lọ gba kaadi idibo PVC wọn.
Gomina Abiodun naa ni ko si iṣẹ ni ọjọ kan soso naa.
O ni ki awọn ọdọ to ba ti pegede ati awọn agbalagba lati lọ gba kaadi idibo wọn nitori ko ṣee fi ẹnu sọ ipa ti idibo n ko ni igbe aye awọn araalu.
Gomina ipinlẹ Ogun naa parọwa si wọn lati lo ọjọ isinmi ki wọn lọ si ijọba ibilẹ wọn lati lọ gba PVC wọn nitori o ṣe pataki, o ṣe koko.












