Wo bí ayédèrú fídíò ìbálòpọ̀ rẹ̀ ṣe le è fọ́n kárí ayé látọ́dọ̀ àwọn ọrẹ́ tímọ́ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lasiko yii ti aye di aye kọmputa, ti aye ti lu jara wọn, o ti rọrun bayi lati gbe ori Ojo si ọrun Aina.
Ohun ti Ojo ko ṣe ri laye rẹ, yoo si di ọran ti ko le bọ ninu rẹ, bi ko ba ṣọra.
Ọpọlọpọ ọna lawọn eeyan to sunmọ ni julọ lori ayelujara si le gba wọle si wa lara, bi wọn ko ba ni ibẹru Ọlọrun lọkan.
Yoruba bọ̀, wọn ni bi iku ile ko ba pa ni, ti ode ko le pa ni nitori ẹyinkule ni ọta wa, inu ile ni awọn aseni n gbe.
Yatọ si jibiti lilu, to ti di tọ́rọ́ fọ́n kálé lori ayelujara, asa gbigbe fidio ibalopọ ẹlomii jade, koda bi ki i ba ṣe ẹni naa ni wọn n ba lo pọ nitootọ, tun n ṣẹlẹ pẹlu.
Ọmọbinrin kan, Jodie, (ki i ṣe orukọ rẹ gan-an), ṣalaye idaamu ọkan, ti ọrẹ rẹ timọtimọ ko ba a.
Ọ̀rẹ́ naa lo gbe ori Jodie sọrun obinrin miran, to ẹni to n ni ibalopọ pẹlu ọpọlọpọ ọkunrin.

Oríṣun àwòrán, Getty image
"Ohun ti wọn n pe ni Deepfake lo ṣẹlẹ si mi, bí wọ́n se gbe fọto ati fidio ibalopọ to fi oju mi han sori ayelujara"
Ikilọ: Awọn ọrọ to jọ mọ ibalopọ wa ninu alaye yii, ati ti ifipabanilopọ.
Jodie salaye fun BBC pe,
"Ni 2021 ni ẹnikan fi atẹjiṣẹ ori ayelujara (email) ranṣẹ si mi, nigba ti mo ṣi i, mo ri fidio to wa nibẹ.
Si iyalẹnu mi, fidio ibi ti mo ti n ba ọriṣiiriṣii ọkunrin ṣere ifẹ lo wa nibẹ, ohun ti n ko ṣe!.
"Wọn ti gbe ori mi sọrun obinrin to n ni ibalopọ pẹlu ọkunrin oriṣiiriṣii, fọto ibalopọ to n ṣafihan mi naa wa nibẹ pẹlu.
"Ohun ti awọn oyinbo n pe ni Deepfake lo ṣẹlẹ si mi. "

"Mo bẹrẹ si sunkun kikoro, mo n gbera dalẹ bi mo ṣe ri ohun to n jade lorii foonu mi"
Ẹnikan lo kọkọ gbe oju Jodie sori opo ti wọ́n ki i ṣafihan nnkan mi-in ju ibalopọ lọ.
O si kọ ọrọ sibẹ pe Jodie n jẹ ki ara oun maa gbe fukẹ.
Ẹni naa waa n beere pe, ṣe awọn yoku loju opo naa le lo aworan rẹ fun ibalopọ, ki wọn si pin kari ayelujara.
Jodie to le diẹ logun ọdun sọ pe, "Mo bẹrẹ si i sunkun kikoro, mo n gbera dalẹ bi mo ṣe ri ohun to n jade lorii foonu mi.
"Mo mọ pe ohun to le ba aye mi jẹ pata lo n ṣẹlẹ si mi, o si da bii pe gbogbo nnkan ti tan fun mi"
Bi wọn ṣe n gbe fidio ibalopọ naa jade ko tan sibẹ, o tilẹ tun gba atẹjiṣẹ ti ọkunrin kan ti n sọ fun un pe, ṣe ko ni i jẹ kawọn pade ni.
Ìṣẹ̀lẹ̀ yii waye ni ọdun 2019.
Jodie sọ pe ọkunrin naa ṣapejuwe oun deledele, o si sọ pe awọn ti n sọrọ loju opo tẹlẹ, ki Jodie maṣe se bii pe oun ko mọ oun mọ.
Awọn orukọ ti wọn kọ soju opo lati sapejuwe Jodie naa ni : Aṣẹwo, oloṣo, iyalaaya oniṣekuṣe ati bẹẹ bẹẹ lọ
Ninu oṣu karun-un ọdun 2020, lasiko igbele Korona ni UK, ọrẹ Jodie kan pe e si akiyesi ìṣẹ̀lẹ̀ naa.
Ọrẹ naa sọ fun un pe awọn eeyan kan n pin fọto rẹ loju opo Twitter, wọn si n kọ ọ sibẹ pe oloṣo ni.
Wọn n kede sibẹ pe, ẹni to ba fẹẹ ba a ṣere ifẹ, ko tete kan si i.
Ẹnikan kọ ọ sibẹ pe, "Ki lohun to wu ọ lati ba Jodie ọmọge ṣe? Aworan Jodie to wọ aṣọ iwẹ (bikini) lo fi si fọto naa.
Awọn orukọ ti wọn kọ soju opo to n kede Jodie naa ni : Aṣẹwo, oloṣo, iyalaaya oniṣekuṣe ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Awọn fọto ti Jodie ya pẹlu ẹrin-ẹyẹ lẹnu, to gbe soju opo ayelujara pẹlu awọn ẹbi rẹ lawọn to n daamu rẹ yi pada, ti wọn fi n sọ ọ lorukọ buruku.
" O pada ye mi pe fọto awọn obinrin mi-in ti mo mọ ni yuifasiti, naa wa lara awọn ti wọn n gbe jade yii.
" Mo ri i pe awọn eeyan mi lati Cambridge naa wa nibẹ.
" Ẹsẹkẹsẹ ni mo mọ pe emi gan-an ni wọn fẹ ba laye jẹ, ẹni to n gbe ihoho mi jade naa mọ-ọn-mọ n fiya jẹ mi ni.
Iwadii bẹrẹ lati mọ ẹni to wa nidii fidio ibalopọ Jodie
Jodie ṣalaye fun BBC pe oun bẹrẹ si i ba awọn obinrin mi-in toun n ri ninu awọn aworan naa sọrọ.
O loun n kilọ fun wọn pe ki wọn ṣọra, ko ma jẹ pe awọn ni yoo tun kan.
Oun ati ọrẹ rẹ kan, Daisy, bẹrẹ si i tọpinpin awọn oju opo ayelujara, wọn si ri i pe wọn pọ ti wọn n pin fidio ihoho naa.
" Ba a ṣe wadii to, bẹe lo n ye wa si i pe wọn ti pin awọn aworan naa jinna gan-an.
" Ninu iwadii wa lati mọ pe ẹni to ba sun mọ eeyan pẹkipẹki loju opo lo le ri nnkan naa ṣe.
" Abi ko jẹ ẹni kan tinu ṣaa n bi si oluwa rẹ lo n huwa ika"
Awọn ọrẹ meji yii pa ero pọ, wọn ni ọrẹkunrin Jodie tẹlẹ ni yoo wa nidii ibajẹ naa, Jodie si pada lẹyin rẹ loju opo ayelujara gbogbo.
Ṣugbọn ogun to n ja a ko tori ẹ ṣẹ o.
‘Ọrẹ ti mi o rokan lo wa nidii iwa buruku naa’

Jodie sọ pe ọmọkunrin kan wa toun fẹran pupọ, ọrẹ oun timọtimọ ni. Orukọ rẹ ni Alex Woolf.
" Nigba ta a n kọ orukọ awọn eeyan ta a ro pe o le wa nidii iwa naa, a o kọrukọ Alex Woolf si i, nitori mo finu tan an patapata.
" Lati kekere lati jọ n ṣọrẹ, a jọ nifẹẹ orin kikọ ni.
" Nigba ti mo wa ninu iṣoro yii, mo sunkun tọ Alex lọ, o si ba mi daro pupọ, o ki mi gan-an.
" Mo ro pe ajafẹtọọ obinrin ni paapaa, pẹlu bo ṣe gba mi tọwọ-tẹsẹ lasiko wahala naa.
" Aṣe Alex Woolf lo mu fọto ta a jọ ya ni Cambridge College lọ fawọn ti yoo maa pin in ka.
" Fọto ti ẹnikankan ko ni lọwọ ju Alex lọ.
Oun naa lo tun n pin awọn fọto mi yooku fun wọn ki wọn le maa fi ṣe " Deepfake! "
" O mọ ipa ti iwa naa ni lori aye mi, o si tun hu u fun mi.
" O ba mi lọkan jẹ pupọ. "
‘Wọ́n ju amòòkùnṣìkà sẹ́wọ̀n’

Alex Woolf, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn, gbadajọ ẹwọn ogun ọsẹ loṣu kẹjọ ọdun 2021.
Ileẹjọ sọ pe ihoho obinrin mẹẹẹdogun, eyi ti Jodie wa ninu wọn lo ti fi han lori ayelujara.
Wọn da a duro nibi iṣẹ orin to n ṣe fọdun meji, wọn si paṣẹ pe ko san ọgọrun-un pọn-un (£100), owo gba-ma -binu fawọn obinrin to tẹ ẹtọ wọn loju mọlẹ.
Iwa ọdaran ni lati fi ihoho ẹlomi-in han lori irọ abi otitọ, oṣu kẹwaa ọdun 2023 ni wọn sọ ọ dofin lati le dabobo etọ awọn eeyan lori ayelujara.
Ṣugbọn ọpọlọpọ aworan bẹẹ lo wa lori ayelujara, awọn mi-in si ṣẹṣẹ n wọbẹ ni pẹlu.
Ohun to ṣẹ koko fun gbogbo eniyan ni lati ṣọra.
Ki kaluku kiyẹsara loju opo intanẹẹti, ibi ẹlẹgẹ ni!










