N kò jẹ gbèsè lára N250bn, ìbanilórúkọjẹ́ lásán ni - Góminà Sokoto

Aworan Gomina ipinlẹ Sokoto

Oríṣun àwòrán, Office of the Press Secretary, Government House Sokoto

Gomina ipinlẹ Sokoto ti koro oju si iroyin to jade lati ileeṣe to n mojuto ọrọ gbesẹ ni Naijiria eyi to ni ijọba rẹ wa lara awọn Gomina to ya obitibiti owo lẹnu igba ti wọn de ori oye.

Alhaji Ahmed Aliyu sọ pe ko si ootọ ninu ọrọ pe oun ya biliọnu mọkandinlaadọrin labẹle ati nkan bi miliọnu mẹtadinlogoji dọla lati ilẹ okere.

O ni iro pata ni iroyin yi ti ko si lẹsẹ nilẹ.

O wa kesi gbogbo awọn to loun jẹ gbesẹ lati wa sita wa sọ ibi toun ti yawo.

‘’Bo ba ṣe pe wọn gbe igbesẹ yi lati bamilorukọjẹ,ko le ṣiṣẹ tori pe lati igba ti mo ti de ori aleefa ni mo ti n san owo oṣu deede’’

Gomina naa sọ pe eyi ko tunmọ si pe oun ko ni ya owo lọjọ iwaju amọ lọwọ bayii, oun ko ya owo kankan bẹẹ si ni oun ko jẹ agbaṣẹ ṣe kankan lowo.

Ahmed Aliyu sọ fun BBC oe oun yoo gbe igbesẹ lori iroyin naa ti wọn fẹ fi ba oun lorukọ jẹ.

‘’Dede owo to ba wọle sakoto wa laa n lo lati pese awọn nkan taa nilo’’

Ta wa lo jẹ gbese lorukọ ipinlẹ Sokoto?

A o ti ri aridaju idahun si ibeere yi am ohun taa m ni pe lọṣẹ to kọja ni ileeṣẹ to n mojuto ọrọ gbese ni Naijiria gbe abajade kan sita eleyi to ṣe atupalẹ iye owo tawọn Gomina jẹ laarin oṣu mẹfa to kọja.

Ninu rẹ, wọn ni awọn Gomina mẹtala to ṣẹṣẹ bẹrẹ ijọba ya biliọnu okoolenigba ati mẹfa Naira lọdọ awọn ayanilowo labẹle ati lẹyin odi.

Lara awọn Gomina ti wọn darukọ la ti ri Gomina ipinlẹ Kano,Zamfara,Katsina ati Sokoto.

Yatọ si Gomina ipinlẹ Sokoto to ke gbajare pe oun ko yawo kankan, awọn Gomina to ku ko yi ti jade sita tako iroyin yi.

Iye ti iroyin yi sọ pe Gomina ipinlẹ Sokoto ya si jẹ miliọnu marundinlaadoje dọla le diẹ lati ilẹ okere.

Iṣiro paṣiparọ Naira si dọla ti ajọ DMO fi ṣiro owo gbese yi si jẹ dọla kan si 889 owo Naira.

Aworan orukọ awọn ipinlẹ to jẹ gbese ati iye ti onikaluku jẹ

Oríṣun àwòrán, DMO

Àkọlé fídíò, Owobo Ogunde: Mo ṣì ń rí bàbá mi Ogunde lójú àlá, ohun tó sọ fún mi ni máà ṣe páta

Gómìnà mẹ́tàlá jẹ gbèsè N250bn láàrin oṣù mẹ́fà lórí àlééfà

Awọn gomina ati aarẹ́ Tinubu

Oríṣun àwòrán, @BATOfficial

Ileeṣ ijọba to mojuto ọrọ gbese, Debt Mangement office, DMO, sọ pe awọn ipinlẹ mẹtala kan ni Naijiria ti yawo to to ojilenigba ati mẹwa biliọnu Naira.

Wọn ya owo yi lọwọ awọn ayanilowo nile ati lẹyin odi.

Ninu awọn ipinlẹ to ya ninu owo yi gẹgẹ bi ileeṣẹ naa ṣe salaye ni ipinlẹ Katsina, Zamfara, Plateau, Niger, Benue, Cross River ati olu ilu Naijiria ,Abuja.

Laarin oṣu mẹfa,iyẹn ọgbọnjọ oṣu Kẹfa si ọgbọnjọ ọsu Kejila ti wọn gun ori alefa ni wọn ya awọn owo yi gẹgẹ bi DMO ti ṣe kede loju opo wọn.

borrowed 226 billion naira from lenders inside and outside the country.

Atẹjade yi ṣalaye pe awọn Gomina mẹrinla mii tun mu alekun ba iye gbese ipinlẹ wọn pẹlu owo to sunmọ N509.3bn.

Ninu rẹ la ti ri gbese ilẹ okere N243.95bn ti eleyi ti wọn ya labẹle si jẹ N265.37bn.

Iṣiro paṣiparọ owo Naira N889 si dọla kan ni ileeṣe yi fi ṣe iṣiro gbese naa.

Atupalẹ gbese ti wọn jẹ...

Awọn ipinlẹ yi to fi mọ Benue, Cross Rivers, Katsina, Niger, Plateau, Rivers, Zamfara, ati FCT ya owo N115.57 lọwọ awọn ayinilowo labẹle nigba ti awọn Gomina ipinlẹ Ebonyi, Kaduna, Kano, Niger, Plateau, Sokoto, Taraba ati Zamfara ya N111.24bn lọdọ awọn ayanilowo ilẹ okere eyi to ṣe deede $125.1m.

Gomina Kano ninu awọn to ya owo nilẹ okere ya biliọnu mẹfa le dọla 6.6 biliọnu lọwọ banki agbaye World Bank ati IMF ti akọsilẹ siwa wi pe Gomina Niger naa ya owo 1.27 miliọnu nilẹ okere bakan naa.

Gomina ipinlẹ Cross Rivers Bassey Otu lo ya owo to pọju lọ iyẹn N16.2bn labẹle to si ya $57.95m lọwọ awọn ayanilowo ilẹ okere laarin oṣu Kẹfa si oṣu Kejila ọdun 2023.

Katsina tẹle pẹlu gbese N99.3bn.

Gbese to jẹ tẹlẹ jẹ N62.37bn amọ o fo lọ soke pẹlu N36.93bn ninu oṣu Kejila ọdun 2023.

Ki ni eyi tumọ si fawọn ipinlẹ to jẹ gbese yii?

Dokita Aminu Achida to jẹ onimọ nipa ọrọ aje ni fasiti Usman Dan Fodiyo sọ pe apẹre ohun to n ṣelẹ yi n tọka si pe awọn Gomina ko ni ri owo lati fi san owo oṣu tori gbese pupọ.

O ni amọran ohun fawọn ijọba ni ki wọn ṣe ohun to yẹ lasiko yi.

Ni ọdun 2023, awọn Gomina ipinlẹ gba obitibiti owo ju tatẹyinwa lọ lẹyin igba ti ijọba apapọ yọ ẹdinwo owo bẹntiroo taa mọ si subsidy.

Atupalẹ owo yi fihan pe awọn Gomina gba to N627bn loṣu Kẹsan ninu owo ti ijọba pin ninu apapwọle orileede Naijiria.

Ni oṣu Kejila won gba to N610bn.

Ni oṣu Kẹjọ wọn gba to N555bn.