Ìjọba Nàìjíríà, ẹ yé jẹ gbèsè kún gbèsè mọ́ -DMO

Aworan Tinubu ati iye gbese NAijiria bayii

Oríṣun àwòrán, Bola Tinubu/budgit/twitter

Ajọ to n ri si amojuto gbese ọrun orilẹede Naijiria, DMO ti ke si ijọba apapọ orilẹede Naijiria pe ko dẹkun yiya owo kun owo to ti ya tẹlẹ.

Ileeṣẹ naa ṣalaye pe ida mẹtalelogun owo ti Naijiria n pa ni ọdun 2023 ni yoo fi san gbese.

Ileeṣẹ to n mojuto gbese ọrun Naijiria naa ṣalaye fun ileeṣẹ akoroyinjọ Reuters pe o ṣeeṣe ki gbese ọrun orilẹede Naijiria de gongo ida mẹtadinlogoji oṣuwọn igbe aye awọn eeyan rẹ (GDP) lati ida mẹtalelogun to wa lọdun to kọja.

Ileeṣẹ naa woye pe iye alekun gbese ti Naijiria tun jẹ lati ilẹ okeere atawọn ti wọn gba lọwọ banki apapọ Naijiria lo mu wọn woye pe o ṣeeṣe ki gbese tun pọ si lọdun yii.

Ni oṣu karun ọdun 2023 nikan,nigba to ku ọgbọn ọjọ ki ijọba Buhari fi ipo silẹ, ile igbimọ aṣofin apapọ Naijiria buwọlu yiya owo to din diẹ ni tiriliọnu naira (aadọta dọla) latọwọ banki apapọ.

Aworan gbese NAijiria lati ọdun 2015 si 2022

Oríṣun àwòrán, budgit

Ohun ti ijọba ana sọ nigba naa ni pe awọn fẹ fi kun eto iṣuna naijiria ati lati ṣe awọn akanṣe iṣẹ kan kaakiri orilẹede Naijiria.

Nibayii, apapọ gbese to wa lọrun Naijiria bayii titi de oṣu kejila ọdun 2023 jẹ biliọnu mẹtalelọgọrun dọla eyi to ja si tiriliọnu mẹrindinlaadọta naira, (N46 trillion).

Wahala gbese sisan kun ara olori iṣoro ijọba Aarẹ Tinubu titi kan eto ọrọ aje to n fa bi igbin ọwọngogo ohun gbogbo ti ọpọ si n reti awọn ayipada ti wọn mu nnkan padabọsipo.