Ààrẹ Tinubu kò buwọ́lu àfikún owó oṣù kankan – Iléeṣẹ́ ààrẹ Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, asiwaju bola ahmed tinubu/twitter
Ileeṣẹ aarẹ orilẹede Naijiria ni Aarẹ Bọla Tinubu ko tii buwọlu afikun yoowu lori owo oṣu awọn to dipo oṣelu mu atawọn oṣiṣẹ ẹka iṣedajọ gẹgẹ bi awọn kan ṣe n gbe e kaa kiri.
Lọjọru ni iroyin bu sita pe ajọ to n mojuto owo oṣu, RMAFC ti bu ida mẹrinlelaadọfa kun owo oṣu aarẹ, igbakeji aarẹ, awọn to dipo oṣelu mu atawọn oṣiṣẹ ẹka iṣedajọ.
Ninu atẹjade kan ti olubadamọran fun aarẹ Tinubu lori ọrọ akanṣe iṣẹ ati ibanisọrọ, Dele Alake fi sita lọjọbọ, o ni aarẹ ko tii buwọlu afikun ti wọn n sọ naa ati pe aba naa ko tilẹ tii de iwaju aarẹ debi pe yoo tilẹ buwọlu rara.
“Bi o tilẹ jẹ wi pe a mọ pe ajọ to n ri si owo oṣu, RMAFC laṣẹ labẹ ofin lati ṣeto owo oṣu ati ajẹmọnu fun awọn to ba di ipo oṣelu mu atawọn adajọ, sibẹ ko si bi irufẹ aba ti wọn ba gbe sita ṣe le e fidi mulẹ lai jẹ wi pe aarẹ bu ọwọ lu u.”
O ni alukoro ajọ RMAFC ti jade sita sọrọ pe irọ to jina si ootọ lọrọ yii.
Ìdí rèé tí a fi ń gbèrò àfikún 114% sí owó oṣù ààrẹ àti àwọn tó di ipò òṣèlú mú - RMAFC

Oríṣun àwòrán, Officialbat/Twitter
Àjọ to n mojuto owo oṣù àwọn to di ipo oṣelu mú, Revenue Mobilisation, Allocation and Fiscal Commission (RMAFC), ti sọ pe irọ ni iroyin to ni oun ti fọwọ́ si afikun owo oṣù fun awọn oloselu, awọn adari iṣejọba ati awọn oṣiṣẹ ni ẹka ìdájọ́, pẹ̀lú ìdá 114%.
Lati Ọjọru ni iroyin ti n lọ lori ayelujara pe wọn fi owo gọbọi kun owo oṣu awọn to di ipo oṣelu mu.
Eyi si ti n fa àríyànjiyàn laarin àwọn ọmọ Naijiria. Oludari àjọ RMAFC , Hassan Mohammed Usman, sọ fún BBC pe ikede ti awọn fi sita kọ́ nìyẹn. Ọgbẹni Usman sọ pe ojúṣe àjọ naa ni lati ṣe agbeyẹwo owo oṣu ààrẹ, awọn gomina, awọn aṣòfin, ati awọn adájọ́.
Ki Buhari to kuro nipo aarẹ la ti gba aṣẹ afikun owo oṣu
"Ki Ààrẹ Muhammadu Buhari to kuro ni ipo lo ti fun wa ni iwe pe agbẹjọ́rò agba ati awọn agbẹjọ́rò, sọ pe ka ṣe agbeyẹwo owo oṣu.
"Lẹyin naa ni awọn ọmọ igbimọ aláṣẹ ijọba apapọ naa sọ pe ka ṣe agbeyẹwo owo oṣu ti wọn naa." Oga sọ pe oṣù bíi mẹrin ni awọn fi ṣe iṣẹ́ naa, ti awọn si fi ààbọ̀ ranṣẹ́ si ààrẹ, sugbọn ko fi ranṣẹ́ si ile aṣòfin lati yẹ ẹ wo titi to fi kuro nipo.
"Ile aṣòfin ko tii ṣe àgbéyẹ̀wò rẹ. Lẹyin ti wọn ba yẹ ẹ wo ni aarẹ yoo fi ọwọ́ si ko le di òfin." O salaye pe N1. 3m ni owo oṣu ààrẹ tẹ́lẹ̀, sugbọn pẹlu eto tuntun tí wọ́n wọn n gbero rẹ, yoo fẹẹ di N2m.
Bakan naa ninu ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan pẹlu ileeṣẹ amóhùnmáwòrán Arise, Ọgbẹni Usman sọ pe ẹẹkan laarin ọdun marun-un ni wọn ma n ṣe àtúnṣe owo osu ààrẹ ati awọn yooku , sugbọn ọdun 2007 ni wọn ti ṣe e kẹ́yìn.
O ni oríṣiríṣi ayẹwo ati ijiroro ni àwọn ṣe, ki wọn to fẹnu ko lati fi ìdá 114% kun owo oṣu
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post












